Mọ̀ nípa ibùdó tí o ti le gba omi ọmú lọ́fẹ̀ẹ́ fún ọmọ ní Naijiria

Obinrin to n fun ọmọ ni ọmu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, Broadcast Journalist

"Mo da bi ẹni to ti tán fún, àti iya buruku nitori pe mi o ri omi ọmu tó tó fun ọmọ mi nigba ti mo bii."

Diẹ lara nkan ti arabinrin, Dokita Chinny Obinwanne sọ fun BBC re e.

Ninu ifọrọwanilẹnu wo pẹlu akọroyin BBC, Nkechi Ogbonna, Dokita Obinwanne, ni nigba ti oun bi ọmọ tuntun, omi ko jade ni ọyan oun rara, eyi to mu ko nira lati fun ọmọ naa ni ounjẹ.

“Niṣe lo dabi ẹni pe mo kuna ninu ojuṣe mi akọkọ gẹgẹ bi iya.”

Iriri rẹ yii lo mu ko da ibudo kan silẹ, nibi ti awọn obinrin le lọ lati fi omi ọmu wọn silẹ lọfẹẹ, fun anfaani awọn ọmọ ti iya wọn ko ni omi ni ọmu, tabi ti iya wọn ku, tabi nitori awọn idi mii.

Ibudo naa to pe orukọ rẹ ni MilkBank NG, ni ibudo akọkọ ni Naijria, nibi ti wọn n ko omi ọmu obinrin pamọ si.

Oṣu Kẹjọ, ọdun 2020 ni wọn ṣi ibudo naa, lati ran awọn ọmọ ti wọn bi lai pe ọjọ, ati awọn iya ti ko le fun ọmọ ni ọmu.

O le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin (700,000) ọmọ tuntun, to n ku ni ọdọọdun ni Naijiria.
Àkọlé àwòrán, O le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin (700,000) ọmọ tuntun, to n ku ni ọdọọdun ni Naijiria.

Ajọ WHO sọ pe Naijiria lo wa ni ipo kẹta, ninu awọn orilẹ-ede ti wọn ti n bi awọn ọmọ ti oṣu wọn ko pé l’agbaye.

O le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin (700,000) ọmọ tuntun, to n ku ni ọdọọdun ni Naijiria.

Dokita Chinny Obinwanne sọ oe ṣugbọn adinku le ba iṣẹlẹ yii, ti awọn ọmọ tuntun ba n ri omi ọmu ti awọn eeyan fi tọrẹ, mu.

Ẹnikan to ma n fi omi ọmu rẹ tọrẹ ni ibudo MilkBank NG, Mariam Abimbola, sọ fun BBC pe omi ọmu ti oun ma n fi silẹ ni ojumọ ma n to lita kan, paapaa nitori pe o n lo ẹrọ to n fa omi jade ninu ọmu, ‘breast pump’.

Ipinlẹ Eko nikan ṣi ni ibudo yii wa ni Naijiria.

Awọn iyalọmọ ma n lọ si ibudo naa lati fi omi ọmu wọn silẹ ni ọfẹ.

Dokita Obinwanne sọ pe awọn le ri to lita marundinlagoje ni ọsẹ.

“Amọ ipinnu wa ni lati ma a ri to igba lita omi ọmu ni ọsọọsẹ, ti yoo ba fi to oṣu mẹta si asiko yii.”

Bawo ni wọn ṣe n tọju awọn omi ọmu naa?

Mariam Abimbola, sọ fun BBC pe omi ọmu ti oun ma n fi silẹ ni ojumọ ma n to lita kan, paapaa nitori pe o n lo ẹrọ to n fa omi jade ninu ọmu, ‘breast pump’.
Àkọlé àwòrán, Mariam Abimbola, sọ fun BBC pe omi ọmu ti oun ma n fi silẹ ni ojumọ ma n to lita kan, paapaa nitori pe o n lo ẹrọ to n fa omi jade ninu ọmu, ‘breast pump’.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni ibudo yii, ẹrọ amunawa ‘generator’, ni wọn ma n lo ni gbogbo igba.

Eyi jẹ ọna lati mu ki awọn omi ọmu naa dì ninu amohunjẹ tutu, paapaa ti ko ba si ina ijọba.

Dokita Obinwanne sọ pe ọfẹ ni wọn n pin omi ọmu fun awọn iyalọmọ to ba nilo rẹ, ṣugbọn wọn ma n gba laarin ẹgbẹrun mẹta si ẹgbẹrun mẹfa, gẹgẹ bi owo fun amojuto ati itọju ibudo ti wọn n ko ọmi ọmu pamọ si.

Bawo ni wọn ṣe n ṣamojuto awọn omi ọmu yii?

Akọsilẹ to wa ni oju oyelujara ileeṣẹ Medela, ọkan lara awọn gbajugbaja ileeṣẹ to n ṣe ẹrọ to n fa omi ọmu jade ni agbaye, sọ pe awọn iyalọmọ ti ilera wọn dara nikan, ti ọmọ wọn ko si tii ju oṣu mẹfa lọ, ni wọn ma n gba omi ọmu wọn.

Ki obinrin to le fi omi ọmu silẹ, ibudo naa yoo ṣe awọn ayẹwo kan fun, lati mọ boya o ni aarun kankan bi HIV/AIDS, ati bẹẹ bẹẹ lọ lara.

Idi ni pe awọn aarun kan le gba inu omi ọmu wọ agọ ara ọmọ tuntun.

Lara awọn ibeere ti wọn tun ma n beere ni :

  • Boya obinrin naa ma n lo awọn oogun kan tabi àgbo
  • Wọn tun ma n beere boya o ma n mu ọti lile lojoojumọ
  • Iye eroja caffeine to n mu
  • Iru awọn aisan to n ba finra

Botilẹ jẹ pe awọn nkan wọn yii le ma di obinrin lọwọ lati fi omi ọmu rẹ silẹ lọfẹẹ, o jẹ ọna lati rii daju pe omi ọmu naa ko lewu fun ọmọ tuntun ti yoo mú.