Kà nípa òfin America tó lè ràn P'Diddy àtàwọn ìlúmọ̀ọ́ká míì lẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ibu owo akọrin raapu Sean "Diddy" Combs ni obinrin ẹlẹẹkẹta tun ti fẹsun ifipalopọ kan to si ti pe lọjọ ni orileede America.
Arabinrin to m'ẹsun tuntun yi wa sọ pe Diddy ati ọrẹ rẹ Aaron Hall jijọ fipa ba oun ati ọrẹ rẹ lopọ lọdun 1990 tabi 1991.
Awọn iwe ipẹjọ lori ọrọ yi ti tẹ awọn ileeṣẹ iroyin America lọwọ to fi mọ Rolling Stone.
Aṣoju arakunrin Combs sọ pe: ''Ahesọ ọrọ ti wọn hun leyi jẹ to da lori aṣemaṣe lati nkan bi ọgbọn ọdun sẹyin ti wọn ṣẹṣẹ wa n gbe wa lasiko yi''
''Ọgbọn ati ri owo gba ni wọn n da.Wọn ri gẹgẹ bi ẹni ti wọn le parọ mọ lati le fi ri owo gba''
BBC ti kan si aṣoju fun ọgbẹni Hall naa.
Iṣọwọ ẹsun yi n waye lẹyin ti ofin kan taa mọ si New York Adult Survivors Act, faaye silẹ kan to farakasa ifipabanilopọ pẹjọ ki gbendeke ọjọ Kẹrinlelogun oṣu Kọkanla to de opin.
Awọn ilumọọka mii wo lo n jẹjọ labẹ ofin yi?
Wọn buwọlu ofin yi ni imọriri pataki iru idaamu ọkan ti ifipabanilopọ maa n mu ba awọn to koju rẹ ati bi o ṣe nira fawọn eeyan lati tete yọju ti iru nkan yi ba deba wọn.
Ọpọ awọn ilumọọka ni wọn ti n koju ẹsun ifipabilopọ labẹ ofin yi to fi mọ Jamie Foxx ati Axl Rose.
Awọn mejeeji ti tako ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Ninu ẹsun tuntun ti wọn fi kan Combs,arabinrin naa ti wọn forukọ bo laṣiri sọ pe oun ati ọrẹ rẹ jijọ lọ sibiode kan ti ileeṣẹ rẹkọdi orin kan ṣagbatẹru rẹ.
O ni nibẹ lawọn ti pade Ọgbẹni Combs ati Ọgbẹni Hall.
Obinrin yi ni niṣe ni wọn n fun awọn ni ọti mu lalẹ ọjọ naa ti wọn si ni kawọn tẹle wọn pada lọ si ile arakunrin Hall.
Nibẹ larabinrin yi sọ pe wọn ti fipa mu oun lati ni ibalopọ pẹlu Ọgbẹni Combs.
Ẹsun yi tun sọ pe arakunrin Combs ṣabẹwo si ile arabinrin naa lẹyin ọjọ meloo kan ti o si bẹrẹ si ni faraya.
''Niṣe lo n jaya pe ọrẹ arabinrin yi yoo tu aṣiri nkan toun ati ọrẹ rẹ ṣe fun obinrin mii to n fẹ nigba naa.''
Esun ti wọn gbe lọ siwaju ile ẹjọ giga julọ New York County Supreme Court, sọ pe arabinrin yi " bun awọn ẹbi ati ọrẹ to sunmọ gbọ nipa iṣẹlẹ yi''
O fi kun pe arabinrin naa tọ awọn oniwosan lọ lori ''iporuru ọkan ti iṣẹlẹ yi ko ba a''
Eyi ni ẹsun ẹlẹẹkẹta ti wọn yoo fi kan arakunrin Combs ni oṣu yi .
LỌjọbọ ẹsun ẹlẹẹkeji waye to ni P'Diddy fipa lopọ pẹlu arabinrin to mẹsun wa Joi Dickerson-Neal, lọdun 1991.
Arabibinri yi sọ pe lasiko ti a n wi yi, akrin raapu naa fi oogun sinu ọti fun oun ''to mu ki n oun ma le gbe apa ati ẹsẹ mi rara''
O ni o pada wa arabinrin Dickerson-Neal lọ si ile to n gbe to si fipa ba lopọ gẹgẹ bi wọn ṣe wi ninu iwe ipẹjọ.
Ninu ọrọ to fọ lesi si ibeere BBC, agbẹnusọ Ọgbẹni Combs sọ pe ẹsun yi kii ṣootọ ti ko si ju ọgbọn a tio gbowo lọwọ awọn lọ.
Nigba to n sọrọ nipa ofin Adult Survivors Act, agbẹnusọ Combs sọ pe ''ẹjọ pajawiri yi jẹ ọna kan gbogi tawọn eeyan fi n dori ofin to laniyan daada kodo''
Lọjọ Ẹti, arabinrin Dickerson-Neal sọ pe fifi ẹsun yi lelẹ niwaju ileẹjọ mu ki ọkan oun balẹ.
''O dabi ẹni pe wọn gbe okunkun birimu to bomi mọlẹ kuro laya mi ni ti mo si le tẹsiwaju lati jẹ nkan to ba wu mi laye''
Arakunrin Combs yanju ẹjọ alakọkọ ti wọn fi kan an lati ọwọ iayawo rẹ tẹlẹ Casandra Ventura to jẹ akọrin takasufe lọsẹ to kọja.
Arabinrin Ventura fẹsun ifipabanilopọ ati fifi eeyan ṣowo nabi kan P'Diddy.
O ni baba olowo raapu yi fipa ba oun lopọ to si lu oun laarin ọdun mẹwaa bẹrẹ nigba to wa lọdun mọkandinlogun titi to fipe ẹni ọdun mẹtadinlogoji.
Awọn mejeeji fi tubi n nubi yanju ọrọ naa lọjọ keji ti arabinrin yin mu ẹsun wa si ile ẹjọ.
Arakunrin Combs ti tako gbogbo ẹsun ti Ventura mu wa ti agbẹjọro rẹ si ni ipinnu awọn lati yanju ọrọ lae ṣẹjọ kii se tori pe awọn jẹbi.












