Ṣe loootọ ni pe wọn ri oku 322 ní Anambra? Ohun ti a mọ ree

Bi iroyin kan ṣe n ja ran-in nilẹ pe ko din ni oku okoolelọọdunrun ati meji (322) ti ibojì wọn si foju han nipinlẹ Anambra, Bianca Ojukwu, tii se yawo Oloogbe Emeka Ojukwu to n beere fun ijọba Biafra nigba kan, ti sọ pe nnkan irira ni bi iroyin naa ṣe n tan kalẹ .
Bianca, to tun jẹ Akọwe ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Truth, Justice and Peace Commission (TJPC), ṣalaye, pe otitọ ni pe wọn ri awọn iboji nitẹ oku nipinlẹ Anambra.
O ni ṣugbọn onka oku 322 ti ọpọ awọn ileeṣẹ iroyin n gbe jade ki i ṣe otitọ.
Bianca fidi ẹ mulẹ, pe ko ti i seeyan to le sọ pato iye oku ti wọn ri ninu awọn iboji naa.
O ni iwadii lọna imọ ijinlẹ Sayẹnsi yoo waye lati mọ iye to jẹ gan-an.
Akọwe ẹgbẹ TJPC naa fi kun un pe onka 322 yii jẹ ti awọn asiko ti ọpọ eeyan ṣubu lera wọn l'Anambra, ti awọn mi-in ku, ti awọn kan si di awati ninu awọn iṣẹlẹ naa. Awọn eeyan ti wọn sọnu gẹgẹ bi akọsile to mejidinlogun.
O wa gba awọn ẹbi teeyan wọn ba sọnu nimọran lati kan si ẹgbẹ yii fun iranlọwọ
Iwadii sọ pe eeyan 322 to sọnu lọwọ ninu awọn akitiyan asiko naa
Ẹgbẹ TJPC ti Bianca n ṣe akọwe rẹ yii bẹrẹ isẹ loṣu kẹfa ọdun 2022, Gomina Chukwuma Soludo lo si fi lelẹ nigba naa.
Iṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ ni lati ṣewadii rogbodiyan to n waye nipinlẹ Anambra.
Ẹgbẹ TJPC ṣalaye iwadii kan ti wọn lawọn ṣe nipa ifọrọwanilẹnuwo laarin ilu, ati lawọn ileeṣẹ, wọn ni iwadii naa lo sọ pe eeyan 322 lọwọ ninu awọn akitiyan asiko naa.
Wọn gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo maa ri si ọrọ awọn eeyan to sọnu ('Bureau of missing persons')
Igbimọ naa ni yoo maa sapa lori bi wọn yoo ṣe ri awọn eeyan wọnyi pada.
Wọn wa rọ awọn akọroyin lati maa ṣewadi ohun ti wọn n gbe jade wo fin-ni-fin-ni, ki wọn ma baa maa ko araalu laya soke lori ofege iroyin.
Tẹ o ba gbegbe, eto aabo lapa Ila-Oorun orilẹ-ede yii ti n mẹhẹ fawọn asiko kan, eyi ti ipinlẹ Anambra jẹ ọkan lara wọn.
Aabo to mẹhẹ naa fa iku araalu atawọn agbofinro l'Anambra, eyi ti Gomina Chukuwma Soludo si n ja raburabu lati kapa rẹ bi wọn ṣe sọ












