Joe Ligon: Ẹlẹ́wọ̀n tó pẹ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n jùlọ ní Amerika gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn ọdún 68 lẹ́wọ̀n

Joe Ligon

Oríṣun àwòrán, BRADLEY S BRIDGE

Lẹyin ọdun mejidinlaadọrin, Joe Ligon to jẹ ẹni to pẹ ju lẹwọn ninu itan orileede Amẹrika ti gba itusilẹ.

Nigba to wa ni ọdun mẹẹdogun ni wọn ran lẹwọn lori ẹsun pe oun ati awọn akẹgbẹ rẹ kan kopa ninu idigunjale ati ikọlu sawọn ọmuti kan eyi to kangun si pe eeyan meji padanu ẹmi wọn lọdun 1953.

Itan baba to fi ọdọ wọ ẹwọn yi jẹ eleyi to se eeyan ni kayefi nitori titi di igba to fi jade lẹwọn, ni se lo n sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Ewọn gbere ti wọn fi si jẹ eleyi ti ko fun un laanfaani lati tọrọ aforijin titi di ọdun 2017.

Ni soki gbogbo awọn to mọ ko to di ero ẹwọn lo ti fẹẹ ku tan tabi ti wọn ti dagba debi pe wọn ko da ara wọn mọ mọ.

Ọpẹlọpẹ agbẹjọro rẹ to sipe fun niwaju adajọ ti wọn fi tu silẹ ni osu keji ọdun 2021 yi, Joe ko ba ma ti kuro lẹwọn titi di ba ti se n sọrọ yi.

O ti kuro lẹwọn bayi, sugbọn o ba BBC sọrọ nipa iriri rẹ nigba to wa lẹwọn ati afojusun rẹ bayi to ti gba ominira.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Ma da si nkan ti ko kan ẹ bo ba fẹ gbe igbe aye alafiaa.

Koko kan pataki ti Joe n tẹnumọ ni pe lati igba kekere loun ti da nikan wa.

Kọda, o sọ pe ni nigba ti oun wa lẹwọn, bi igba ti oun si n tẹsiwaju pẹlu idanikanwa lo ri.

"Iranlọwọ lo jẹ fawọn eeyan bi temi ti wọn fẹ da wa.

Iru eeyan bẹẹ ni mo jẹ ati pe kete ti mo ti wọ inu ẹwọn ti wọn tilẹkun mọ mi, nise ni mo di eti mi si gbogbo nkan to n lọ layika.

Lẹẹkọọkan wọn gba wa laaye lati gbọ redio tabi ka wo ẹrọ amounmaworan.

Awọn nkan wọnyi lo di ọrẹ timọtimọ fun mi lẹwọn''.

Joe Ligon

Oríṣun àwòrán, BRADLEY S BRIDGE

Bi eeyan ba sọ pe Ligon yiwa pada si daada nigba to wa lẹwọn, a ko jina sootọ.

Iwa sise jẹẹjẹ yi ni ko jẹ ki o ko si wahala ti igbe aye rẹ ninu ẹwọn ko si mu inira wa ju ti tẹgbẹ lọ.

O ni nise loun fi ọdun mejidinlaadọrin toun lo lẹwọn lati fi kọ ẹkọ pataki nipa ki eeyan mama da si nkan ti ko kan an.

Nigba tasiko to ti wọn yoo tu silẹ lẹwọn,ko tiẹ nii lara rara wi pe ko si ẹnikankan to wa lati wa pade rẹ.

Àkọlé fídíò, Budo Ikoko water problem: Ìyàwó wa ti sá lọ kúrò ní Asa nítorí àìsí omi- Alhaji Sunmonu

Joe ni oun ko wa ọrẹ kankan nitori oun mọọmọ pinuu bẹẹ ni.

''Nigba ta wa lẹwọn, a ko ni ọrẹ pupọ, bẹẹ la o ni ọrẹ nita naa.Mi o tiẹ ki n lo gbolohun ''ọrẹ''

lati sapejuwe ẹnikankan.Ọpọ lo pe eeyan lọrẹ ti o si jasi aburu fun wọn.''

O salaye pe ''ni temi a le jijọ jẹ alabasepọ tabi akegbẹ sugbọn mi o mu ẹnikankan nimu ọrẹ''

Bawo le se di ero ẹwọn?

Bi a ba wo igba ewe Ligon, a o ri pe lati igba naa lo ti bẹrẹ si ni danikan wa.

Ni ilu Birmingham ni Alabama to dagba si, ko ni ọrẹ kankan nibẹ.

Ọpọ igba awọn mọlẹbi rẹ nikan lo maa n ba sepọ ti wọn a si maa tẹti gbọ iwaasu lati ẹnu baba to bi baba rẹ ni ile ijọsin to wa nibẹ.

Joe Ligon

Oríṣun àwòrán, PENNSYLVANIA DEPARTMENT OF CORRECTIONS

Ni igba to di ọmọ ọdun mẹtala, a ti oun ati mama rẹ to n sisẹ nọọsi ati baba rẹ to n sisẹ mọkaliiki ati awọn aburo rẹ, wọn ko lọ si agbegbe guusu Philadelphia.

Ileewe nira fun un ti ko si mọ bi wọn se n kọ tabi ka iwe. Ko mọ ere idaraya kankan se ko si ni ọrẹ ti eeyan n ba se pọ.

Aini ọrẹ rẹ yi lo n ba lọ titi di irọlẹ ọjọ ti wọn lọ daran pẹlu awọn kan lọdun 1953.

Ninu awọn ti wọn jijọ kora wọn lo digun jale lọjọ taa n wi yi, ko si ẹnikankan to mọ ninu wọn.

Awọn to kan pade ladugbo ti wọn jijọ se ikọlu si awọn ọmuti kan ni ọlọpaa ko wọn papọ.

Abalọ ababọ, awọn ọlọpaa ko oun ati awọn ọrẹ rẹ ti wọn si fẹsun ipaniyan kan.

Ọrọ di ile ẹjọ nibi ti adajọ ti ni ki wọn ran lẹwọn gbere lẹni ọdun mẹẹdogun.

Ipinlẹ Pennsylvannia ti wọn ti ran lẹwọn jẹ ọkan ninu awọn ipinlẹ mẹfa ti wọn kii dari ji awọn ti o ba gba idajọ ẹwọn gbere.

Eyi lo mu ki o gba kamu idajọ lori ẹsun onigun meji ti wọn fi kan to si kọri si ẹwọn lai rojọ.

Philadelphia

Oríṣun àwòrán, H. ARMSTRONG ROBERTS/CLASSICSTOCK

Koda ko tiẹ mọ iye ẹwọn ọdun ti wọn ran lọjọ naa lọhun.

Bayi to ti wa kuro lẹwọn, ki lo kan?

Igbiyanju agbẹjọro rẹ lo mu ki Ligon pada ri itusilẹ lẹwọn.

Bo tilẹ jẹ wi pe anfaani wa fun lati pe ẹjọ kotẹmilọrun sugbọn ainimọ se akoba fun ti o si pẹ lẹwọn ju bo ti se yẹ lọ.

Nigba ti yoo fi jade lẹwọn lọjọ kọkanla osu keji ọdun 2021,nise ni o dabi iranran loju rẹ.

''O dabi ẹni pe wọn tun mi bi ni,nitori gbogbo nkan lo dabi tuntun loju mi''.

''Mo wo awọn ọkọ tuntun,mo wo ile ti wọn gbe misi ati awọn ile onigogoro to yi wa ka.

Gbogbo rẹ lo yatọ loju mi sugbọn o ti n mọra diẹ diẹ''

Ajọ ẹlẹyinju aanu kan lo n se iranwọ fun bayi ati le gbegbe aye alaafia lẹyin to jade lẹwọn.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Ẹ̀yà Ara Ifọ̀ ní olùkọ́ Adedokun kọ́ wa