Ọlọ́pàá gbé Chef Dammy, Sowore àtàwọn míì fapá jánú

Aworan Damilola Adeparusi

Oríṣun àwòrán, X/Yomi Fasipe

Ọrọ tun ba ọna miiran yọ lori aawọ to bẹ silẹ laarin gbajumọ alase nni, Damilola Adeparusi, ti ọpọ eeyan mọ si Chef Dammy ati Pasitọ ijọ kan, Wolii Jeremiah Adegoke.

Bẹẹ ba gbagbe, ọpọ awuyewuye lo ti n waye laarin awọn mejeeji lẹyin ti Chef Dammy kopa ninu idije ounjẹ sise fun ọpọ wakati.

Chef Dammy, ẹni ọdun mejilelogun, dero atimọle ọlọpaa lọjọru, ọjọ kẹtalelọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2023, to si tun gba itusilẹ lọjọ naa lẹyin ti wọn gba beeli rẹ.

Ọjọ Kọkandinlogun osu kẹwa ọdun 2023 ni Chef Dammy kede pe Wolii Adegoke, ẹni to se atilẹyin fun lasiko to n se ounjẹ naa, n dunkooko mọ ẹmi oun.

Ọpọ eeyan lori ayelujara n gba ẹbi Chef Dammy niyanju lati mase pa ẹnu mọ lori isẹlẹ yii

Bẹẹ ba gbagbe, Damilola Adeparusi lo ti kigbe saaju lori ayelujara pe wolii naa ti ni ki oun dira fun ogun lati ja, ti awọn mejeeji si ti tẹsẹ bọ sokoto kannaa.

Bi o tilẹ jẹ pe Dammy kede lati se ipade akọroyin, ki oun si tu asiri ohun to fa aawọ laarin awọn amọ ko pada pe ipade awọn oniroyin naa mọ.

Se ni ẹnu si n ya ọpọlọpọ eeyan pe ki lo lee waye, to fa aawọ laarin awọn mejeeji?

Ninu ọrọ ti Oluyẹmi Fasipe gbe sori opo ayelujara X, o kede pe ileeṣẹ ọlọpaa ilu Akure nipinlẹ Ondo, ti mu Chef Dammy lọ si agọ wọn lori ẹsun kan to fi kan Pasitọ rẹ,

O wa rọ awọn mọlẹbi Chef Dammy lati kigbe sita lori ohun to sẹlẹ si Chef Dammy ati ibaṣepọ to wa laarin oun ati Pasitọ naa.

Ko pẹ si igba to gbe ikede naa jade, lo tun pada gbe iroyin mii sita pe Chef Dammy ti gba itusilẹ lẹyin ti wọn gba beeli rẹ.

Ọrọ ti Omoyele Sowore sọ

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore

Ki ni awọn eeyan n sọ lori ayelujara?

Ọpọ eeyan lo ti fi ẹhonu wọn sita lori ayelujara lori bi Ileeṣẹ ọlọpaa ṣe mu Chef Dammy lọ si ahamọ.

Omoyele Sowore, oludije sipo Aarẹ ẹgbẹ oṣelu AAC ninu eto idibo to kọja bu ẹnu atẹlu igbesẹ ileeṣẹ ọlọpaa, to si ni wọn ko mọ ohun to yẹ ki wọn gba jumọ.

“Ileeṣẹ Ọlọpaa ti wọ ara wọn nilẹ, bawo ni wọn se ma mu akẹkọọ to kigbe sita pe Pasitọ n dunkoko mọ oun.”

@dahnnysparrow ni “Ileeṣẹ ọlọpaa maa n sisẹ fun ẹni to ba fun wọn lowo ju, eyi jẹ ohun itiju”.

@omorogiec ni “Lati igba to ti se idije ounjẹ sise fun ọpọ wakati, ni ko ti ni alaafia, Awọn eeyan to n tẹle lasiko naa ni isẹ pupọ lati se. Asiko ti ọmọbinrin yii nilo wọn ju ree”.

@Pa_Chijo ni “Iyun Pasitọ kana to n kọrin iwuri fun lasiko idije ounjẹ sise fun ọpọ wakati. Ẹ sa fun awọn eeyan ẹṣin yii nitori ika ni wọn”.