Yèyé Osun méjì tó rí àtákò ẹ̀sìn n‘Ilorin sọ ìrírí wọn àti bí ọ̀kan ṣe di Mùsùlùmí padà

Àkọlé fídíò, Yeye Osun: Ọ̀kan ní ogun ọdún 16 ló ṣẹ́ nínú oníṣẹ̀ṣe, èkejì ní Ọlọ́run ló pe òun sí Islam
Yèyé Osun méjì tó rí àtákò ẹ̀sìn n‘Ilorin sọ ìrírí wọn àti bí ọ̀kan ṣe di Mùsùlùmí padà

Gbogbo awọn ololufẹ BBC Yoruba to n fi ọkan ba awọn iroyin wa lọ yoo ranti rogbodiyan ẹsin kan to waye nilu Ilorin, nipinlẹ Kwara losu diẹ sẹyin.

Lasiko rogbodiyan naa ni Yeye Osun kan, Yeye Osun Ajesikemi Olokun Omolara Olatunji, ti polongo pe oun fẹ se ọdun Osun amọ ti awọn Musulumi nibẹ yari pe lai, ko le se ọdun naa.

Ọrọ naa fa awuyewuye pupọ, koda, o di pe wọn n ko ara wọn lọ sile ẹjọ, eruku laasigbo naa ko si tii rọlẹ patapata nilu Ilorin di akoko yii.

Bakan naa, obinrin onisẹse miran, Iya Osun Efunsetan Abebi tẹlẹri lo ti wa pada di Alhaja Hawau alalukuran

Eyi si lo ta BBC Yoruba nidi kan, lati lọ gbọ tẹnu awọn obinrin onisẹse mejeeji naa lati mọ awọn iriri wọn nidi ẹsin isẹse.

Bakan naa la fẹ mọ ohun ti oju Yeye Osun akọkọ, ti wọn da lọwọ kọ lati se ọdun Osun ri lasiko ti rogbodiyan naa n waye.

Tunwẹ, a tun fẹ mọ idi ti Iya Osun keji to di ẹlẹsin Musulumi bayii ri, to se yi ọkan pada kuro ninu isẹse ati ohun to mu pada gba ẹsin Islam.

Yeye Osun mejeeji

"Ko wu mi pe mo fẹ di onisẹse ri amọ ogun to n ja mi lati ọdun mẹrindinlogun, ninu ilana isẹse ni ogun naa ti lọ.”

Ọpọ eeyan ni iroyin ko ye nipa awọn obinrin mejeeji naa, ti wọn jẹ onisẹse tẹlẹ amọ ti ọkan ninu wn gba ẹsin Islam.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Yeye Osun Ajesikemi Olokun Olatunji ni oun kọ ni oun gba ẹsin Islam.

O ni wọn ko bi oun sinu isẹse, Musulumi ni iya to bi oun lọmọ nigba ti baba to bi oun jẹ Kristiẹni.

O ni bi oun si se n dagba, ni oun n dagba bii Kristiẹni ati Musulumi, amọ ogun kan n ja oun fun ọdun pipẹ.

“Ara nnkan to gbe mi de Ilorin niyẹn. Mo ro pe maa ri ojutu sọrọ ara mi.

Awọn to dẹ mu mi rin nigba yẹn si wa laye, ti wọn n mu mi tọ oniruuru Alfa lọ amọ nibi ti Ọlọrun ba ni ọna abayọ si isoro eeyan ba wa, ti ko ba tii debẹ, ko ni duro.

Ko wu mi pe mo fẹ di onisẹse ri amọ ogun to n ja mi lati ọdun mẹrindinlogun, ninu ilana isẹse ni ogun naa ti lọ.”

"Mo yi ọjọ ti mo fẹ se ọdun Osun pada tori atako, n ko si duro nilu yii mọ lati se ọdun naa"

Nigba to n salaye rogbodiyan to la kọja, Yeye Ajesikemi ni ko si wahala kankan mọ nigba ti oun ti jawọ ninu sise ọdun Osun to n fa rogbodiyan naa.

“Agbegbe ti mo n gbe, awujọ awọn musulumi ati Kristiẹni ni, ti a si dijọ n gbe ni alaafia lai si wahala kankan.

Nigba ti wahala sẹlẹ lori ọdun ti mo fẹ se, mo yi ọjọ ti mo fẹ se ọdun Osun naa pada, n ko si duro nilu yii mọ lati se ọdun naa.

Lati igba naa ni ko ti si wahala kankan mọ, ti onikaluku wa si n lọ ni ilọ rẹ.

Yeye Osun Ajesikemi Olokun Omolara Olatunji

“Bi mo se lọ sinu isẹse ati bi mo se pada kuro nibẹ, Ọlọrun nikan lo ye tori kii se mimọsi emi gan"

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ Yeye Osun Efunsetan Abebi tẹlẹ amọ to wa di Alhaja Hawau Alalukurani salaye pe Ọlọrun nikan lo ye bi oun se pada sinu ẹsin Islam latinu ẹsin isẹse ti oun n se tẹlẹ.

Nigba to n salaye nipa awọn iriri rẹ, Yeye Osun tẹlẹ naa ni awọn Alfa kan wa ta ko awn ni odo ti awọn ti lọ rubọ.

“Ọkan ni awọn ọmọ to tẹle mi lo ka isẹlẹ naa silẹ, to si ju sori afẹfẹ, bi inu si se bi ọkan lara awọn baba wa niyẹn.

Eyi lo mu ki ọrọ yii di tile ẹjọ. Kii se awọn Alfa lo dunkoko mọ mi lati fi isẹse silẹ tori ohun to pamọ, oju Ọlọrun lo to.

Alfa Okutagidi to gba mi silẹ, mo si lọ ki pe o seun, bi mo se de iwaju rẹ ni ẹmi Ọlọrun wọn aye mi.ẹ̀mí Ọlọ́

Funra ara mi ni mo yanu niwaju Alfa pe mo gba fun Islam, mo si fẹ ki ẹ wẹ mi pada sinu Islam.

Ọpọ awọn eeyan ni wọn ni awọn ko tii gba pe mo fẹ pada sinu Islam, to si gba wọn to osu kan, ki wọn to gba mi gbọ nigba ti n ko yi ipinnu mi pada.”

Alhaja Hawau Alalukurani

"Awọn Musulumi fun mi lẹbun to pọ, o jọ mi loju, o si ya mi lẹnu eyi to da bii isẹ iyanu loju mi"

Nigba to n sọrọ nipa ẹbun ti awọn eeyan kan fun tori pe o gba Islam, Alhaja Awawu ni lootọ ni wọn fun oun lẹbun pupọ, eyi to ya oun lẹnu.

“Wọn fun mi lẹbun to pọ, o jọ mi loju, o si ya mi lẹnu eyi to da bii isẹ iyanu loju mi.

Di isinsin yii, mo si n se iranran rẹ pe se lootọ ni abi irọ ni.”

Alhaja naa wa gba gbogbo eeyan nimọran lati ronu wọn, ki wọn mase sọnu, ki wọn to sọnu.