Wo nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa oògùn Alabukun àti ọkùnrin tó kọ́kọ́ po oògùn náà

Oríṣun àwòrán, oldnaija
Ọpọ eeyann lo mọ oogun ti wọn n pe Alabukun, amọ iwọmba kereje eeyan lo mọ itan to wa nidi oogun ọhun.
Alabukun jẹ ọkan lara awọn oogun to pẹ julọ ni Naijiria, bẹẹ si ni oogun ọhun si niyi laye ode oni lẹyin ọdun gbọọrọ ti wọn ti n po.
Oogun Alabukun milẹ titi ni Naijiria, bakan naa ni wọn mọ lawọn orilẹ-ede mii bii Amẹrika, ilẹ Gẹẹsi ati China.
Lai ṣe ipolowo kankan tabi ipolongo, Alabuku jẹ oogun ti tọmọde-tagba mọ lati aye atijọ titi di aye ode oni.
Ta lo wa nidi oogun Alabukun?
Ọpọ eeyan ni ko mọ Oloye Jacob Odulate, ti apẹle rẹ n jẹ “Blessed Jacob” to jẹ gbajumọ apoogun nigba aye rẹ.
Ọkunrin ọhun lo kọkọ ṣawari eroja oogun alabukun, to si kọkọ po oogun naa.
Wọn bi jacob Odulate ni ọdun 1884 niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko.
Nigba to wa lọmọ ọdun mẹrinla lo pinnu pe oun yoo jẹ nnkan laye, eredi ree to fi fẹsẹ rin lati Eko si Abeokuta nibi to ti bẹrẹ owo oogun pipo ati oogun tita.
Bi Alabukun ṣe bẹrẹ

Oríṣun àwòrán, others
Ọdun 1918 ni Jacob Odulate joko ninu laabu rẹ to ti n po oogun pọ lati kọ awọn eroja ti yoo po alabukun lọjọ naa lọhun.
Agbegbe Sapon, niluu Abeokuta ni laabu Odulate wa lọdun naa lọhun, nibẹ lo si ti po awọn eroja naa pọ.
Lara awọn eroja naa lo wa lati ilu Liverpool, nilẹ Gẹẹsi, ninu eyii ti ‘acetylsalicylic acid’ ati ‘caffeine’ wa.
Ninu oogun alabuku ni ‘acetylsalicylic acid’ ti iwọn rẹ jẹ 760 mg, ati ‘caffeine’ti iwọn rẹ jẹ 60 mg wa, ti apapọ iwọn oogun naa si jẹ 820 mg.
Aṣeyọri oogun Alabukun
Lara awọn ohun to mu ki oogun naa ṣaṣeyọri ni bo ṣe po awọn eroja lati oke okun ati eroja ilẹ adulawọ pọ.
Fun nnkan bii ọgọrun ọdun ti Alabukun fi ta warawara, wọn ko fi igba kankan ṣe ipolowo rẹ ri, awọn eeyan si n bere oogun naa titi di oni yii.
Ara idi ti wọn ko ṣe polowo Alabukun ni awọn eroja ti wọn fi po pọ, awọn eroja naa yoo mu ko ṣoro lati ṣe ipolowo rẹ nitori awọn apoogun yoo ri daju pe wọn le oogun naa kuro lori igba.
Idi miran tun ni pe oogun naa n ṣiṣẹ, awọn eeyan si n ra.
Ọdun 1962 ni Jacob Odulate to kọkọ po oogun naa jade laye lẹni ọdun mejidinlọgọrin.












