Israel /Gaza War: Ìkọ ológun Hamas tu àwọn èèyàn míì tó wà ní ìgbèkùn sílẹ́ pẹlú bí àwọn mọlebi ṣe n fojú sọ́nà

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn ìṣí keji ọmọ Israel to wa nigbekun Hamas kuro nigbekun ọhun lọjọ Satide, lẹyin ọpọlọpọ wakati ti wọn fi da wọn duro lai jẹ ki wọn lọ.
Awọn ẹbi wọn paapaa ti n kaya soke pe boya wọn o ni i bọ ninu ahamọ Hamas mọ ni.
Ikọ ologun Israel ṣalaye pe ọmọ ilẹ naa mẹtala ni wọn yọnda ni Gaza, wọn lawọn naa si tori eyi yọnda ẹlẹwọn mọkandinlogoji ọmọ Palestine lagbegbe West Bank.
Wọn fi kun un pe Hamas naa si tu eeyan mẹrin ti wọn jẹ ọmọ Thai silẹ nigbekun.
Ọjọ Ẹti ni itusilẹ akọkọ waye, nigba ti wọn ṣadehun ati dawọ ogun duro fọjọ mẹrin, eyi ti Qatar ṣagbatẹru rẹ.
Asọye ti wọn jọ sare sọ lọjọ Satide lo fa bi kaluku wọn ṣe n juwọ silẹ yii.
Ni tawọn Israel, ẹgbẹ alagbelebu pupa lafojusun wa pe wọn yoo fa wọn le lọwọ lẹnu ibode Gaza, ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ, pẹlu Egypt (laago meji ọsan).
Ikọ ologun Hamas, awọn ologun Qassam, sọ pe awọn koju iṣoro lati ko awọn nnkan iranwọ wọ Gaza, ati bawọn yoo ṣe ṣa awọn ẹlẹwọn Palestine ti wọn fi paarọ awọn ti Hamas.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Israel ni tiẹ loun ko tapa sofin kankan to de adehun ajọṣe.
Agbẹnusọ awọn Hamas, Osama Hamdan, ṣalaye pe tirela ojile-lọọdunrun (340) to ko nnkan iranwọ lo lọ si Gaza lọjọ Ẹti.
Amọ o ni marundinlaadọrin (65) pere lo ṣi de Ariwa Gaza, eyi ti ko to idaji ninu adehun ti Israel bawọn ṣe, gẹgẹ bo ṣe sọ.
Apejuwe Ariwa yii latọdọ Israel ni pe ibudo ogun ni, wọn ni Ajọ Iṣọkan Agbaye (UN) lo yẹ ko pese iranwọ fun wọn.
Lẹyin-o-rẹyin, ọga kan lọdọ awọn Palestine to jẹ alẹnulọrọ, fidi ọrọ ti Qatar sọ mulẹ pe wahala yii ti yanju.
Bẹẹ ni Hamas fọhun 'a dupẹ' si Egypt ati Qatar fun bi wọn ṣe jẹ kadehun ọlọjọ perete to mu ogun dawọ duro yii maa tẹsiwaju.
Labẹ adehun naa, aadọta ọmọ Isrẹli to wa nigbekun ogun, awọn obinrin atawọn ọmọde ni wọn ni ki Hamas tu silẹ laarin ọjọ mẹrin, eyi ti yoo jẹ paṣi-paarọ fun aadọjọ (150) ọmọ Palestian ti wọn yoo tu silẹ nigbekun.
Ijọba Isrẹli sọ pe o ṣeeṣe kawọn ṣafikun adehun ọlọjọ perete to dawọ ogun duro naa, ti wọn ba n yọnda ọmọ Isrẹli mẹwaa lojumọ nigbekun, o kere tan.
Ṣugbọn wọn ti wa ṣaleri pe awọn yoo ri i pe awọn sọ Hamas di nnkan igbagbe, wọn duro lori adehun ọlọjọ perete naa fungba diẹ ni.
Hamas ji ojilenigba eeyan gbe (240) nigba ti wọn kọlu Guusu Israel lọjọ keje, oṣu Kẹwaa, wọn si pa eeyan ẹgbẹrun kan ati igba (1,200)araalu lasan ti ko mọ nnkan kan nipa ogun lawọn ti wọn pa yii gẹgẹ bi alaye awọn Israel.
Nirọlẹ ọjọ Satide, aadọta ẹgbẹrun eeyan (50,000) fẹhonu han ni gbagede Tel Aviv, ti wọn pariwo pe ki wọn da awọn eeyan awọn pada wale, wọn kọ ọ sara awọn paali atọka ti wọn gbe dani ati sara aṣọ ti wọn wọ, ireti wọn ni pe adehun ẹlẹgẹ kan yoo ṣee ṣe.
Ijọba Isrẹli sọ pe jiju ọwọ silẹ ọjọ Satide yẹn jẹ kawọn ọdọ meji kan gba ominira ninu idile Or; meji mi-in gba itusilẹ lati ẹbi Weiss ( Ẹni ọdun mẹtalelaaadọta,53 ati mejidinlogun, 18 ni wọn pe wọn) meji lati idile Avigdori (Ẹni ọdun mejilelaaadọta (52) ati mejila (12) lọjọ ori wọn. Ati mẹrin lati idile Haran ati Shoham, to fi mọ ọmọ ọdun mẹta kan ati ọmọ ọdun mẹjọ mi-in.
Baba kan toun ati idile rẹ jẹ apa kan Irish ati Isrẹli, pada ri ọmọ rẹ, Emily Hand, ẹni to pe ọdun mẹsan-an nigba to wa nigbekun, sọ fun BBC pe binu oun ṣe dun to lati ri ọmọ oun obinrin pada, oun ti pinnu lati ṣe ohunkohun toun ba le ṣe lati mu awọn to ṣi wa nigbekun dari wale.
Awọn naa ni Raya Rotem, ti wọn fi ọmọ rẹ, Hila Rotem Shoshani, silẹ lọjọ Satide, ti wọn ko si yọnda iya yii. Itay Regev, to jẹ ẹgbọn fun Maya, ẹni ọdun mọkanlelogun (21) ti wọn ṣẹṣẹ fi silẹ naa ṣi wa nigbekun.
" Ọkan mi ti pin yẹlẹyẹlẹ nitori ọmọ mi ọkunrin, Itay, ṣi wa nigbekun Hamas ni Gaza" Bẹẹ ni Mirit Regev ti i ṣe iya ọmọ naa wi.
Ki wọn too maa yọnda awọn eeyan ni Gaza, Noam Sagi to jẹ ọmọ iya kan, Ada Sagi, ẹni ọdun marundinlọgọrin (75) to wa nigbekun ogun, sọ fun BBC pe, " A ṣi n duro de iwe awọn ti wọn maa fi silẹ lalẹ oni, boya orukọ iya wa maa wa nibẹ. Ifiyajẹni ni, gbogbo ẹbi wa lo n reti boya orukọ iya wa yoo wa ninu awọn ti wọn maa fi silẹ".
Ada Sagi ko si ninu awọn ti wọn fi silẹ lọjọ Satide.
Pupọ ninu awọn eeyan Palestine ti Isrẹli yọnda nigbekun lọjọ Ẹti, obinrin mẹrinlelogun atawọn ọdọkunrin mẹẹẹdogun ni wọn wa ni ibi ti wọn maa n kọkọ fawọn eeyan pamọ si ,ki wọn too ba wọn ṣẹjọ .
Ọkan ninu wọn, Sarah al-Suwaisa, ṣalaye pe Isrẹli yin taju-taju wọn si tun ge ina mọnamọna awọn ẹlẹwọn ki wọn too fi wọn silẹ.
O ṣapejuwe iwa naa bii eyi to yẹpẹrẹ eeyan, to baayan ninu jẹ, o ni Hamas nikan lo ṣeranlọwọ fawọn.
Awọn kan tun kora wọn jọ ni Beitunia lọjọ Satide lati gba awọn eeyan Palestine mi-in ti wọn tun gba iyọnda-Awọn obinrin atawọn ọdọ ti wọn ko si ọgba ẹwọn Ofer.
Ọpọlọpọ asia Hamas ni wọn ta sibẹ gẹgẹ bi akọroyin BBC Lucy Williamson ṣe jábọ̀.
Lara awọn ti wọn tu silẹ ni Nourhan Awad, ẹni ọdun mẹtalelogun (23), ti wọn mu ni 2015 lori ẹsun pe wọn fura si i pe o lọwọ ninu ìgúnbẹ kan to ṣẹlẹ ni Jerusalem.
Ọmọbinrin yii lo ọdun mẹjọ ninu ẹwọn ọdun mẹwaa ti wọn ran an lọ.
Bakan naa ni Israa Jaabis ṣe wa lẹwọn lati 2015, lẹyin ti mọto rẹ daṣẹ silẹ loju ọna marosẹ lagbegbe West Bank.
Ẹsun ti Isrẹli fi kan an nigba naa ni pe o n gbiyanju ati ju bọmbu si mọto ni, ṣugbọn itako ti wa lori eyi.
Ṣaa, Olootu ilẹ Thailand, Srettha Thavisin, sọ pe awọn ọmọ Thai mẹrin ti wọn fi silẹ lọjọ Satide n ṣe daadaa.
"Alaafia ni gbogbo wa wa, tọkan-tara wa n ṣiṣẹ daadaa, a si le sọrọ ja geere.''
Bẹẹ ni Olootu Thailand kọ ọ sori ayelujara.















