Ènìyàn mẹ́jọ́ kú níbí ìsẹ̀lẹ̀ òrùlé mọ́ṣálásí tó wọ́ lulẹ̀

Oríṣun àwòrán, AMMAR RAJAB
Eniyan mẹjọ ti gbẹmi mi lẹyin ti orule mọṣalaṣi to wọ lulẹ le awọn eniyan lori ni Zazzau, ni Zaria.
Iṣẹlẹ yii waye lasiko ti awọn eniyanlọgọọrọ wa ni Mọṣalasi ni Ọjọ Jimọh, ti wọn n kirun.
Iwadii ti bẹrẹ lori ohun to fa iṣẹlẹ orule to wọ naa, amọ Emir sọ fun awọn oniroyin pe lati Ọjọbọ ni ẹgbẹ kan lati ogiri naa ti la, ki iṣẹlẹ orule to wo naa to waye.
Mọṣalasi naa ni wọn ni o ti le ni ọgọrun un, ti kii si ṣe igba akọkọ niyii ti awọn ile n wọ ni orilẹede Naijiria.
Agbẹnusọ fun Emir, Abdullahi Kwarbai ni oku eniyan mẹrin ni wọn kọkọ ri , ki wọn to wa riu mẹta miran.

Oríṣun àwòrán, AMMAR RAJAB
Awọn mẹta ti wọn ri naa ni awọn adoola ẹmi ri lasiko ti wọn n doola ẹmi awọn eniyan to ha si abẹ orule to wọ naa.
Nibayii, Emir, Mallam Ahmed Nuhu Bamalli ni awọn ti gbe awọn onimọ ẹrọ nipa ile kikọ lati wa ṣe atunṣe to yẹ ninu Mọṣalaṣi naa.
Ni alẹ ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye ni wọn sin oku awọn to doloogbe naa ni ilana ẹsin Musulumi, ti ojo si n rọ lasiko naa.
Agbẹnusọ fun Emir ni awọn eniyan mẹjọ ni wọn sin oku wọn, ti awọn eniyan mọkanlelogun si farapa, ti wọn si n gba iwosan ni ileewosan.

Oríṣun àwòrán, AMMAR RAJAB
Bakan naa lo fikun un pe afọju ati ọmọ to n mu mọna wa ninu awọn to ku ninu iṣẹlẹ naa.
Ninu ọrọ rẹ, o ni Emir ko si ninu mọṣalaṣi naa nigba ti iṣẹlẹ naa waye.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ni ile alaja meji ti wọn n kọ ofurufu rẹ lọwọ lo wọ le ori orule mọṣalaṣi naa, to fi wolu awọn eniyan mọle, to si gba ẹmi awọn eniyan.
Fidio to wa lori ayelujara ṣafihan bi orule aarin Mọṣalaṣi naa lo ṣe si nibẹ, ti wọn si le ri ofurufu lati inu mọṣalaṣi ọhun.

Oríṣun àwòrán, AMMAR RAJAB

Oríṣun àwòrán, AMMAR RAJAB












