Àwọn gómìnà Yorùbá kàn sí Akeredolu n‘Ibadan, wọ́n jíròrò lórí àgbéga Nàíjíríà àti ilẹ̀ Káàrọ̀ Oòjire

Oríṣun àwòrán, Facebook/Aketi
Alaga fun awọn gomina ni iwọ oorun guusu Naijiria, ẹni to jẹ gomina fun ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu gba alejo awọn Gomina akẹgbẹ rẹ lati wọ oorun guusu Naijiria laana niluu Ibadan.
Gẹgẹ bi atẹjade ti agbẹnusọ gomina nipinlẹ Ondo, Richard Olatunde fi ransẹ si awọn akọroyin, o ni awọn gomina naa wa lati wa ba Gomina Akeredolu jiroro lori ọrọ to jẹ mọ orilẹede Naijiria ati ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.
Lara awọn gomina to ṣe abẹwo si Gomina Akeredolu ni, Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo, Babajide Sanwoolu ti ipinlẹ Eko, Dapo Abiodun lati ipinlẹ Ogun ati Biodun Oyebamiji lati ipinlẹ Ekiti.
Akeredolu kan sara si awọn gomina fun isọkan ti wọn gba laye lai wo pe wọn ko ki n ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu kana, ti ilọsiwaju si wa kaakiri gbogbo ipinlẹ mẹfẹfa ni iwọ oorun guusu Najiria.
"Inu mi dun lati gba awọn gomina lati iwọ oorun guusu Naijiria, ti a si jiroro lori awọnh ọrọ to ni ṣe pẹlu orilẹede Naijiria ati awọn ipinlẹ wa lapapọ."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post

Oríṣun àwòrán, Facebook/Aketi
Ti a ko ba gbagbe saaju ni Gomina Akeredolu pada si orilẹede Naijiria lẹyin to lo ọpọlọpọ ọjọ loke okun ni bi to ti lọ gba itọju ara rẹ.
Bakan naa ni awọn ẹgbẹ PDP kesi ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo lati rọ Akeredolu loye nitori ilera rẹ ko fun un ni anfani lati le ṣe ijọba.
PDP ni o ku diẹ kato fun Gomina Akeredolu lati mule si Ilu Ibadan to jẹ olu ilu ipinlẹ Oyo dipo ko wa ni ilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo.
Sugbọn olubadamọran fun Gomina lori ọrọ isẹ akanṣe, Doyin Odebowale wa fesi pada idi ti Akeredolu fi wa niluu Ibadan ni sẹyin kudiẹkudiẹ to ba ile ijọba ipinlẹ Ondo lọwọlọwọ bayii.
Odebowale ni atunṣe ti bẹrẹ si ile naa, ti Gomina yoo si pada si ipinlẹ Ondo liapẹ
O fidi rẹ mulẹ bi Gomina ṣe wa niluu Ibadan ko di siṣe isẹ lọwọ rara















