Lọ́jọ́ kan ṣoṣo,aṣòfin Nàìjíríà ṣètò ìgbéyàwó fàwọn ọmọ òrukàn ọgọrùn- ìdí réè

Oríṣun àwòrán, attaheerou.gulma
Aṣofin kan nile aṣojuṣofin Naijiria to n ṣoju awọn eeyan ipinlẹ Kebbi ti danikan ṣeto igbeyawo fawọn ọmọ orukan obinrin ọgọrun nibi ayẹyẹ kan to waye lọjọ Abamẹta.
Ni aafin Emir ilu Kebbi ni Sarkin Kabin Argungun, Alhaji Ismail Muhammad, ti dari eto igbeyawo ọgọrun ọmọ orukan obinrinrin wọnyi.
Ọpọ awọn eeyan lo peju sibi ayẹyẹ naa lati ipinlẹ Kebbi ati awọn ipinlẹ mii to wa ni iwọ oorun ariwa Naijiria.
Wọn so ọkọ ati iyawo kọọkan papọ gẹgẹ bi tọkọ-taya lẹyin ti wọn kede iye owo sadaaki ti wọn si jẹri si lati ọdọ awọn alagbatọ wọn.
Lara ẹbun ti wọn fi fun awọn iyawo tuntun wọnyi ni ibusun ati ẹṣọ ile mii to fi mọ Al Qurani kọọkan.

Ọjọ ayọ ati idunnu nla loni jẹ fun mi-Hafsat
Ọkan ninu awọn ọmọ orukan obinrin naa ti wọn fi le ọkọ Hafsat Ismail ṣapejuwe igbeyawo gẹgẹ bi iṣẹlẹ nla ni igbese aye oun.
''Oore kekere kọleyi jẹ nittori mi o lero pe mo maa tete lọ si ile ọkọ nitori mi o m iya ati baba to bi mi rara''
Aṣofin to ṣeto yi to si jẹ aṣoju ẹkun idibo Argungu/Augie ni ile aṣojuṣofin Naijiria,Sanni Yakubu Noma sọ pe oun mọ ẹdun ọkan ki eeyan ma le ṣeto igbeyawo bi awọn iyoku tori pe ọmọ orukan loun naa jẹ.
O ni idi ree toun fi ṣeto igbeyawo yi fawọn ọmọ orukan obinrin yi
Ṣaaju ni aṣofin loun ti ṣe ifilọlẹ igbimọ ti yoo ṣeto igbeyawo yi.
O ni oun yoo tẹsiwaju etoigbeyawo ọlọdọọdun yi titi toun yoo fi pari saa ọlọdun mẹrin rẹ ni ile aṣojuṣofin Naijiria.

Oríṣun àwòrán, attaheerou.gulma
Ọpọ awọn ọkọ ati iyawo tuntun yi ni wn kun fun ayọ ati idunnu tori bi wọn ṣe ri igbeyawo ṣe ni irọwọ rọsẹ yi.
Wọn fi ẹmi imoore han fun aṣofin to ṣeto yi fun wọn.
Bi ere bi ere eto igbeyawo elero pupọ to bẹrẹ ni ipinlẹ Kano ti n gbalẹ kaakiri awọn ipinlẹ loke ọya.
Lọdọ awọn eeyan apa ariwa Naijiria,igbeyawo ṣe apataki ti awọn eeyan ko si ko iyan rẹ kere rara.
Bi nkan ṣe ri lode oni nipa aisowo a maa jẹ idiwọn fawọn to to gbe igbesẹ yi ti wọn o fi ni ṣe igbeyawo lasiko.
Bi idẹkun nla ni eto igbeyawo yi a maa jẹ fun ọpọ ti ko ni ọrọ lati fi ṣe eto igbeyawo.
















