Fídíò ṣàfihàn bí òṣìṣẹ́ kan ṣe ń tọ̀ sínú táńkì tí wọn fi ń ṣe ọtí bíà

Aworan ọti Tsingtao

Oríṣun àwòrán, Getti Image

Awọn alakoso orileede China ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori fọnran kan to tẹ wọn lọwọ, nibi ti wọn ti ri ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ipọnti Tsingtao, nibi to ti n tọ sinu agba ọti wọn, lasiko ti iṣẹ n lọ lọwọ.

Ẹgbẹgbẹrun awọn eeyan la gbọ pe wọn ti wo fọnran ibi ti oṣiṣẹ naa ti n tọ sinu agba to kun fun eroja ọti ti wọn n ṣe lọwọ lati ta fun awọn araalu.

Ọti Tsingtao lo gbajumọ daadaa lorileede China, to si jẹ pe ọti naa ni pupọ awọn eeyan fẹran ju lati maa mu, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Ọkunrin to n tọ sinu agba bia

Oríṣun àwòrán, Screen shot

"Ọkunrin to tọ sinu agba ọti ati ẹni to ya fọnran naa kii ṣe oṣiṣẹ ileeṣẹ wa taara"

Awọn alakoso ileeṣẹ naa sọ pe ni kete ti fọnran naa ti tẹ awọn lọwọ, ni awọn ti ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo lati bẹrẹ iṣẹ iwadii lori rẹ.

Ileesẹ Tsingtao ni gbogbo ọti ti oun ṣe lasiko ti oṣiṣẹ naa lọ tọ sinu agba ọti, ni awọn ti gbesẹ le, ko ma ba a jade sita fun tita.

Ninu fọnran naa to jade l’Ọjọbọ to kọja, ni wọn ti ri ọkunrin kan to wọ aṣọ ileeṣẹ naa, pẹlu fila idaabobo, to si gun ogiri to yi agba ọti naa ka, ko to bẹrẹ sii tọ sinu ẹ.

Ileeṣẹ iroyin The Paper to gbe iroyin naa jade lọjọ Ẹti ṣapejuwe idanimọ ara fọnran naa gẹgẹ bii "Tsingtao beer No.3 factory".

Bakan naa, iwe iroyin National Business Daily ninu iroyin wọn sọ pe ọkan lara awọn alakoso ileeṣẹ Tsingtao, ti wọn ko darukọ rẹ sọ pe, ọkunrin to tọ sinu agba ọti ati ẹni to ya fọnran naa kii ṣe oṣiṣẹ ileeṣẹ wọn taara.

Atẹjade ti ẹka to n sakoso kata-kara ọja ati akoso osisẹ nillesẹ Tsingtao to wa niluu Pingdu fisita ni wọn ti gbe igbimọ oluwadii dide, ti wọn si ko gbogbo ọti ti wọn ṣe laarin asiko naa pamọ.

Atẹjade naa fikun pe, awọn ko nii fi ọwọ yọbọkẹ mu ọrọ naa, ni kete ti awọn ba ti pari iwadii wọn, ni ẹni to huwa ibajẹ naa yoo foju wina ofin.

BBC ti ba awọn alakoso ileeṣẹ naa sọrọ, wọn si ti jẹ ko di mimọ pe awọn ko nii foju fo ọrọ naa.

Wọn ni ileeṣẹ naa gbajugbaja daadaa kaakiri orileede China ati agbaye.