Ebi pa àádọ́ta èèyàn kú ní Ethiopia, èranko 4,000 tún jáde láye nítorí ọ̀gbẹlẹ̀

Ethiopia

Oríṣun àwòrán, reuters

O le ni aadọta eeyan to ti jade laye bayii lagbegbe Tigray ati Amhara, lorilẹ-ede Ethiopia.

Awọn alaṣẹ ilẹ naa ni eyii ko ṣẹyin ọgbẹlẹ to mu nibẹ ati bi Amẹrika ati UN ṣe gbẹsẹle awọn iranwọ okeere kan to yẹ ko wọ orilẹ-ede ọhun.

Gẹgẹ bii ohun ti ajọ agbaye, UN sọ, igba marun un ọtọtọ to yẹ ki ojo rọ nibẹ ni ojo kọ lati rọ.

Ṣaaju ni ajọ UN ati orilẹ-ede Amẹrika ti kọkọ gbẹsẹle awọn ohun iranwọ to yẹ ko fi ṣọwọ si orilẹ-ede naa latari bi awọn eeyan kan nibẹ ṣe n ji awọn ohun iranwọ naa ko.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọdun to kọja ni ogun abẹle to waye ni Tigray ṣẹṣẹ pari lẹyin ọdun meji.

Ni bayii, nnkan bii eeyan mẹrindinlaadọta lo ku niluu Yechila ni Tigray, nigba ti eeyan mẹfa mii ku niluu Amhara, to wa lagbegbe Wag Hemra latari ounjẹ ti ko si.

Yatọ si awọn eeyan to jade laye, nnkan bii ẹgbẹrun mẹrin ohun ọsin naa lo tun ba iṣẹlẹ naa lọ.

Bi Ariwa Ethipia ṣe n koju ọgbẹlẹ to n mu ẹmi eeyan atawọn ẹranko lọ, ni iha guusu ati ila oorun n koju iṣẹlẹ omiyale.

Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ, ajọ UN sọ pe ko din ni 370,000 eeyan to ti sa fi ile wọn silẹ nitori iṣẹlẹ omiyale naa.

O kere tan, eeyan mẹtalogoji ni omiyale ati ilẹ riri ti ṣekupa ni agbegbe ila oorun.

Lasiko ogun to waye nibẹ ni orilẹ-ede naa padanu awọn ohun elo iranwọ to yẹ ko gba, eyii to yọri si iku ẹgbẹgbẹrun eeyan.

Amọ awọn iroyin kan tilẹ sọ pe nnkan bii 500,000 eeyan ni ebi ati iyan pa ku.

Ṣugbọn ogun naa wa sopin lẹyin ti ijọba Ethiopia ati awọn ọmọ ogun Tigray People's Liberation Front (TPLF) tọwọ bọwe adehun alafia, eyii ti ajọ AU ṣagbatẹru rẹ.