Àsìkò wo ló yẹ kí tọkọtaya bẹ̀rẹ̀ ìbálòpọ̀ lẹ́yìn ìbímọ?

Oríṣun àwòrán, RAPHAELLE MARTIN
Ireti tọkọtaya ni lati bẹrẹ ibalopọ pada lẹyin ti obinrin ba bimọ tan. Ṣugbọn oriṣiriṣi nkan ma n ṣe idiwọ fun eyi.
Eyi ko ṣẹyin bo sẹ jẹ pe ibalopọ lẹyin ti obinrin ba bimọ ma n nira fun ọpọlọpọ nitori irora rirọ bi, awọn eroja ‘hormones’ ninu ara ati itọju ọmọ tuntun.
Bakan naa ni aarẹ ṣi le mu ara obinrin to ṣẹṣẹ bimọ, eyi ti ko nii jẹ ki ibalopọ wu u mọ.
Asiko wo lo yẹ ki tọkọtaya duro de ki wọn to bẹrẹ ibalopọ pada?
Awọn dokita ma n gba awọn obinrin to ba bimọ pe ohunkohun ko gbọdọ wọ oju ara wọn fun ọsẹ mẹfa lẹyin ti wọn ba bimọ tan, nitori ki o le tete san lẹyin ti ọmọ gba ibẹ jade.
Ireti wa pe ẹ̀jẹ̀ to ku yoo ti jade tan ninu ara nigba naa.
Ti o ba ṣẹṣẹ bimọ, ti o si fẹ ẹ ni ibalopọ lati oju ara, o le ma gbadun rẹ bi i ti tẹlẹ ko to o bimọ.
Kii ṣe obinrin to bi ọmọ lati oju ara nikan ni ọrọ kan, o tun kan awọn obinrin to ba fi iṣẹ abẹ bimọ.
Eyi ko ṣẹyin irora to wa lati ara ọmọ bibi, ṣugbọn o tun nii ṣe pẹlu pe eroja estrogen to ti ni ipa lori bi awọn iṣan oju ara ṣe n ràn si.
Onimọ nipa agọ ara obinrin, Rebecca Booth, niluu Kentuck lorilẹ-ede United Kingdom, lo sọ eyi.
Ajọ eleto ilera orilẹ-ede naa gba awọn obinrin ni imọran pe ti ibalopọ ba n dun ọ, o le gbiyanju lati lo awọn ipara to wa fun ibalopọ.
Agọ ara rẹ le ti yipada
Ayipada ti yoo ba ara rẹ nii ṣe pẹlu ọjọ ori rẹ ati iye ọmọ ti o ti bi.
Awọn ayipada ti yoo ba awọn eroja ‘hormones’ ṣe e ṣe ko mu ki oju ara gbẹ ju boṣe yẹ lọ.
O si le gba to asiko diẹ ki ibalopọ to wu ọ. Ṣugbọn ko to o di asiko naa, iwọ ati ololufẹ rẹ le gbadun ara yin ni awọn ọna mii.
Ilana ti o le tẹle ti o ba fẹ bẹrẹ ibalopọ
Ibalopọ lẹyin ọmọ bibi ṣe pataki, nitori pe ti ọkọ ati iyawo ko ba sun mọ ara wọn, o le fa ipinya ninu igbeyawo, tabi ikanra.
Onimọ nipa ibalopọ, Amy Levine sọ pe lati gbadun ibalopọ pada lẹyin ibimọ:
Ẹ bẹrẹ pẹlu fifi ẹnu ko ẹnu tabi fi ọwọ pa ara yin lara
Jẹ ki ololufẹ rẹ mọ ti o ba n ni irora: Ti o ba dakẹ bi ẹni pe o n gbadun rẹ, amọ ti ọrọ ko ri bẹẹ, o ṣeeṣe ki o bẹrẹ si ni ri ibalopọ gẹgẹ bi nkan buruku dipo igbadun. Ẹ le ṣe awọn ere ifẹ mii yatọ si ibalopọ nikan.
Ẹ sẹ jẹẹjẹ: Gẹgẹ bi obinrin, o le kọkọ lo ìka ọwọ rẹ̀ lati fi wo bi oju ara rẹ ṣe ri, tabi boya o ṣi n ni irora. O le gbiyanju rẹ nipa lilo ipara ibalopọ.
Fi aaye silẹ fun isinmi: Asiko ti ọkan iwọ ati ololufẹ rẹ ba wa papọ ni ẹ le gbadun ibalopọ, kii ṣe nigba ti ẹ ba n ro nkan ọtọọtọ.
Beere fun iranlọwọ: Ti o ba ṣi n ni irora lẹyin ọsẹ mẹfa ti o ti bimọ, lọ ọ ri dokita rẹ fun ayẹwo ati itọju.












