Ológun Israel fẹ̀sùn ìpànìyàn kan iléwòsàn lórí ikú àwọn tó wà nígbèkùn

Isreli

Awọn ologun ilẹ Isrẹli ti fi fidio kan sita, ninu eyi ti wọn ti sọ pe awọn eeyan ogun to wa nigbekun lawọn n ṣafihan rẹ bi wọn ṣe n gbe wọn lọ sileewosan nla to wa ni Gaza, lẹyin ikọlu Hamas to waye lọjọ keje, oṣu kẹwaa.

Agbẹnusọ awọn ṣọja naa tilẹ sọ pe inu ileewosan ọhun ni wọn pa ọkan ninu awọn si.

O ṣalaye pe inu ileewosan Al-Shifa to wa ni Gaza ni wọn ti pa Noa Marciano, ẹni ọdun mọkandinlogun, lẹyin to farapa ranpẹ, ti wọn si gbe e lọ si ọsibitu ọhun, ṣugbọn ti wọn ṣeku pa a ninu ọsibitu naa.

Awọn ologun yii fi kun un pe, awọn ti ṣawari ibudo kan ti Hamas n lo bii olu ileeṣẹ wọn tẹlẹ, ṣugbọn awọn Hamas sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ.

"Wọn gbe ọmọ-ogun Israel wọ ileewosan Shifa, ibẹ ni awọn apaayan Hamis si pa a si"

Ikọ iroyin BBC ko ti i le fidii fidio naa, tawọn ologun Israel (IDF) fi han awọn akọroyin nibi ipade oniroyin to waye lọjọ Aiku ọsẹ yii.

Agbẹnusọ awọn ologun Isrẹli, Daniel Hagari, sọ fawọn akọroyin pe, "A sọ fawọn ẹbi Noa pe, gẹgẹ bi iwadii wa, wọn ji i gbe nigba ti nnkan ko ṣe e, wọn si gbe e wọ ile kan nitosi Shifa.

" Nigba ti ija n lọ lọwọ lagbegbe naa, ajinigbe to gbe Noa ku, Noa naa si farapa diẹ.

Sugbọn ọgbẹ naa ko to ohun to le ṣeku pa a.

Wọn gbe Noa wọ ileewosan Shifa, ibẹ ni awọn apaayan Hamis mi-in si pa a si."

ileewosan Gaza

Ija ogun lo pa ologun Israel, kii se awa - Hamas

Bo tilẹ jẹ pe Hamas ti tako ẹsun yii ṣaaju, ti wọn si sọ pe ija ogun lo pa Noa lọjọ kẹsan-an oṣu kọkanla yii, Hagari ṣafihan fidio ikọlu naa, eyi to ni ọjọ keje oṣu kẹwaa lo waye.

O tẹsiwaju pe ọjọ keje oṣu kẹwaa naa ni Hamas kọlu Guusu Isrẹli lojiji, nibi ti wọn ti pa ọmọ Isrẹli ẹgbẹrun kan ati igba (1,200), ti wọn si tun mu ojilenigba (240) sigbekun.

Fidio naa ṣafihan awọn eeyan meji ti wọn ti mu sigbekun ogun, ti wọn n gbe wọn wọ ileewosan to tobi ju ni Gaza.

Bakan naa lo ṣafihan awọn ọkunrin ti wọn di hamọra ogun, ọjọ keje oṣu kẹwaa lo han ninu fidio yii.

Amẹrika ni oun ti ri awọn ẹri kan to n tọka si pe Hamas ti sọ awọn ileewosan Gaza di ibudo ti wọn n ko nnkan ogun si

Ọkan ninu awọn ti wọn mu sigbekun naa n ja lati gba ara rẹ silẹ, nigba ti fidio ṣafihan ẹnikeji rẹ to sun sori atẹ, ti wọn fi n gbe alaisan.

Latigba ti fidio yii ti jade ni wahala ti wa lọrun ikọ ologun Isrẹli (IDF) lati fi otitọ to wa nidii ẹsun yii mulẹ, pe loootọ ni Hamas ti sọ ileewosan Gaza di ibugbe iku.

Nigba ti wọn n sọrọ lorii fidio Isrẹli, awọn Hamas sọ pe awọn ko le fidi ohun ti wọn n wi naa mulẹ.

Wọn ni Isrẹli lo sọ ileewosan di ẹdun arinlẹ ni Gaza, ọwọ awọn ko si nibẹ rara.

Bakan naa ni orilẹ-ede Amẹrika sọ pe oun ti ri awọn nnkan kan, to n tọka si pe Hamas ti sọ awọn ileewosan Gaza di ibudo ti wọn n ko nnkan ogun si, titi to fi mọ ileewosan Al-Shifa.

12,300 oku ni wọn pa ni Gaza, 2000 oku mii lo wa labẹ ile awoku ti ado Israel kọlu - Hamas

Awọn alatilẹyin Isrẹli fọwọ si idojukọ ti wọn yoo fi ṣẹgun Hamis loootọ, ṣugbọn wọn ni nnkan ko dẹrun, awọn alaiṣẹ n ba a lọ gidi.

Nipa iye eeyan to ti doloogbe, awọn eleto ilera Hamas sọ pe o ti to ẹgbẹrun mejila ati ọọdunrun (12,300) nigba ti ẹgbẹrun meji eeyan ti ku sabẹ ile tẹnikan ko ri wọn gbe sin.

Bi eyi ṣe n waye ni awọn eeyan n beere fun itusilẹ awọn to wa nigbekun ogun wọnyi.

Wọn fẹ ki ijọba Benjamin Netanyahu ti i ṣe Olootu ilẹ Isrẹli wa nnkan ṣe ni kia, kawọn to wa nigbekun Hamas le gba ominira.

Lọjọ Satide to kọja lawọn kan fẹhonu han, ti wọn fẹsẹ rin lati Tel Aviv de Jerusalem, ki wọn too fẹhonu han taara niwaju ile Netanyahu gan-an

Ninu ọrọ Netanyahu, o ni afojusun ohun akọkọ ni lati ṣẹgun Hamas, ikeji ni lati tu awọn to wa nigbekun silẹ, ikẹta si ni kawọn bọ lọwọ idunkooko to n ti Gaza wa.