Àwọn agbébọn jí èèyàn tó lé lọ́gọ́rùn-ún gbé ní Zamfara

Zamfara

Awọn ara abule Mutunji, nijọba ibilẹ Maru, nipinlẹ Zamfara ti sọ pe o le lọgọrun-un eeyan tawọn agbebọn gbe wọgbo lọ niluu naa lalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kọkanla ọdun 2023 yii.

Awọn olugbe abule Mutunji sọ fun BBC pe lẹyin tawọn kirun to gbẹyin lalẹ ọjọ naa, ni ọga awọn agbebọn torukọ rẹ n jẹ Damina, ko awọn agbebọn rẹpẹtẹ wọlu ti wọn si bẹrẹ rogbodiyan.

Eeyan to le lọgọrun ni wọn ko wọgbo bawọn araalu Mutunji ṣe wi, obinrin atawọn ọdọ lo si pọ ninu wọn.

Wọn fi kun un pe Damina to ko awọn agbebọn wọlu naa ko ṣẹṣẹ maa ṣe bẹẹ, wọn ni aadọta miliọnu (50m) to ni kawọn san lo ṣe ko awọn ọmọ ogun rẹ wa.

‘’Wọn ba awọn ọkọ wọya ija ki wọn to ko awọn eeyan wa wọgbo lọ’’

Ẹnikan to jajabọ lọwọ awọn agbebọn naa sọ pe wọn kọkọ fi lulu ṣe tawọn ọkurin ilu naa ki wọn too maa ko awọn eeyan wọgbo lọ.

O ṣalaye pe Damina lawọn le pe ni agbowo-ipá ni gbogbo Mutunji ati agbegbe rẹ, nitori o maa n paṣẹ pe kawọn samwo ori onimiliọnu pupọ ni.

Ọkunrin yii tẹsiwaju pe awọn abule mi-in tun wa nitosi Mutunji ti ọga awọn agbebọn yii ti gbowo nla.

O lo fipa gba miliọnu lọna ọgbọn (30m) lọwọ awọn ara abule Kwana, ogun miliọnu lọwọ awọn eeyan abule Sabon Mahuta, o si gba miliọnu mẹwaa naira lọwọ awọn ti Unguwar Kawo.

‘’Aadọta miliọnu ti wọn fẹẹ gba naa la n ṣa jọ lọwọ ti fi ko awọn eeyan wa wọgbo lọ’’

Awọn olugbe abule Mutunji ṣalaye pe aadọta miliọnu naira ti Damina fẹẹ gba bii owo ori lawọn n ṣa jọ lọwọ to fi de pẹlu awọn ikọ ogun rẹ, to si pada ko awọn eeyan wọgbo lọ.

Wọn ni ọsẹ kan lo fawọn lati ṣa owo ọhun jọ, nigba tọsẹ kan pe lo ṣigun waa ba awọn bi eyi.

"Awọn agbebọn lo n dari agbegbe wa ni ka sọ, a o lagbofinro kankan.

‘’Wọn maa n ko wa lọ sinu igbo lati lo wa bii alagbaṣe.

‘’Ti wọn ba wọ aarin ilu, wọn a jẹran ọfẹ, wọn a mu tii atawọn ounjẹ inu agolo, wọn o ni i sanwo fun wa.

"Ipo aibalẹ ọkan la wa, nnkan ko dẹrun fun wa rara ‘’

Bẹẹ lawọn eeyan Abule Mutunji sọ.

Ko ti i si atẹjade latọdọ awọn agbofinro nipa iṣẹlẹ yii lasiko ta a pari akojọpọ iroyin yii.