Agbébọn ń gba ìṣákọ́lẹ̀ lọ́wọ́ àgbẹ̀ l’Ókè-Ọya, kí wọ́n tó kórè oko

Aworan awọn agbẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn agbẹ ni apa iwọ-oorun-ariwa orilẹ-ede Naijiria lo n koju iṣoro latọwọ awọn agbebọn lagbegbe naa to n beere iṣakọlẹ ki wọn too le ko ire oko wọn.

Awọn agbẹ naa lo wi pe niṣe ni awọn agbebọn naa n fipa gba owo lọwọ wọn abi ki wọn padanu ire oko naa ti wọn ko ba lee san iṣakọlẹ ohun nipa ki wọn koo lọ abi ki wọn fina sii.

Atẹjade kan latọwọ ajọ iṣọkan agbaye to n moju to ounjẹ ati eto ogbin ti fi lede pe iyan yoo mu ni apa ariwa Naijiria latari eto abo to mẹhẹ nibẹ.

"Ko si agbẹ to le ko ire oko rẹ kuro ayafi to ba san iye owo tawọn agbebọn naa ni ko san"

Ajọ ọlọpaa nipinlẹ Kaduna wipe awọn ti ba awọn olori lawọn agbegbe naa ṣe ipade pọ nipa ọna ati bori ipenija eto abo ọhun.

Awọn olugbe Birnin Gwari lo ti waa ke gbajare pe niṣe ni ọrọ naa n buru sii paapaa julọ bi awọn agbebọn ọun ṣe n dunkoko mọ wọn ju ti atẹyinwa lọ.

Olugbe ilu Birnin Gwari kan ṣe alaye fun BBC pe: “Awọn agbebọn naa a wa nigba ti a ba n ṣiṣẹ oko, wọn o si nii yọju mọ titi di igba ti a ba ti ko ire oko tan ti a si di wọn sinu apo lati waa gbaa pe awọn lo nii.

“Wọn o wi pe ki a ra ire oko naa pada lọwọ wọn lẹyin ti wọn ba gbaa lọwọ wa.”

O wi pe ko si agbẹ to lee ko ire oko rẹ kuro ayafi to ba san iye owo tawọn agbebọn naa ni ko san.

Ọkunrin naa tẹsiwaju pe “Ti agbẹ naa ko ba ri owo san, o ni lati fi ire oko naa silẹ ni.

“Awọn naa pe ara wọn ni ‘Ansaru’ ti wọn maa n fipa gba ‘saka’ lẹyin tawọn agbebọn ba ṣe tiwọn tan.

“Iṣoro yii ti mu ki ọpọlọpọ sa filuu lẹ.”

Awọn agbẹ Katsina naa n san iṣakọlẹ

Ni ipinlẹ Katsina, awọn araalu ṣalaye fun BBC pe o to ilu mẹfa tawọn agbebọn ti n gba iṣakọlẹ bẹẹ.

Olugbe ọkan lara awọn ilu ọhun to ni awọn agbebọn naa maa n gbowo ki wọn to gba agbẹ laaye lati bẹrẹ ikore wi pe “laarin ẹẹdẹgbẹrin naira si ẹgbẹrun lọna ogun ni owo ti wọn maa n beere fun”.

Ọkunrin naa wi pe awọn ko ba lee gbena woju awọn agbebọn naa to ba jẹ pe imọ gbogbo araali ṣe ọkan.

Iṣoro idena awọn agbẹ lati kore oko ni apa oke-ọya yii n mu adinku ba ounjẹ laarin ilu ni akoko kan naa ti awọn araalu sunkun ọrọ-aje to dẹnukọlẹ.

Ajọ to n moju to ounjẹ ati eto ọgbin lagbaye n lo ti wi pe eeyan to le ni miliọnu mẹrindinlogun ati abọ ni o ṣeeṣe koju ebi lapa ariwa orilẹ-ede Naijiria lati oṣu kẹwa si oṣu kejila ọdun 2023.

Iṣoro yii ni yoo peleke si ni ọdun 2024 bi wọn yoo ṣe di miliọnu mẹrinlelogun ti yoo maa koji airounjẹ jẹ ni agbegbe naa ni Naijiria.