Ọmọ aṣofin kan l‘Oyo àti akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH márùn-ún pẹ̀lú awakọ̀ ló jóná nínu ìjàmbá mọ́tò

Oríṣun àwòrán, Bola Bamgbola
Iye eeyan to ku lẹyin ijamba ọkọ awọn akẹkọọ LAUTECH to waye ti pe mẹfa bayii.
Oju ọna marosẹ Osogbo-Ifon-Oyo ni awọn akẹkọọ naa ti n bọ lalẹ Ọjọru ki ijamba ọkọ ọhun to waye, ninu eyii ti lara awọn akẹkọọ naa ti jona di eeru.
A gbọ pe awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ipinlẹ Osun doola mẹfa ninu awọn akẹkọọ naa, ti wọn si gbe wọn lọ sile iwosan.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ree...
Ileeṣẹ iroyin Punch jabọ pe awakọ awọn akẹkọọ naa fi ọkọ bọoṣi rẹ gba ọlọkada kan ni ilu naa, o si gbiyanju lati salọ lẹyin ti awọn araalu bẹrẹ si n le.
Oṣojumikoro to ba Punch sọrọ ni “Nigba to ku mita diẹ ki ọkọ naa de ibi afara Ojutu ni ijanu rẹ kọṣẹ ti ọkọ naa si takiti, ti ina si sọ lara rẹ.”
“Wọn doola awọn kan ki ina ọhun to tan ka amọ eeyan mẹta jona ku.”
Ọga ileeṣẹ adoola ẹmi ipinlẹ Osun, Osun Ambulance Scheme, Elizabeth Arowosafe, sọ fun ileeṣẹ iroyin Punch pe nnkan biii ago mẹsan an abọ alẹ ni awọn gba ipe pajawiri pe ọkọ to ko awọn akẹkọọ LAUTECH to n bọ lati irinajo ti ni ijamba.
"Awakọ bọọsi naa kọlu eeyan kan, o n sare asapajude lati salọ, lo fi ni ijamba, ti mọto naa si jona"
O ni “Wọn sọ fun mi pe awakọ naa gba ẹnikan ni Okinni, o si n sare asapajude nitori awọn kan ti wọn n le lẹyin iṣẹlẹ naa.”
“Awakọ ọhun, obinrin kan ati akẹkọọ kan to jẹ ọkunrin jona gurugu, a doola eeyan mẹfa, a si gbe wọn lọ sile iwosan UNIOSUN niluu Osogbo.”
“Mo gbọ pe akẹkọọ LAUTECH ti wọn rinrinajo afẹ lọ si omi Erin-Ijesha ni wọn.”
Arowosafe tẹsiwaju pe “Ọkan lara awọn akẹkọọ naa sọ fun ileeṣẹ wa pe irinajo afẹ kan ni wọn ti n bọ.
O darukọ lara awọn ti wọn jọ wa ninu ọkọ naa fun wa amọ ko lagbara lati darukọ awọn mii.”
Lẹyin akoko diẹ ni Arowosafe tun sọ fun Punch pe “A ṣẹṣẹ kuro ni UNIOSUN bayii ni.
Mẹta ninu awọn ti a gbe lọ sile iwosan ṣi wa laaye, a ti ko awọn meji mii lọ si UCH nilu Ibadan.”
“Ẹnikan ninu wọn ṣi wa ni ile iwosan UNIOSUN, awọn mẹta to ṣẹ ku ti jade laye, oku mẹfa lo wa nilẹ bayii.”
Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ to n ri si irinna ọkọ loju popo ni Naijiria, FRSC, Agnes Ogungbemi to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe ere asapajude lo ṣokunfa rẹ.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH jóná nínú ìjàmbá mọ́tò, àwọn aláṣẹ fásítì ní àwọn kò tíì lè sọ ìyè akẹ́kọ̀ọ́ tó ku

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn akẹkọọ fasiti imọ ẹrọ Ladoke Akintola ni ilu Ogbomosho ti ko ijamba ọkọ kan lasiko ti wọn ṣe irinajo pada si ile ẹkọ wọn lati Erin Ijesa.
Ijamba yi to waye l'Ọjọru lawọn alaṣẹ ko tii sọ pato iye awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Awọn akẹkọọ naa n dari lati ibi irinajo inaju ti wọn ṣe lọ si Erin Ijesa.
Agbegbe Ilobu si Okinni la si gbọ pe ijamba ọkọ naa ti waye lẹyin ti ọkọ to ko awọn akẹkọọ yi gbina.
A ko le sọ ni pato boya ọkọ naa kọlu ọkọ miran ni tabi oun nikan lo farakasa ninu ijamba yi.
Ibudo irinajo afẹ Ẹrin Ijẹṣa ni wọn ti n bọ ki wọn to lugbadi ijamba naa
Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa, Anuoluwa Adeboye nigba to ba akọroyin BBC sọrọ lori ero ibanisoro so pe awon ilu Ẹrin Ijẹṣa ni ipinlẹ Ọṣun ni wọn ti n bọ ki wọn to lugbadi ijamba naa.
Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ LAUTECH Ogbomọshọ naa tun tẹsiwaju lati ṣalaye pe wọn seto irin ajo afẹ si ibudo omi oloke giga Erin-Ijesa Waterfall leyin idanwo saa kinni wọn,
Bakan naa lo sọ pe pupọ wọn lo wa ni ipele aṣekagba ni fasiti naa
Àwọn ọlọpaa ati awọn alaṣẹ fasiti LAUTECH ko le sọ iye awọn to ku ati ohun to fa ijamba naa
Ohun ti a gbọ ni pe awọn eeyan kan ku ti awọn miran si farapa ninu iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi Ọgbẹni Lekan Fadeyin to jẹ alukoro ile ẹkọ fasiti LAUTECH ti ṣe sọ fun akọroyin wa.
Ohun naa kole sọ pato pe iye eeyan bayi lo ku tabi farapa.
Awọn akẹkọọ yi jẹ akẹkọọ lẹka imọ isiro ti wọn si ṣe irianjo yi lẹyin ti wọn pari
Ati ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn alaṣẹ fasiti naa, ko tii si eyikeyi to le sọ pato bi iṣẹlẹ yi ṣe waye tabi iye awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Alukoro ile ẹkọ naa , Ogbeni Lekan Fadeyin, eni to fi idi ijamba naa mulẹ fun awọn akọroyin ṣalaye wi pe, ọpọlọpọ ẹmi lo sofo ninu ijamba naa ṣugbọn ko le fidi iye won mule nitori oun ko tii gba ẹkunrẹrẹ iroyin lori iṣẹlẹ naa.
Ọmọ olori ọmọ ẹgbẹ to pọ julọ ni ile aṣofin ipinlẹ Oyo wa ninu awọn akẹkọọ naa

Ohun ti a ri gbọ ti a si le fi idi rẹ mulẹ ni pe ọmọ Sanjo Adedoyin, olori ọmọ ẹgbẹ to pọ julọ ni ile aṣofin ipinlẹ Oyo wa lara awọn to padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa.
Orukọ ọmọ naa ni Faith Adedoyin ti awọn iranṣẹ ikinni lorisi si ti n waye fun baba rẹ, Họnọrebu Sanjo Adedoyin nile aṣofin ipinlẹ Oyo l'Ọjọbọ.
Ni irọlẹ Ọjọru ni iroyin gbori ayelujara tawọn eeyan si n pin awọn aworan to ṣafihan ọkọ to jona ati awọn eeyan ti wọn pe ni akẹkọọ to farapa.
Ninu awọn aworan la ti ri eyi tara awọn arakunrin meji kan bo latari ina to jo wọn.
Wọn joko silẹ ti arakunrin kan si duro to n ba wọn sọrọ.
A ri ti ara, oju ati ẹsẹ ọkan ninu wọn bo bi igba ti eeyan da nkan gbona si lara.
A tun ri aworan mii to ṣafihan ohun to jọ oku eeyan to jona ninu ọkọ to n jona lọwọ.















