Nnamdi Kanu kọwé ránṣẹ látì'mọ́lé pé kí Simon Ekpa jáwọ nìdí ìpe kónílé-ó-gbélé

Aworan Nnamdi Kanu ati Simon Ekpa

Oríṣun àwòrán, BBC/SIMON EKPA FACEBOOK

Ọrọ taa ni ki Baba ma gbọ, Baba naa ni yoo pada wa pari ẹ.

Bẹẹ lo fẹ ẹ jọ nigba ti olori ikọ ajafominira ilẹ Biafra,IPOB, Nnamdi Kanu kọwe si Simon Ekpa pe ko jawọ nidi ipe ki awọn araalu joko sile lalae jade sita.

Simon Ekpa jẹ ọkan lara awọn to n paṣẹ lẹyin ti ijọba Naijiria fi Nnamdi Kanu si atimọle.

Orileede Finland lowa to ti n paṣẹ ranṣẹ si awọn eeyan nilẹ Igbo pe ki wọn ma ṣe jade sita fọrọ aje kankan ni gbogbo ọjọ Aje.

Nnamdi Kanu to wa ni atimọle lori ẹsun iditẹmọjọba sọ pe ki Ekpa kede sita faraaye gbọ wi pe oun gba aṣẹ lọdọ Kanu.

Aworan iwe ti Agbẹjọro Aloy Ejimakor fi sita lorukọ Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Barrister Aloy Ejimakor

Aworan iwe aṣẹ Nnamdi Kanu ti agbẹjọro rẹ fi sita

Oríṣun àwòrán, Barrister Aloy Ejimakor

Aṣẹ ti Kanu pa yin waye lasiko ti ijọba awọn ipinlẹ to wa ni iwọ oorun Guusu Naijiria n kesi awọn araalu lati jade lalae bẹru ki wọn si maa ṣe isẹ wọn lai si idiwọ.

Kanu sọ pe ''mo bẹrẹ igiyanju yi lati le mu ominira ba awọn eeyan wa ni.Kii ṣe pe mo fẹ fi ko wọn lẹru''

O tẹsiwaju pe tọkan tọkan loun ko faramọ ẹnikẹni tabi eyikeyi ẹgbẹ to ṣetan lati mu inira baw awọn eeyan oun.

''Mo fẹ ko jawọ nidi ṣiṣe atako fawọn Gomina tabi awọn eeyan to wa nipo ijọba nitori o ko mọ bi wọn ṣe gbe igbesẹ nitori mi.''

Kanu wa pari ọrọ rẹ pe ki ọkan ninu awọn agbẹjọro rẹ iyẹn Alloy Ejimako fi ikede yi sita top ba ri wi pe Simon Ekpa kọ lati gbe ikede yi jade loju opo rẹ.

Ki ni Simon Ekpa sọ

Aworan awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹnu lọọlọ yi ni ọpọ eeyan ni ila oorun Guusu Naijiria ti n sọ pe konile o gbele ọjọ Aje yi ko tẹ awọn lọrun.

Lọpọ igba lawọn janduku ati ọdaran mii ti n lo anfaani ikede yi lati ko araalu laya jẹ.

Ọpọ awọn olori lagbegbe naa ni wọn ti kesi awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB lati dẹkun aṣẹ yi.

Njẹ ki wa ni Simon Ekpa sọ si aṣẹ ti Nnamdi Kanu pa yi ati pe ṣe yoo gbọ ọrọ si Kanu lẹnu?

Ni bayii Simon Ekpa ti fi esi ranṣẹ pada lori ọrọ yi.

O sọ peawada kẹrikẹri ni ọrọ yi jẹ ati pe o jẹ itabuku fun olori IPOB tii ṣe Nnamdi Kanu.

Simon Ekpa tẹsiwaju loju opo rẹ ni Twitter wi pe ayederu ni iwe to n ja rainnita yi tawọn ileeṣẹ iroyin kan gbe sita pe Nnamdi Kanu lo kọ ọ.

O ni gẹgẹ bi olootu ijọba ile Biafra labẹ aṣẹ Maazi Kanu, oun kesi gbogbo ọmọ ilẹ Biafra lati fọwọ rọ ayederu iwe yi to wa lati ọdọ ajọ ọtẹlẹmuye DSS danu.

O ni awọn ko ni gba aṣẹ lọdọ ajọ DSS ko si si ọrọ mii mọ lẹyin eyi.

''Wọn gbọdọ tu Nnamdi Kanu silẹ o si gbọdọ ba awọn ọmọ Biafra sọrọ lati orileede Finland''

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post