Àláfíà ni Ààrẹ Bazoum wà ní àhámọ́ tó wà ṣùgbọ́n..

Aworan Aarẹ Mohamed Bazoum

Oríṣun àwòrán, AFP

Aarẹ Niger ni wọn ti kede pe lakọ lo wa ni ahamọ ikọ ologun to ditẹgbajọba lẹyin ti dokita se abẹwo si.

Mohamad Bazoum, ọmọ rẹ ọkunrin ati Iyawo rẹ ni awọn wa ni abẹ agbala wọn ni Niamey lati ọjọ kẹrindinlogoji oṣu keje.

"Ibi ti wọn fi wọn pamọ si ko dara rara, wọn ti yọ ina." Eyi ni ọrọ Dokita lasiko to n ba ileeṣẹ oniroyin lati orilẹede France sọrọ.

Abẹwo ọhun ni ijọba tuntun buwọlu lẹyin ti ọpọ awọn olori orilẹede bẹrẹ si ni pe fun itusilẹ Aarẹ ati mọlẹbi rẹ.

Ileeṣẹ iroyin RFI ni abẹwo yii lo jẹ igba akọkọ ti Aarẹ Bazoum yoo gba alejo lẹyin ti wọn gba ijọba lọwọ rẹ.

Bazoum, ẹni ọdun mẹtalelọgọta ni iroyin ni o ru gan, ti ọmọ rẹ, ẹni ogun ọdun si wa ni idubulẹ aisan sugbọn ti wọn ko ni anfani si itọju.

"Dokita ni anfani lati ba Aarẹ sọrọ, pẹlu Iyawo ati ọmọ rẹ."

Bakan naa ni dokita gbe ounjẹ ati oogun lọ fun wọn ni ahamọ.

Lẹyin abẹwo naa, Aarẹ Bazoum jẹ ko di mimọ pe ọkan oun balẹ.

Igbesẹ ijọba tuntun ti Ọgagun Abdourahamane Tchiani n dari lati fi aye silẹ fun dokita lati se abẹwo Aarẹ ati mọlẹbi rẹ ko sẹyin ipe ti ghogbo agbeye n pe fun pe ki wọn tu Aarẹ naa silẹ.

Ọmọ obinrin Aarẹ Bazoum, Zazia, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ti ko si ni ile lasiko iditẹgbajọba naa ni awọn mọlẹbi oun ko ni anfani lati mu omi to mọ, tabi ri ina mọnmọna, ti wọn ko si ri ounjẹ gidi jẹ.

O ni gbogbo ounjẹ gidi ti awọn ko sinu ẹrọ amu nnkan tuntun lo ti bajẹ nitori ko si ina mọnamọna.

"Ipo ti awọn mọlẹbi wa nira pupọ sugbọn wọn ni awọn ko dẹkun ija fun nnkan to tọ sugbọn o nira fun lati ri mọlẹbi ninu isoro.