Bí ajá bá bù yín jẹ aporó kò ràn án, abẹ́rẹ́ àìsàn dìgbòlugi lòògùn rẹ̀ -Oníṣègùn
Yoruba bọ wọn ni eyin taja fin ba ọmọ rẹ ṣere oun naa lo fi n bu u jẹ.
Lode oni ta wa yi, awọn eeyan to ni aja layika wọn mọ pe ọmọ aja nikan kọ lo wa ninu ewu eyin aja to n bu eeyan jẹ.
Ati olowo rẹ ati awọn ẹlomiran to wa layika ni o ni lati ṣọra gidi lọwọ aja paapa eleyi to ba ni kokoro aisan digbolugi lara.
Loni ti o jẹ ayajọ aisan digbolugi lagbaye eyi taa mọ si World Rabies Day, BBC Yoruba kan si awọn onimọ iṣegun kan nibi ti wọn ti n ṣe ipolongo lori ewu to wa ninu ki aja to ni kokoro digbolugi lara bu eeyan jẹ.
Ki ni a n pe ni aisan digbolugi
Aisan to n ran ka nipa itọ ẹnu ẹranko tabi ibujẹ ẹranko ni aisan digbolugi jẹ.
Ninu awọn ẹranko layika wa ti eeyan ti le ko aisan yi ni aja,adan ati kọlọkọlọ.
Lara afihan tabi apẹrẹ aisan yi taa le ri ni pe ara eeyan yoo maa gbona,ori yoo maa fọ,itọ yoo maa da lẹnu rẹ leralera ko si ni laakaye lati mọ nkan to n ṣẹlẹ.
Abẹrẹ ajẹsara wa fun aisan yi amọ to ba di pe aja tabi ẹranko mii to ni kokoro yi lara ba bu eeyan jẹ, ile iwosan lo yẹ kẹni naa lọ lae jafira.
Ki ni nkan tawọn onimọ iṣegun taa ba pade layajọ aisan digbolugi sọ ni ikilọ paapa fawọn to n foju di aja to ni kokoro aisan yi lara?
Ati aja to n ba eeyan ṣere ati eleyi to buru lo ṣeeṣe ko ni kokoro aisan digbolugi lara
Ọdọọdun lawọn akọṣẹmọṣẹ dokita to n tọju ẹranko ni Naijiria maa n ṣe iwọde idanilẹkọ ewu to wa ninu aisan digbolugi.
Ni ilu Abeokuta la ti ṣalabapade awọn to n ṣe iwọde irufẹ rẹ lọdun 2023.
Akọkọ alaye tawọn onimọ iṣegun taa ba pade yi sọ ni pe ki eeyan ni ifura to pọ la ti le mọ boya aja ni kokoro yilara tabi ko ni i.
Akọṣẹmọṣẹ dokita to n tọju ẹranko to ba wa sọrọ ninu awọn to n ṣe iwọde ipolongo lori aisan digbolugi Dokita Olusola Adeleye sọ pe ati aja to n ba eeyan ṣere ati eleyi ti kii ba eeyan ṣere lo yẹ ka fura si.
Ninu alaye rẹ, o ni aarun digbolugi jẹ eleyi to n pa eeyan.
O ni aja to ba n ba eeyan ṣere daada tẹlẹ to si ṣadede bẹrẹ si ni sa fun eeyan, apere leyi jẹ pe o ni kokoro digbolugi lara.
Bẹẹ naa lo sọ pe eyi ti kii ba eeyan ṣere to sadede bẹrẹ si ni gbo kaakiri to si foju oro han, iru aja bayi naa ni kokoro digbolugi lara.
O ni bi ọrọ ba ti ri bayii, ki eeyan tara pe awọn to n tọju ẹranko lati wa wo iru aja bẹẹ lo kan.
Aporo ko ran kokoro aisan digbolugi
Oludari eto itọju fawọn ẹranko Taiwo Jolaoso to pẹlu awọn to ṣe iwọde naa ṣe ikọlu faraalu ni paapa awọn ti aja to ni aisan digbolugi ba bujẹ.
Taiwo sọ pe awọn eeyan kii tete ya si itọju fun ẹni ti aja ba bu jẹ. O ni lọpọ igba kokoro yi yo ti wọ wọn lara ki wọn to lọ si ileewosan.
''Bi aja ba ti bu eeyan jẹ, ko fọ oju eegbo yẹn daada ko si lọ si ile iwosan ni kiakia.Tori pe bo ba pẹ ko to lọ si ileewosan,kokoro yẹ le ti de ọpọlọ rẹ''
Ni afikun alaye iru itọju to yẹ ki wọn ṣe bi eeyan ba ri pe aja bu u jẹ, dokita Olusola Adeleye sọ pe abẹrẹ marun un ọtọọtọ ni eeyan ti aja ba bu jẹ yoo gba.
''Aporo ko pa kokoro to n fa aisan digbolugi.Onitọhun yoo maa gbo bi aja ni to si le gba ibẹ ya were''
Abẹrẹ ajẹsara fun aisan digbolugi nkọ?
Awọn akọṣẹmọṣẹ yi sọ pe anfaani wa lati gba abẹrẹ ajẹsara eleyi to le dena kiko aisan digbolugi ti aja ba bu eeyan jẹ.
Wọn sọ pe lawọn aaye ti ijọb ala kalẹ eeyan le lọ gba abẹrẹ yi to si jẹ pe ọfẹ lo ba de.
''Ẹẹkan lọdun lọfẹ ni abẹrẹ yi.Ijọba ti san owo ẹ fun wọn''













