Kí ló dé tí Isbae-U, aláwàdà lórí ayélujára gba omíjé lójú àgbà òṣèré tíátà?

Aworan BaeU ati Tola Oladokun

Oríṣun àwòrán, ISBAEU

Gbajugbaja adẹrinposonu nni, Adebayo Ridwan, ti ọpọ mọ si Isbae-U gba ọna iyalẹnu yọ si ilumọka oṣere tiata lobinrin, Tola Oladokun, eyi to mu omije bọ loju rẹ.

Gẹgẹ bii fọnran ti Isbae-U fi lede lori ayelujara, o ransẹ pe gbajugbaja oṣere naa lati wa si ile rẹ fun isẹ kan ti wọn jọ fẹ se papọ.

Kete ti Tola Oladokun wọle joko ni Isbae-U n dibọn bi ẹni pe o n tọ mama naa sọna lori bi wọn yoo ṣe jọ se ere sinima naa.

Sugbọn ohun iyalẹnu lo jẹ nigba ti onilu ati elewi sadede wọle lati bẹrẹ si ni maa ki agba oṣerebinrin naa.

Se ni omije nla bọ loju gbajugbaja oṣere tiata naa nigba ti Isbae-U tun fi ounjẹ ta lọrẹ ati owo toto ẹgbẹrun lọna igba naira.

Ki lo de ti Isbae-U fi gba omije loju Tola Oladokun plu is aanu yii?

Ninu ọrọ rẹ, BaeU ni oun fẹ dupẹ lọwọ Tola Oladokun fun isẹ ribi ribi to ti n ṣe ninu agbo sinima, ti oun si jẹ ọkan lara awọn ololufẹ sinima to n ṣe sita.

“Ọkan lara ololufẹ yin ni mo jẹ, agba ọjẹ ti wa ni ẹ jẹ ninu ere sinima, o dẹ di dandan ka ṣe iwuri fun yin pupọ.

“Ko ki n ṣe pe ẹ tọrọ owo lọwọ mi tabi ẹ tọrọ ounjẹ lọwọ mi, isẹ ti mo ba pe yin fun, ẹ ma wa ba mi ṣe, ma dẹ fun yin lowo,

“Emi ati yin ni ibaṣepọ ọmọ ati iya, isẹ temi ni lati dupẹ lọwọ yin fun isẹ ribiribi ti ẹ ti ṣe, fun idi eyi, mo ma fun yin ẹgbẹrun lọna igba naira.”

Pẹlu omije ni Tola Oladokun fi gbadura fun BaeU pe yoo dagba, yoo si ṣe aseyọri bi o ṣe mu inu oun dun pẹlu oore ojijito gba omije loju oun naa.

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

Aworan Tola Oladokun

Oríṣun àwòrán, Instagram/iyajenifah_tolaoladokun/

Ta a ni Tola Oladokun?

Owomitola Oladokun jẹ gbajugbaja oṣere tiata, olootu sinima ati agbohunsafẹfẹ lori redio.

Ọdun 1959 ni wọn bi ilumọka yii niluu Igangan nipinlẹ Oyo.

Tibi Tire ni sinima akọkọ ti yoo kopa ninu rẹ sugbọn o di ilumọka ninu sinima kan ti orukọ rẹ n jẹ Jenifa, ni bi to ti n jẹ ‘Iya Suliya.

Ninu ọrọ rẹ pẹlu BaeU, Tola Oladokun ni oun ṣe ajọyọ ọdun marundinlogoji ti oun ti bẹrẹ sinima ni ọdun mẹfa sẹyin.

O sọ fun BaeU pe ọjọ ti inu oun dun ju ni ọjọ ti oun ko lọ si ile ti oun kọ.

Aworan Adebayo Ridwan

Oríṣun àwòrán, @ISBAE-U

Ta ni Isbae U?

Adebayo Ridwan tí ọpọlọpọ mọ si Bae U Barbie jẹ adẹrinpoṣonu lorí ayelujara ti Instagram.

O jẹ ọmọ gbajugbaju oṣere tiata to ti di oloogbe, Kamal Adebayo ti ọpọ si Sir Kay.

Bae U ni oun bẹrẹ ere ipanilẹrìn lẹyìn tí ironu fẹ pa oun sile.

O ni funra oun lo n tọju ara oun, kí Ọlọrun to fi ọna iṣẹ ti oun n ṣe han oun.

Bakan naa lo maa n ṣere ìtage.