Ààrẹ Niger, Bazoum gbìyànjú láti sá mọ́ àwọn adìtẹ̀gbàjọba tó fi sí àhámọ́ lọ́wọ́ ṣùgbọ́n...

Aworan aarẹ Bazoum

Oríṣun àwòrán, Getty

Ijọba ologun orileede Niger ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ Aarẹ orileede naa tẹlẹ ti wọn gba ijọba lọwọ rẹ, Mohamed Bazoum, lasiko to fẹ sa mọ wọn lọwọ ni ahamọ to wa.

Agbẹnusọ ologun kan lo kede ọrọ naa, to si ni asiko ti Mohamed Bazoum n gbiyanju lati sa pẹlu awọn ẹbi rẹ, awọn to n dana ounjẹ fun un ati awọn ẹṣọ rẹ ni aṣiri tu sita, ti wọn si ko wọn.

Wọn ni ọkọ baluu agberapa ti a mọ si helicopter ni wọn fẹẹ fi salọ kuro lorileede naa, ko to di pe ọwọ tẹ wọn.

Lati igba ti wọn ti gba ijọba lọwọ Bazoum lo ti wa ninu ile, nibi ti ko ti le jade lọ sibikibi.

Nigba to n sọrọ naa lori ẹrọ amohunmaworan, Amadou Abdramane to jẹ agbẹnusọ awọn ologun aditẹgbajọba orileede naa sọ pe nnkan bi aago meji oru ni Mohamed Bazoum gbiyanju lati salọ pẹlu ẹbi ẹ, awọn meji to n dana fun un ati awọn ẹṣọ aabo rẹ ti wọn wa lahamọ inu ile

O ni gbogbo igbiyanju aarẹ ọhun lo foriṣanpọn, ati pe gbogbo awọnto gbimọran pẹlu rẹ lati salọ naa lọwọ ti tẹ, ti wọn yoo si fi imu wọn danrin.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe agbegbe kan to wa ni Niamey, lẹyin odi Niger l’awọn eeyan naa n gbiyanju lati lọ fi arapamọ si, gẹgẹ bi iwadii to tẹ wọn lọwọ.

O ni awọn ọkọ baluu agberapa (Helicopters) to jẹ ti awọn alagbara lati apa Naijiria ni wọn fẹẹ fi ko awọn eeyan naa kuro ni Niger, to si bu ẹnu atẹ lu igbesẹ Bazoum naa.

Bi a ko ba gbagbe, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2023 ni awọn ologun ditẹ gba ijọba lọwọ Aarẹ Mohamed Bazoum, to si jẹ pe latigba naa lo ti kọ lati kọwe fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi Aarẹ.

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la ko tii mọ ibi ti wọn ko Aarẹ tẹlẹ naa ati awọn eeyan rẹ pamọ si.

Ko pẹ ti wọn gba ijọba lọwọ Mohamed Bazoum, ni Aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden ti pe awọn ologun to ṣe igbajọba yii lati fi silẹ kuro ni ahamọ, lati le daabo bo eto iṣejọba awa-ara-wa ti wọn fi ọjọ pipẹ jiya fun.

Bẹẹ naa ni ajọ Ecowas ti Aarẹ Bola Tinubu Naijiria ti dunkoko mọ awọn ologun yi lati tu Bazoum silẹ amọ wọn keti ikun.

Ohun taa gbọ kẹyin ni pe awọn ọmọ ogun ajọ Ecowas n gbero lati kogun ja awọn aditẹgbajọba yi bi wọn ko ba da ijọba pada fun Bazoum.

Titi di akoko yi, a ko mọ igbesẹ to kan lori gbigba akoso ijọba pada fun Bazoum.