Wọ́n lu kọmíṣọ́nnà lálùbami l'Ondo, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Aworan kọmiṣọnna Ondo Kehinde Akinrotoye

Oríṣun àwòrán, Zaheed Aribisala

Awọn eeyan kan ti lu kọmiṣọnna ipinlẹ Ondo, Kehinde Akinroye to n dari ajọ OSOPADEC to n ri si idagbasoke àwọn agbègbè ti epo rọ̀bì wa n'ipinlẹ Ondo.

Àwọn èèyàn ti enikẹni ko mọ ni won yabo ọfiisi ajọ OSOPADEC ti wọn sì bẹrẹ si ni da ọgbà náà ru.

Bayii ni Kọmiṣọnna Akinrotoye ti ọpọ mo sì "BONSUE " bọ sọwọ awọn eeyan naa lti wọn si lu u ni lalubami ti wọn si tun fa aṣọ rẹ ya.

Iroyin tun fidi rẹ mulẹ pe ọkọ̀ ti kọmisọnna Akinrotoye gbe wa sì oriko ile Isẹ OSOPADEC náà ni wọn bajẹ pẹlu awọn míiràn to wa ni inu ọgbà àjọ ọ̀hún.

Awọn akẹkọọ to wa nibi iṣẹlẹ naa sọ ohun ti oju wọn ri

Ajayi Idowu to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ awọn ọmọ bibi ìjọba ibilẹ ẹsẹ odo sọ pẹ nígbà ti ipade ati idanilẹkọọ n lọ lọwọ ni ọfiisi àjọ OSOPADEC ni wọn ṣadeedee gbọ ariwo ọkọ̀ awọn oṣiṣẹ pàjáwìrì.

Idowu ni ‘’lẹyin naa ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ eleto abo lọ sọ fun awakọ naa pe ki o dẹkun ariwo pipa.

Ọkan lara awọn alejò to wa fun ayẹyẹ iṣide owo iranwọ fun awọn akẹkọọ ni a kọkọ pe e.''

O ni nígbà ti wọn maa de isalẹ ni wọn to rii pe awọn afunrasi janduku ni wọn ti wọ inu ọgba naa pẹlu ọkọ̀ mẹta ti wọn sì bẹrẹ si ni da eto to n lọ ru.

Awon oṣiṣẹ eleto abo gbiyanju lati dawọn lẹkun, amọ pabo ni akitiyan jasi.

Alaga OSOPADEC Ọgbẹni Sam Erejuwa naa gbiyanju lati ri pe awọn akẹkọọ ko faragba ninu iṣẹlẹ ọhun.

Igba ti a pada de isalẹ, ari pe won ṣẹ akọlu sì awon kan, a ri pe owo tẹ awọn to wa, ti awọn oṣiṣẹ abo ko sì je ki wọn lọ.

Ọlọpaa Ondo sọrọ lori iṣẹlẹ naa

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ti ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya sọ fun BBC Yoruba pe awọn eeyan f'arapa ninu rogbodiyan ọhun.

Arabinrin Odunlami-Omisanya sọ pe kọmisọna kan ni àjọ OSOPADEC naa f'arapa ti o si di ero ile iwosan.

"Bi ago kan ni ọmọkùnrin kan wa sì ile isẹ ọlọpaa to sunmọ Ile isẹ àjọ OSOPADEC lati wa so pe awọn kan wa ṣe ikọlu sì àjọ OSOPADEC ti wọn sì bẹrẹ si ni da ayẹyẹ ètò iranwọ owo ìwé kíkà fun awọn akẹkọọ to wa lati ijọba ibilẹ ti OSOPADEC ṣoju ru.

Awọn ọlọpa sì gbera lo sìbẹ lati pẹtu sì wahala naa,’’ agbẹnusọ ọlọpaa lo sọ bẹẹ.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo sọ pẹ oun ko le fi idi rẹ múlẹ boyá awọn janduku lo ṣe akọlu sì kọmisọnna Akinrotoye.

Amọ, o ni iwadii ti bẹrẹ lórí iṣẹlẹ ọhun.