Ìyàwó fi ọmọ-odó lu ọkọ rẹ̀ pa l'Ondo, ló bá f'ẹsẹ̀ fẹ

Oríṣun àwòrán, Joshua Adetunji
Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti sọ pe oun yoo ma mu Arabinrin Tayelolu Solomon ti wọn fẹsun kan pe o fi ọmọ odo lu ọkọ rẹ, Ọgbẹni Felix Solomon pa.
Iroyin fidi rẹ mulẹ pe ọjọ Abamẹta to lọ yìí ni Tayelolu la ọmọ odo mọ ọkọ rẹ, ẹni ọdun mẹtadinaadọrin lori nigba to n sun lagbegbe GRA nipinlẹ Ondo.
Iwadii fihan pe tọkọtaya ti jọ n ja tẹlẹ ṣaaju iṣẹlẹ buruku yii.
Ọmọkunrin to jẹ ọmọ oloogbe yii ṣalaye pe baba oun ati iya ti kọkọ ja bi wakati diẹ sẹyin ki iya oun to la ọmọ odo mọ baba oun lori ti o si salọ lẹyin naa.
Ọmọ naa sọ pe loju oun ni mama oun ti fi ọmọ odo lu baba oun lori lati oju orun ti o sí f'ẹsẹ fẹ.
"Edeaiyede kan waye laarin awọn mejeeji eleyii ti ija lọjọ naa.
Lẹyin ti wọn jọ ja tan ni baba mi lọ sun sori àga nibi ti iya mi ti la ọmọ odo mọ ọ lori.
Lẹsẹ k'ẹsẹ naa ni baba o le sọrọ mọ ti o sí ṣubu lati ori aga.
Igba mẹta ọtọọtọ ni iya mi la ọmọ odo mọ baba mi ti o sí gba ibẹ jẹ Ọlọrun n'ipe.
Lẹyin ti iya mi ti ri wí pe baba mi o le sọrọ mọ ni o lọ fi ọmọ odo naa pamọ sí ẹyin kule ile wa ki o to salọ.
Mo ke gbajare s'awọn ara adugbo, wọn sí gbe baba mi digba digba lọ si ile iwosan, ẹpa ko boro mọ.
Wọn gbe oku baba mi lọ sí ile igbokusi.
Ọmọ mẹta ni iya mi bi fun baba mi, emi gan an ni abikẹyin," ọmọ oloogbe ṣalaye.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Arabinrin Funmilayo Odunlami to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ni awọn agbofinro ti bẹrẹ iṣẹ lati wa obinrin naa ri ki o le foju wina ofin.















