Àfikún dé bá iye àsìkò R Kelly lọgbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí wọn kéde ẹ̀sùn míràn

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbajugbaja olorin ọmọ ilẹ Amẹrika, R. Kelly ni o ti tun di dandan fun lati lo ọdun kan miiran lẹyin ti ileẹjọ ti kọkọ ko lọkun si ọgba ẹwọn ọgbọn ọdun.

R, kelly ni o ri ẹwọn he lọdun 2022 lẹyin ti Ileẹjọ da lẹbi lori ẹsun pe o n ṣe agbatẹru lilo awọn obinrin ati ọmọde fun owo nọbi ati ibalopọ ti ko lẹtọ.

Lẹyin ọpọlọpọ oṣu, Kelly tun ri ẹjọ he fun igbakeji fun ẹsun owo nọbi ati ibalopọ awọn obinrin ni ileẹjọ giga Chicago

Eeyan mọkanla lo fẹsun kan an, ninu wọn ni obinrin mẹsan ati ọkunrin meji ti wọn kopa ninu igbẹjọ ọlọsẹ mẹfa gbako

Ti R. Kelly ba lo gbogbo awọn ọdun yii lọgba, yoo wa ni ọmọ ọgọrin ọdun ko to gba ominira.

Lasiko igbẹjọ yi, awọn olupẹjọ ijọba apapọ ṣalaye fun ile ẹjọ iriri bi olujẹjọ naa ti ṣe fipa ba awọn eyan lopọ to si tun tabuku wọn bi o ṣe gbe fọran naa sori ayelujara.

“Nitori o jẹ Kelly, ọpọ awọn eeyan lo ti fọran ibalopọ awọn ọmọde.

“Ohun ti Kelly ṣe lo tabuku ẹtọ ọmọniyan.”

Ninu iwe ẹjọ awọn olupẹjọ, wọn salaye pe Kelly mọmọ ni erongba lati ṣe akoba fun awọn ọmọ kekere, ati riran lọ si ẹwọn ọlọjọ gbọrọ ni yoo dabobo agbegbe awọn ọmọ naa.