Wo ọkọ̀ Volvo tí Funmilayo Ransome-Kuti lò gbẹ̀yìn, kó tó jáde láyé
Ni ilẹ Yoruba, ọpọ awọn ọkunrin to laami-laaka ni akọsilẹ wọn wa ati ipa ti wọn ko si agbelarugẹ agbegbe koowa wọn.
Ẹtahoro si ni akọsilẹ to wa nipa awọn obinrin to jẹ akinkanju lagbegbe koowa wọn.
Amọ ko si bi a se fẹ darukọ irufẹ awọn obinrin akikanju yii ti a ko ni ranti obinrin akọkọ to wa mọto ayọkẹlẹ ni Naijiria.
Orukọ rẹ ni Mama Olufunmilayo Ransome-Kuti, orukọ ọkọ rẹ ai ni Oludotun Ransome Kuti.

Oríṣun àwòrán, Kuti Museun
“Mama Kuti lo ọpọlọpọ mọto ki wọn to dagbere faye amọ ọkọ Volvo yii ni wọn lo gbẹyin, ki wọn to ku.”
BBC Yoruba fẹsẹ kan ilu Abeokuta nibi ti agboole ẹbi Kuti wa lati mọ bi ile ọhun se ri.
A si ri daju pe wọn ti sọ ile naa di ibugbe isẹnbaye nibi ti wọn se awọn ohun eelo ti mama Olufunmilayo Ransome-Kuti ati ọkọ rẹ, Oludotun Ransome-Kuti lọjọ si.
Nibẹ la si se alabapade mọto Volvo kan to wa nilẹ, eyi ti eruku ti bo pupọ.
Nigba to n salaye bi mọto naa se jẹ, oludari ibudo naa, Akinlabi Sokunbi, ni ọkọ Volvo ti mama naa gun gbẹyin ni ọkọ naa.
“Mama Kuti lo ọpọlọpọ mọto ki wọn to dagbere faye amọ ọkọ Volvo yii ni wọn lo gbẹyin, ki wọn to ku.”
O fikun pe ọpọ eeyan lo maa n wa wo ibudo isẹmbaye naa, paapaa awọn ọmọ̀de ati awọn oyinbo.
Sokunbi wa rọ awọn ọmọ ilẹ Yoruba lati maa wo awọn ohun ti wọn se lọjọ ni ibudo naa.

Oríṣun àwòrán, Kuti Museun
Ta ni Olufunmilayo Ransome-Kuti?
Mama Kuti, nigba aye rẹ jẹ akikanju obinrin, ajafẹtọ awọn obinrin ati abo bi akọ nitori igboya ati iwa akin to hu.
Koda, akọsilẹ gan wa pe Mama Funmilayo Ransome-Kuti lo lewaju awọn obinrin nilu Abeokuta, tii se olu ilu ipinlẹ Ogun bayii, lati tako owo ori sisan lasiko eebo amunisin.
Iwọde naa si rinlẹ debi pe ọrọ naa ni Alake to wa lori oye lasiko naa ba kuro lori itẹ.
Bakan naa lo tun maa n gbena woju awọn adari ilu tlọkan o jọkan, ti iwa rẹ yii si jẹ ko di ilumọọka.
Lara awn ọmọ ti Olufunmilayo Ransome-Kuti bi ni Olikoye Ransome-Kuti, Beko Ransome-Kuti ati Olufela Ransome-Kuti.
Gbogbo awọn ọmọ mama yii si lo ni ẹmi akin ati igboya lati jijagbara lati tako iwa ijẹgaba ati imusin.






