Ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ jápa, ẹ ronú dáadáa kí ẹ tó gbé ìgbésẹ̀ – Ìjọba àpapọ̀ kìlọ̀

Oríṣun àwòrán, NIDCOM
Alaga ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, NIDCOM, Abike Dabiri-Erewa, ti ke si awọn ọmọ Naijiria to fẹ lọ ṣatipo nilẹ okeere ki wọn dẹkun ati maa gba ọna ẹburu.
O ni o ṣeeṣe ki wọn ko sinu wahala ti apa wọn ko ni ka ti wọn ba n lọ ṣatipo nilẹ okeere lai ni awọn iwe to yẹ ki wọn ni ṣaaju.
Ọrọ yii lo n jade bi ọkẹ aimoye awọn ọmọ Naiiria ṣe n salọ kuri ni Naijiria lọ silẹ okeere fun igbeaye to irọrun.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ NIDCOM, Abdur-Rahman Balogun fi lede, Dabiri-Erewa ṣe ikilọ naa lasiko to bẹ awọn ọmọ Naijiria kan ti wọn n gbe ni Brambton, lorilẹ-ede Canada wo.
Nigba to n kaanu fun ipo ti awọn eeyan naa wa ninu otutu, adari NIDCOM naa rọ awọn ọmọ Naijiria to ni erongba ati lọ ṣatipo lai ni awọn iwe to yẹ lọwọ ki wọn tu ero wọn pa, nitori nnkan ko rọrun nilẹ okeere bi wọn ṣe lero.
O ni “Lọpọ igba, kii ṣe ohun to yẹ ki eeyan dawọle rara.”
Awọn ọmọ Naijiria ṣeranwọ fun awọn aṣatipo ni Canada
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Wayi o, obinrin kan to jẹ ojiṣẹ Ọlọrun ati alaṣẹ ajọ ‘Bethel food bank,’ Vivian Eruka ti sọ pe olootu ilu Brampton ti sọ pe awọn alasẹ ilu naa yoo pese ibusun 800 fun awọn eeyan ọhun.
Bẹẹ naa ni ọgbẹni Wale Rabiu, to ni ileeṣẹ kan ti wọn ti n ṣe burẹdi, ti pese burẹdi ọfẹ fun awọn eeyan naa ki wọn le ri ounjẹ jẹ.
Ẹwẹ, ọmọ Naijiria mii to n gbe ni Canada Ọgbẹni Bayo Adedosu ti sọ fun awọn ọmọ Naijiria nile loko pe ki wọn dẹkun ati maa sọrọ odi nipa orilẹ-ede wọn.














