Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fẹ̀sùn ìṣekúpa olórin Tupac lọ́dún 1996 kan Duane Davis

Aworan Tupac

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Amẹrika ti fẹsun ṣíṣe iku pa Tupac Shakur kan olori awọn ọmọ ipata kan .

O jẹ aṣeyori nla ninu ìṣẹlẹ ọlọjọ pipẹ to n ṣe awọn araalu ni kayeefi titi di ìsìn yii.

Ọdun 1996 ni wọn sekupa Tupac, gbajugbaja akọrin raapu.

Ẹmẹẹrin ni wọn yinbọn pa ẹni ọdún marundinlọgbọn náà ni Las Vegas nígbà to wà ninu ọkọ.

Ni ọjọ Ẹti ni ile ẹjọ sọ pé arakunrin Duane "Keffe D" Davis, ẹni ọgọta ọdun jẹbi ẹsun onigun kan to da lori pé o fi nkan ija oloro sekupa eeyan.

Awọn ọlọpaa sọ pé o gbimọran isekupani yi lẹyìn tí ibatan rẹ ati Tupac jọ ní gbolohun aṣọ ninu ile tẹtẹ Casino kan.

Lọjọ Ẹti ni wọn mu Davis lẹgbẹ ile rẹ tó wà ní Las Vegas l'owurọ ọjọ Ẹti tí yoo sí foju ba ile ẹjọ laipẹ.

Awọn ọlọpaa ti ṣafihan aworan rẹ.

Aworan afurasi odaran Duane "Keffe D" Davis

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Greg Kading, ọlọpaa Los Angeles nígbà kan rí to fi odindi ọdun mẹfa ṣe iwadii òkùnfà ikú Tupac sọ fún ileeṣẹ iroyin Associated Press pe ko jẹ iyalẹnu pe wọn mu arákùnrin Davis.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ni gbogbo awọn to mọwọ tabi to pete pero iku Tupac to kù ko si laye mọ.

Kadung sọ pé "oun nikan lo sẹku lori ìṣẹlẹ yii"

Ni ileẹjọ, agbẹjọro olupẹjọ Marc DiaGiacomo sapejuwe ọgbẹni Davis -olori awọn ọmọ janduku South Side Compton Crips - gẹgẹ bi balogun to dari to si pàṣẹ iṣekupa Tupac.

Nígbà tí wọn ba awọn akọroyin sọrọ, oga ọlọpaa Jason Johansson sọ pé ifarajin awọn ọlọpaa ti pada wa sọ eso rere ṣaaju ko to ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ alaye.

O ní Orlando Anderson Ibatan afurasi naa ati Tupac ti kọkọ ba ará wọn já nínú Casino laipẹ sí ìgbà ti wọn yinbọn pa Tupac l'ojọ keje oṣù Kẹsán ,1996.

O pada jáde laye nile iwosan lẹyìn ọjọ mélòó kan.

Ọgbẹni Johansson fi fọ́nrán fidio ìbí tí wọn tí n na Anderson han awọn akọroyin.

O ní iṣẹlẹ yi lo mú kí wọn gbẹsan nipa ṣíṣe iku pa Tupac nígbà tí o wá ninu ọkọ rẹ loju ìbí tí iná ti da wọn duro.

Ọlọpaa naa sọ pé eyi jẹ aridaju pé ija laarin awọn ọmọ janduku ni ìṣẹlẹ ikú Tupac jèti wọn sì tí ṣe àgbéyẹ̀wò ìṣẹlẹ yí laimọye igba.

O ní ọdún 2018, l'awọn to ni aluja to sì tún sọ iwadii lori iṣẹlẹ yi ji pada.

Bẹẹ lọ sọ pé Ọgbẹni Davis naa jẹwọ fawọn akọroyin pé oun wa ninu ọkọ tí wọn tí yinbọn pa Tupac.