Ìbí tí ọ̀rọ̀ kángun sí rèé lẹ́yìn tí ààrẹ Tinubu dá sí aáwọ̀ láàrin Akeredolu àti Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, newsbeat.ng
Bi ko ba si iyipada kankan o ṣeeṣe ki Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti yanju aawọ to n waye laarin Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu ati igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa.
Ojutu si ọrọ yi ko ṣẹyin ipade kan ti aarẹ ṣe nile ijọba lAbuja lalẹ ọjọ Ẹti ọsẹ yii nibi ti Aarẹ ti ni ki awọn ti ọrọ naa kan gba alaafia laaye.
Nibi ipade naa la ti ri Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Ondo, Ọladiji Ọlamide,igbakeji Gomina Ondo, Lucky Aiyedatiwa, alaga ẹgbẹ oṣelu APC Abdullahi Umar Ganduje.
Nibi ipade yi si ni olori ile aṣofin ipinlẹ naa ti kede pe awọn ti dawọ igbesẹ ati yọ Aiyedatiwa nipo duro.
Eyi waye lẹyin afẹnuko wọn nibi ipade naa to gba wọn to wakati mẹfa.
Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Ondo to ka abajade ipade alaafia naa seti awọn akọroyin ṣalaye pe, ’’Akọkọ, a maa gba alaafia laaye, ikeji, a ko ni i tule ka mọ, igbakeji gomina yoo maa ba iṣẹ lọ gẹgẹ bi afẹnuko ile aṣofin’’
Koko pataki nkan mii ti aarẹ ni ki wọn ṣe lẹyin ipade yii
Yatọ si pe aarẹ ni ki wọn dawọ iyọni nipo igbakeji Gomina Aiyedatiwa duro, aarẹ tun paṣẹ pe ki Aiyedatiwa maa ba iṣakoso ipinlẹ naa lọ titi ti Gomina Akeredolu yoo fi pada sipo.
Bẹẹ naa lo sọ pe ki wọn ko gbogbo awọn ọlọpaa ti wọn ko di ẹnu ọna ile aṣofin kuro ni kiakia.
Iyanju aawọ yi lọjọ Ẹti waye lẹyin nkan bi ọjọ meji ti awọn agbaagba ipinlẹ Ondo kesi aarẹ pe ki o tara dasi ọrọ awuyewuye Ondo yi ki o ma ba fa idẹnukọlẹ iṣejọba.
Wọn tun kesi adari ẹgbẹ oṣelu APC ki wọn ṣe itọsọna fawọn ti ọrọ kan ki onikaluku baa le tọwọ ọmọ rẹ bọ aṣọ.
Ninu iwe ti wọn kọ si aarẹ, awọn to ṣagbatẹru ọrọ yi, Reuben Fasoranti ati akọwe Bakkita Bello rọ awọn ile aṣofin lati ma ṣe yọ Gomina tabi igbakeji rẹ nipo.
Lati igba ti Gomina Akeredolu pada de lati irinajo nibi to ti lọ gba itọju ni wahala ti bẹ silẹ nipinlẹ Ondo.
Ọsẹ akọkọ ninu oṣu kẹsan ni Akeredolu pada de si Naijiria lẹyin oṣu mẹta to si ti n ṣe akoso ijọba lati ilu Ibadan tii ṣe olu ilu ipinlẹ Oyo.
Aiyedatiwa ṣeleri pe oun ko ni i yọ awọn kọmiṣanna sẹyin ninu iṣejọba Ondo
Aiyedatiwa ti wọn ti fẹẹ yọ nipo tẹlẹ naa wa ṣeleri, pe oun ko ni i yọ awọn kọmiṣanna atawọn alaṣẹ ẹka kọọkan sẹyin ninu iṣejọba Ondo.
O lawọn yoo jọ maa tukọ ipinlẹ naa lọ sibi giga ni.
’’ Mo jẹjẹẹ fun gbogbo yin pe mo maa fa yin mọra, gbogbo ohun to ṣẹlẹ sẹyin ti kọja lọ, mo ti jawọ nibẹ mo si gba f’Ọlọrun, gẹgẹ bi ijọba apapọ ṣe gba wa nimọran.
“ Mo si fẹẹ sọ fun yin pe ko si ibinu lọkan mi bo ti wu ko kere mọ. Oṣelu ni gbogbo ohun to waye kọja. Ara oṣelu ni iyọni-nipo wa, bi eeyan ba bori ẹ, ọsẹlu naa ni. O ti wa, mo ti bori rẹ, ohun atijọ ti re kọja lọ.’’
Bẹẹ ni Aiyedatiwa ti ṣe wi.
O wa rọ awọn igbimọ alaṣe lati fọwọsowọpọ pẹlu Akeredolu ati oun naa, kawọn le mu ere ijọba demokresi wa si imuṣẹ fawon eeyan ipinlẹ Ondo.
Aiyedatiwa fọwọ sọya lati bọwọ fẹgbẹ oṣẹlu APC, o loun mọ pe ẹgbẹ ju ẹnikẹni lọ, oun yoo si fun un ni ọ̀wọ̀ rẹ.














