Gbajúmọ̀ Òṣèré apanilẹ́rin Sisi Quadri pàdánù ìyà rẹ̀, omijé bọ́

Sisi Quadri

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọkan lara awọn oṣere fiimu Yoruba to maa n dẹrin pa ẹkẹ awọn ololufẹ fiimu Yoruba Quadri Oyebamiji ti ọpọ mọ si Sisi Quadri ti fi ibanujẹ ọkan rẹ han si bi o ṣe padanu iya rẹ.

Oṣere yii lo kede loju opo Instagram rẹ ni Ọjọru ọjọ Kejilelogun pẹlu fidio kan fo fi sita to n sun ẹkun gidi.

Awọn eekan oṣere Yoruba atawọn irọ tirẹ naa lagbo oṣere ti n ki i pẹlu oniruuru ọrọ ibanikẹdun.

Lara awọn to ti ki i ku idaro ni Femi Adedayo, Shola Kosoko, Sotayo Gaga, Mustapha Sholagbade, Iya Ibadan, Funmi Awelewa, Afeez Owo, Yewande Adekoya ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Sisi Quadri kọ ninu ọrọ rẹ pe gbogbo igba ni iya oun yoo wa ni ọkan oun.

Ninu fidio to fi sita la ti ri ti o n sọkun kikan kikan i awọn eeyan to wa layika rẹ si n rọ ọ.

Sisi Quadri

Oríṣun àwòrán, Sisi Quadri/Instagram

Bakan naa ni fidio naa ṣafihan rẹ nibi ti wọn ti n sin oku oloogbe naa ni ilana ẹsin Musulumi.

“Iwọ ni ọrẹ to sunmọ mi ju ti mo ni laye iya mi, gbogbo igba si ni waa wa ni ọkan mi. Mi o le gbagbọ pe ẹ o si laye mọ, mo n ṣaaro rẹ iya mi.”

Awọn akẹgbẹ rẹ pọ ti wọn ti n gba a niyanju pe ko mu ọkan le ti wọn si n fi adura ranṣẹ sii.