Mọ́tò ya wọ agbo àjọyọ̀ lórí èsì ìbò Ààrẹ Liberia, èèyàn mẹ́ta dèrò ọ̀run

Oríṣun àwòrán, MOSES KOLLIE GARZEAWU/BBC
O to eeyan mẹta to ti jade laye bayii, ti eeyan mejidinlọgbọn si wa ni ile iwosan ni olu ilu Liberia lẹyin ti ọkọ ayọkẹlẹ kan yawọ agbo ti awọn ololufẹ Aarẹ tiluu sẹsẹ dibo, Joseph Boakai ti n ṣe ajọyọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa sapejuwe isẹlẹ naa gẹgẹ bi ijamba ọkọ sugbọn ẹgbẹ oṣelu Boakai pe ni iwa igbesunmani.
Eyi waye lẹyin wakati diẹ ti ajọ eleto idibo lorilẹede Liberia kede Boakai gẹgẹ bi ẹni to bori eto idibo Aarẹ to waye lọsẹ to kọja.
Ninu ọrọ rẹ si awọn araalu lẹyin esi ibo, Aarẹ George Weah pe fun isọkan lorilẹede Liberia
Esi eto idibo lo jẹ eyi to sumọ arawọn pẹkipẹki, to si jẹ ẹgbẹrun lọna ogun ibo lo wa laarin awọn olidije mejeeji.
"Bi dẹrẹba ọkọ se n sa lọ lo fun awọn araalu lara pe o mọọmọ ya wọ agbo ariya ni, kii se bireki ọkọ ni ko dara"
Boakai ti ṣe abẹwo si awọn eeyan to farapa ni ile iwosan to wa ni Monrovia, to si ṣe ileri lati ṣe iwadi lori isẹlẹ naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọwọ ti tẹ dirẹba ọkọ naa.
Lọjọ Aje, Ọjọ Ogunjọ oṣu kọkanla ọdun 2023 ni awọn ololufẹ Aarẹ tiluu sẹsẹ dibo yan, n dunu nipa esi ibo niwaju ọfisi ẹgbẹ oṣelu Unity Party nigba ti ọkọ naa ya bo wọn.
“Sadede ni ọkọ naa bẹrẹ si ni sare, to si yawọ ibi ti awọn eeyan to n dunu wa,” agbẹnusọ UP, Mohammed Ali sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP.
Dirẹba ọkọ naa fi ọkọ silẹ to si mu ere, Awọn eeyan to n binu dana sun ọkọ naa.
Oṣojumikoro sọ fun ileeṣẹ iroyin Liberia Observer pe awọn ro pe ijamba naa waye nitori bireki ọkọ naa to sọ ijanu rẹ nu sugbọn bi dirẹba ọkọ ṣe bẹrẹ si ni salọ, lo fun awọn lara pe o mọọmọ yawọ agbo wọn eeyan.
“A ko gbọ nkankan nitori orin n dun lọwọ... N ko le sọ pato ibi ti ọkọ naa ti wa. Mo kan sadede ba ara mi ni ilẹ,” Bendu Kiadii, ọkan lara awọn to farapa sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters ni ile iwosan.
Ninu atẹjade kan, Ileeṣẹ ọlọpaa pe n kan to waye ni isẹlẹ ijamba ọkọ, to si rọ awọn araalu lati ṣe suuru ati pe iwadii ti bẹrẹ.
Dokita Sia Camanor, dokita agba ni ile iwosan Monrobia John F Kennedy ni eeyan mẹta lo ti jade laye nitori bi wọn ṣe farapa.
Dokita Camanor wa rọ awọn araalu to wa fi ẹjẹ silẹ nitori ọpọ awọn to farapa yii lo padanu ọpọlọpọ ẹjẹ.
Kókó mẹ́fà nípa ìgbé ayé Joseph Boakai, ààrẹ tuntun ní Liberia

Oríṣun àwòrán, EPA
Joseph Boakai, ẹni ọdun mejidinlọgọrin jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako, to sapejuwe ọjọ ori gẹgẹ bii “Ibukun” ni akẹgbẹ ti wọn jọ jade jupo Aarẹ ti ku orire pe o jawe olubori ninu eto idibo.
Esi ibo ti wọn kede igbẹyin fidi rẹ mulẹ oun lo n lewaju ilumọka agbabọọlu tẹlẹri George Weah ninu eto idibo to lagbara ju lati igba ti ogun abẹle ti pari.
Ọpọ alatako Boakai lo pe ni olorun lẹyin ti iroyin kan jade to safihan ni bi ti o ti n sun nibi ayẹyẹ kan sugbọn o ti ṣe ileri lati mu ireti orilẹede Liberia pada, ti yoo saa agbara rẹ lati ma jẹ ki orilẹede Liberia jabọ.
Boakai jẹ igbakeji Aarẹ fun ọdun mejila labẹ ijọba Ellen Johnson Sirleaf, ẹni to jẹ obinrin akọkọ ti yoo jẹ olori orilẹede ni ilẹ adulawọ, to si mọ ọpọ nipa didari iṣejọba.
Igbesi aye Boakia
Ọdun 1944 ni oṣu kọkanla ni wọn bi Joseph Boakai ninu abule kan to wọn n pe ni Worsonga ni apa ariwa Liberia.
Awọn obi rẹ ko le kọ tabi ka iwe.
Boakai bẹrẹ ilẹ ẹkọ ni orilẹede Sierra Leone, to si pari ni ile ẹkọ ni orilẹede Liberia.
O lọ Fasiti Liberia nibi to ti kawe gba oye ninu imọ nipa isowo.
Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ redio kan, Boakai ni gẹgẹ bi ọdọmọkunrin, oun rin lati Wonsonga lọ si olu ilu lati wa igbeaye to irọnu.
Boakai ati iyawo rẹ Kartumu ni ọmọ mẹrin. Ọmọ ẹlẹyin ijọ Onitẹbomi, to si tun jẹ olori ninu ile ijọsin onitẹbomi Effort.
Lọdun 1980, Boakai jẹ minisita fun eto ọgbin labẹ isejọba Aarẹ tẹlẹri, Samuel Doe, ẹni ti wọn ṣekupa lọdun 1990.
Lẹyin to padanu ibo Aarẹ lọdun 2017, o pinnu lati tun igbiyanju lẹẹkan si.
Nigba to n ba ileeṣẹ BBC sọrọ nipa erongba rẹ saaju eto idibo, Boakia salaye pe oun yoo gbe ogun ti iwabajẹ, ti oun yoo si ọrọ eto ọgbin gboro si, mimu adikun ba ọwọngogo owo ounjẹ ati atunṣe awọn oju opopona.
“Awọn eeyan wa nilo orilẹede ti wọn le pe ni tiwọn, ti yoo bọwọ fun won, ti yoo si tun gbe ogun ti iwabajẹ.”
O wa ṣeleri ipe oun yoo gbe ogun ti iwabajẹ lorilẹede naa lasiko ijọba rẹ
Oṣu kinni ọdun 2024 ni Boakia yoo ṣe iburawọle gẹgẹ bii Aarẹ tuntun orilẹede Liberia.
















