Ohun tá a mọ̀ lórí ikú Seyi tó kú sí àhámọ́ ọlọ́pàá ní Ogun rèé

Oríṣun àwòrán, Platform Times
Iroyin iku ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Ṣeyi Oduyiga, gbode kan lọjọ Aiku, Sannde ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kọkanla yii, pẹlu awuyewuye pe awọn ọlọpaa Ogun lo pa a sahaamọ, lẹyin ti wọn fẹsun pe o ya tatoo sara ati jijẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun kan an.
Aburo oloogbe, Mary Oduyiga, ṣalaye fun ẹka iroyin ayelujara ’Platfort Times’, pe ẹgbọn oun lọọ ṣaaji foonu rẹ lọjọ kejidinlogun ọsu kọkanla yii tiṣele naa waye ni, lagbegbe Atoyo ni Ṣagamu.
O ni nibi to ti jokoo labẹ igi kan to si bọ ẹwu rẹ silẹ nitori ooru to mu lawọn ọlọpaa to n ko awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti de.
Mary sọ pe bo ṣe ri wọn lo gbiyanju lati maa sa lọ, ṣugbọn o ṣubu, awọn ọlọpaa naa si mu un.
Ẹsun jijẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun lo ni wọn fi kan an nitori tatoo to ya sara.
Psalm 23, ọwọ meji to n gbe Jesu ga ati ọjọ keje oṣu kẹrin ọdun 2014 ni Ṣeyi fi tatoo naa kọ gẹgẹ bi aburo rẹ yii sẹ sọ, ṣugbọna awọn ọlọpaa mu un wọn si gbe e lọ si agọ ọlọpaa Awolọwọ ni Ṣagamu.
‘’ Awọn ọlọpaa fi ẹnikeji ti wọn mu silẹ, wọn pa ẹgbọn mi nitori tatoo’’
Bi Mary ṣe wi, ’’A bẹ wọn pe ki wọn fi ẹgbọn mi silẹ, wọn lawọn o ni i fi silẹ nitori tatoo to ya sara, wọn ni ọmọ ẹgbẹ okunkun ni.
‘’Wọn fi ẹnikeji ti wọn jọ mu wọn silẹ nitori iyẹn ko ya nnkan kan sara.
‘’Psalm 23 ati ọwọ meji to n gbadura si Jesu lẹgbọn mi ya sara, pẹlu ọjọ keje oṣu kẹrin ọdun 2014 to loun ko le gbagbe to tun kọ sara, ki i ṣ’ọmọ ẹgbẹ okunkun.
‘’Orilẹ-ede South Africa to lọ lo ti ṣe tatoo yẹn. Baale ile to niyawo atọmọ mẹta ni, oun nikan si lọkunrin ninu ọmọ mẹrin tawọn obi wa bi.
‘’Wọn gbe e lọ s’ Eleweeran l’Abẹokuta, wọn o jẹ ka ri i, ọlọpaa beere tuu ọndirẹdi taosan owo ẹ̀yìn’’
Ninu alaye Mary Oduyiga lo ti ni wọn gbe Ṣeyi lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeran, l’Abẹokuta, ṣugbọn wọn ko jẹ koun atawọn ẹbi ri i bawọn ṣe gbiyanju to.
Ọmọbinrin naa sọ pe wọn ko faaye beeli silẹ pẹlu, ọlọpaa kan si ni kawọn lọọ mu ẹgbẹrun lọna igba naira wa bawọn ba fẹe ko jade lahaamọ.
O ni boya nitori awọn ko fun wọn lowo naa ni wọn ṣe pa a.
‘’Igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa Ogun kede iku Ṣeyi fun wa lojiji, o ni o n ṣe bii were, o si pada ku’
Igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa Ogun lo kede iku Ṣeyi fawọn eeyan rẹ bi Mary ṣe wi. O ni ọlọpaa sọ pe oloogbe naa kan deede bẹrẹ si i ṣe bii were loru, o n bu awọn ti wọn jọ wa ni sẹẹli jẹ.
Eyi ni ọlọpaa lawọn ṣe gbe e lọ sọsibitu, nibi to ku si nigba to n gbatọju lọwọ.
‘’A ri ẹjẹ lara oku naa, iho atawọn ibi ti wọn ti ran’’
Nigba ta a de mọṣuari, a ri ẹjẹ lara oku Ṣeyi, iho atawọn oju ọgbẹ ti wọn ti ran.
O ya mi lẹnu pe ọlọpaa le gbe eeyan wa si mọṣuari lai sọ fun wa.
O ṣee ṣe ko jẹ wọn lu u to fi ku ni, tabi ki wọn fun un ni majele jẹ.
‘’Mo ri ẹjẹ ni gbogbo ẹyin ẹ ati oju rẹ, mo si gbọ pe wọn fokun de e lẹsẹ wọn so aṣọ mọ ọn loju, wọn si doju rẹ bolẹ. Ọjọ Ẹti lo ku.’’
Ṣaa, idajọ ododo ni Mary atawọn ẹbi Oduyiga lawọn n wa bayii, wọn lawọn ti n ba awọn lọọya kan sọrọ, awọn yoo si gbe iṣẹlẹ yii de ọdọ ọga agba ọlọpaa l’Abuja.
Alaye ileeṣẹ ọlọpaa Ogun
Laaarọ ọjọ Aiku ni Alukoro ọlọpaa Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, fi atẹjade to ṣalaye igun ọlọpaa sita.
Ileeṣẹ ọlọpaa Ogun lawọn ko purọ mọ Ṣeyi Oduyiga, wọn ni funra rẹ lo jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Buccaneer ati Ẹiyẹ loun ati Gbenga Adejọkẹ tawọn jọ mu latari awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to gba Ṣagamu kan.
Wọn fi kun un pe awọn gbe e lọ si kootu lori ẹsun jijẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun lọjọ kẹtalelogun oṣu kọkanla yii, nigba to di oru ọjọ kẹẹdọgbọn lo bẹrẹ si i ṣe bii alaaganna, to n ge awọn yooku rẹ jẹ.
‘’A gbe e lọ sileewosan awa ọlọpaa, ibẹ ni wọn ti taari rẹ si ileewosan ijọba to wa n’Ijaye, pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ to ge jẹ.
‘’Wọn tọju awọn yooku ara wọn si balẹ, ṣugbọn Ṣeyi ku nibi to ti n gba itọju’’
Bẹẹ ni atẹjade ileeṣẹ ọlọpaa Ogun wi.
Wọn ni ohunkohun to ba yatọ sohun tileeṣe ọlọpaa wi yii, awuruju lasan ni. Ati pe ayẹwo oku yoo waye fun oloogbe, awọn yoo si fi han lode gbangba.
Kọmandi ọlọpaa Ogun lawọn ba ẹbi oloogbe kẹdun, lorukọ CP Alamutu Abiọdun Mustapha, Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun.














