Kò sí ẹni tí yóò mọ̀ tí a bá kú – Àwọn èèyàn Gaza dárò ìkọlù lemọ́lemọ́

Abdelhakim by the ruins of his home

Oríṣun àwòrán, Abdelhakim

    • Author, Lara El Gibaly & Harriet Orrell
    • Role, BBC World Service

Eeyan mẹrin ni Gaza lo ti n ṣe akọsilẹ igbe aye awọn eeyan to n doju kọ ogun ni Gaza, eyii ti wọn fi n ṣọwọ si ileeṣẹ iroyin BBC.

Inu iroyin ti wọn fi n sọwọ si wa ni wọn ti n ṣalaye bi epi ṣe n pa awọn eeyan ati bi wọn ṣe n sa asala fun ẹmi wọn lọwọ ado oloro Israel.

Lati ọjọ keje, oṣu Kẹwaa ni awọn ologun Israel ti n ju ado oloro si Gaza, nibi ti nnkan bii ẹgbẹrun mẹwaa awọn ọmọ Palestine ti ku bayii, gẹgẹ bii ohun ti ileeṣẹ eto ilera ti Hamas n dari rẹ sọ.

Akọlu naa lo n waye ni esi si akọlu ti Hamas kọkọ ṣe si Israle, nibi to ti pa eeyan 1,400.

Ikilọ: O le ri awọn nnkan ti ko dun mọ ninu iroyin yii.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹwaa

Ọkọ ofurufu Israel ju awọn iwe pelebe si isalẹ fun awọn eeyan lati kuro ni Ariwa Gaza ko to ḅerẹ si n sọ ado oloro sibẹ.

Farida

Oríṣun àwòrán, Farida

Farida: Ẹni ọdun mẹrindilogun ni, olukọ si ni niluu Gaza.

O ni: Ile awọn aladugbo mi mẹta lo ti wo palẹ bayii. Gbogbo wa ni a nilo lati kuro nibi amọ ko si ibi ti a fẹ lọ.

A ṣi n duro de ọpọ awọn ọrẹ mi to di awati, o si ṣeeṣe ki wọn ti ku.

Farida atawọn ibatan rẹ kan, to fi mọ ọmọ wẹwẹ mẹfa ni wọn n fi ẹsẹ rin, ti wọn si n sun lẹba ọna. Erongba wọn ni lati rin kọja Wadi Gaza, nibi ti Israel ni ikọlu oun ko ni de.

Adam: Ọjọ kan naa ni Adam n gbiyanju lati fi agbegbe naa silẹ, eyii to jẹ igbiyanju rẹ karun un laarin ọjọ marun un.

O ni “Nnkan bii miliọnu eeyan ni wọn ki wọn fi Ariwa Gaza silẹ lọ ila oorun.

Adam

Oríṣun àwòrán, Adam

Ounjẹ, oogun ati epo bẹntiro lo ti ọwọngogo lẹyin ti Israel ti bẹrẹ si n gbogun ti Gaza, eyii to mu ko ṣoro fun Adam lati ṣetọju baba rẹ to ni arun ‘Parkinson.’

Khalid: Ẹni to n ta oogun nillu Jabalia, ni Ariwa Gaza.

Khalid kọ lati ko mọlẹbi rẹ kuro niluu naa bo tilẹ jẹ ikilọ ti jade pe ki wọn ṣe bẹẹ.

O ni “Nibo ni a fẹ lọ?” “Ko si ibi ti a fẹ lọ ti ko si wahala nibẹ, ko si.

“A maa ku ni igbẹyingbẹyin naa ni.”

Ko tii lanfani lati ko oogun lọ fun awọn onibara rẹ lati igba ti ogun naa ti bẹrẹ.

Ọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa

Ado oloro ba ọkọ to n ko awọn araalu ni adugbo Salah al-Din, ọgọtin eeyan lo ku nibẹ, ti pupọ ninu wọn jẹ obinrin atawọn ọmọ wẹwẹ.

A child's tricycle surrounded by dust and rubble, Gaza City, 15 October 2023
Àkọlé àwòrán, Ilu Gaza, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa

Bi ado oloro ṣe n balẹ ni Ila oorun, ọpọ awọn ọmọ Palestine lo pinnu lati ma fi ile wọn silẹ ni iha Ariwa.

Farida: Lẹyin to sun laarin ọna fun ọpọ ọjọ, Farida banujẹ.

O ni “Mi o mọ ohun ti mo le sọ bayii nipa bi ara mi ṣe ri. Oniruru ado oloro lo n balẹ ni agbegbe wa.

“Ti o ba sun lalẹ ni Gaa, o ko le sọ boya o ṣi maa wa laaye lọjọ keji tabi bẹẹ kọ. Mo ni lati maa mura de ado oloro lati oju orufuru to le waye nigbakugba.”

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹwaa

Ibugbamu to waye nile iwosan Al-Ahli ni Gaza gbẹmi eeyan to le ni 471. Awọn obinrin ati ọmọ wẹwẹ wa lara awọn to ba ado oloro naa lọ.

Abdelhakim: Lẹyin oṣu diẹ ti ogun naa bẹrẹ ni Abdelhakim pari nile ẹkọ giga gẹgẹ bii onimọ ẹrọ ‘software engineer.’

Ile awọn ogunlende ni Al Bureij lo n gbe ni aringbungbun Gaza.

Abdelhakim

Oríṣun àwòrán, Abdelhakim

O sọ ninu fidio kan pe “Ẹni ọdun mẹtalelogun ni mi, mo ṣi wa laaye bayii.

Mi o mọ boya aye yoo gbọ nipa mi ti mo ba ṣi wa laaye, o si ṣeeṣe ko jẹ awọn ọkọ ofurufu to n fo loke yii ni yoo pa mi.”

“A ko ni omi, ko si ogun, ko si ina ẹlẹtiriki atawọn nnkan mii ti a nilo.”

“Mi o tii jẹun fun odidi ọjọ mẹta gbako yatọ si burẹdi kan tie mi atawọn ibatan mi pin.”

“Koda, mi o tii sun ju orun wakati mẹwaa lọ laarin ọjọ mejila. O ti rẹ wa ṣugbọn a ko le sinmi nitori ẹru n ba wa.”

Ọjọ Ẹti, ogunjọ, oṣu Kẹwaa

Ado oloro Israel wo ile Abdelhakim, o si fi fidio ile naa ranṣẹ. Ọpọ eeyan lo n pounrere ẹkun labẹ fidio ọhun.

Abdelhakim: “Ni ṣe ni a joko ki a to gbọ iro ado oloro. Ori lo ko wa yọ ninu ile naa. Awọn alabagbe wa ṣi wa labẹ ile to dawo.

Iyanu ni pe emi atawọn ẹbi mi ṣi wa laaye titi di asiko yii… amọ a ti n kọ lara ile naa pada ki emi ati mọlẹbi mi le maa gbe ibẹ lọ.

Ọjọru, ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹwaa

Ado oloro mii ti balẹ si adugbo Abdelhakim bayii. Titi di asiko yii, ọmọ Palestine 6,972 ni ado oloro ti pa.

Abdelhakim: Inu mi bajẹ lọpọlọpọ bi mo ṣe n ri ẹran ara eeyan to fọnkan silẹ. Ko si ibi kankan ti a le salọ. Ko si ibi ti abo wa fun wa.

Adam: Ọna bi yoo ṣe wa ounjẹ oojọ fun awọn mọlẹbi rẹ lo mu ọmu laya rẹ.

O ni “Mo maa ni lati ji ni idaji lati lọ wa ounjẹ ti awọn ẹbi mi yoo jẹ lai si pe mo to sori ila fun ọpọ wakati.”

“Ti o ba dun ni ori ilẹ, inu rẹ ko le bajẹ to igba ti o ba n lọ tọrọ ounjẹ fun awoon mọlẹbi rẹ.

Khalid: “Ojojumọ ni wọn n ju ado oloro si wa, o si sọro lati jade lọ lati lọ wa ounjẹ ti a maa jẹ.”

Ko si ẹrọ amounjẹ tutu lti ko ounjẹ pamọ si, ounjẹ to ti bajẹ ni a n jẹ nitori pe ko ni ọna abayọ miran mọ.”

A cauliflower with insects crawling on it

Oríṣun àwòrán, Khalid

Àkọlé àwòrán, Ounjẹ ti awọn kokoro ti jẹ ni awọn naa n jẹ

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa

Oju opo ikansiraẹni ati ti ẹrọ ibaraẹnisọrọ ko ṣiṣẹ mọ ni Gaza, eyii to mu ko ṣoro fun awọn eeyan lati ba ara wọn sọrọ. O sọrọ fun BBC lati kan si Adam, Abdelhakim, Farida ati Khalid. Lẹyin ti nnkan pada bọ sipo ni wọn ṣalaye ohun ti oju wọn ri.

Ọjọ Aje, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹwaa

Ọkọ ogun ‘tank’ Israel gba Gaza lọ, eyii ti ọpọ eeyan foju ri loju ọna Salah al-Din, nibi ti awọn eeyan to n sa kuro ni Ariwa Gaza n gba kọja.

Khalid

Oríṣun àwòrán, Khalid

Àkọlé àwòrán, Khalid kọ lati fi Ariwa Gaza silẹ

Khalid:"Mi o ni fi ìlù yìí silẹ. Ohun tí a n ro bayii ni igba ti ado oloro mii yóò tún balẹ ki a lè sinmi."

Oro yii ni igba to gbẹyin ti a gbọ lati ọdọ Khalid ìyẹn lẹyìn tí ọkọ ofurufu Israel kan sọ ado oloro silẹ lati oke ni ọgbọn ọjọ, oṣù Kẹwàá.

O kere, ọgọrun ati eeyan kan lo ku ninu ikọlu náà, nigba ti eeyan 382 mii farapa gẹgẹ bíi nnkan ti ile iṣẹ ètò ìlera sọ.

Israel ni ọkan lára àwọn ọgagun Hamas loun n dojukọ.

*Ile iṣẹ ètò ìlera Gaza, eyii ti Hamas n darí rẹ ló sọ fún wa iye èèyàn tó kù latari ikọlu náà.

Afikun iroyin lati ọwọ Haya Al Badarneh and Mary O'Reilly