Gómìnà Abdullahi Sule Nasarawa fẹ̀yìn olùdíje PDP janlẹ̀, ìlé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn dá a laré

Oríṣun àwòrán, Facebook/AA Sule
Ileẹjọ kotẹmilorun to fi Abuja ṣe ibujoko ti wọgile idajọ igbimọ igbẹjọ awuyewuye idibo gomina Nasarawa to ni oludije ẹgbẹ oṣelu PDP David Ombugadu lo wọle ibo goimina ipinlẹ naa.
Ni bayii, ile ẹjọ kotẹmilọrun ti dajọ pe Abdullahi Sule lo jawe olubori ninu idibo to waye.
Ninu idajo to gbe kalẹ l'Ọjọbọ, ile ẹjọ kotẹmilorun sọ pé igbimọ igbẹjọ to kede Ombugadu PDP gẹgẹ bi oludije to wọle kuna pẹlu idajọ to gbe kalẹ ṣaaju.
Loṣu to kọjá ní igbimọ to n gbẹjọ awuyewuye to jẹyọ lori idibo Gomina Nasarawa wọgile esi ibo to gbe Gomina Sule ti ẹgbẹ oṣelu APC wọlé.
Igbimọ yi sí ni Ombugadu ẹgbẹ PDP lo tọ si ipo yi gẹgẹ bi ẹni tó jawe olubori ninu idibo Gomina oṣu Kẹta ọdun 2023.
Ajọ eleto idibo INEC kede Sule gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori pẹlu ibo 347,209 fún ẹgbẹ APC ti alatako rẹ ninu PDP si ni ibo 283,016.
Amọ esi yi ko ba PDP lara mú ti wọn sì gba iwaju igbimọ to n gbọ awuyewuye lọ ti ababọ ibẹ lọjọ keji oṣu Kẹwaa si jẹ wi pe wọn wọgile àṣeyọrí Gomina Sule ti wọn si ni David Ombugadu lo jawe olubori.
Eleyii lo mu ki APC gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ ni Abuja ti idajọ si wa yi esi yi pada l'Ọjọbọ.
Idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun

Oríṣun àwòrán, facebook/AA Sule, Ombugadu
Ninu idajọ to gbe jade ni oṣu kọkànlá, igbimọ igbẹjọ awuyewuye idibo sọ pe ki INEC gba iwe ẹrí moyege pada ,eyi ti wọn ṣaaju fun Gomina Abdullahi Sule.
Igbimọ igbẹjọ ẹlẹni mẹta to gbe idajọ yi kalẹ labẹ idari Adajọ Ezekiel Àjàyí fẹnu ko pe David Umbugadu ti ẹgbẹ PDP lo jawe olubori ninu idibo Gomina to waye lọjọ Kejidinlogun oṣù kẹta 2023.
Oju opo Zoom ni wọn gba gbe idajọ yii kalẹ nigba naa lọhun.
Labẹ ofin Naijiria, aye si wa fun eyikeyi oludije lati gbe ẹjọ kotẹmilọrun rẹ lọ si ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria.
Ni ile ẹjọ to ga julọ ni idajọ yoo pari patapata.
A ko tii le sọ boya Ombugadu ẹgbẹ PDP yoo morile ile ẹjọ yii lati parí ọrọ nipa esi idibo Gomina ipinlẹ Nasarawa.















