Gender Based Violence: Àjàkálẹ̀ àrùn míì ní ìfìpábánilòpọ̀ níbí pẹ̀lú adúrú obìnrin tí wọ́n ṣeé sí
Pẹlu omije loju, Zahara sọ bi ọkunrin naa to ba a rinrin ajo pọ ṣe ri i mu nipa dida nkan si i loju ti ko fi lee mọ ohun to n ṣe mọ́.
Zahara yan lati ma fi itiju ba tara rẹ jẹ. Lẹyin ti wọn gbiyanju lati fipa ba a lopọ, ko joko tẹtẹrẹ lati maa sọkun tabi wa oju aanu kiri.
Bi ata ni, bí afẹ́fẹ́ tajutaju ni, Zahara ko ṣaa le mi tabi riran.

O gbiyanju lati gba ara rẹ la ṣugbọn ko sọna. Oreọfẹ kan ṣoṣo to ni ni asiko ti ọkunrin naa kan jade lọ mu nkan lẹyin ọkọ. Lai riran, lo ba tu u sigbo.
Ohun to ṣẹlẹ lẹyin naa ni Zahara ṣalaye fun BBC.
- Ẹ̀yin Oníbàárà wa ọ̀wọ́n, ẹ má mikàn, a ti ń dá gbogbo iná yín padà - TCN
- Gbara rẹ sile
- Ìpínlẹ̀ Bauchi àti Kaduna láti máà tẹ àwọn afipábánilopọ̀ lọ́dàá
- Ó ti di ẹ̀ṣẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ fún afipábánilòpọ̀ nípìnlẹ̀ Ekiti- Ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti
- Háà, èyí tún ga! Wó ọkùnrin táwọn obìnrin fipá bá lòpọ̀ ní ẹ̀ẹ̀mejì
- Wo àfipábánilòpọ̀ ẹni ọdún 51 tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti tú làṣirí ní gbangba
- Ìfipábánilòpọ̀ kìí ṣe ìwà ọmọlúwàbí, àwọn òṣèré tíátà pariwo síta
- Iyabo Ojo, Toyin Abraham, Mercy Aigbe, ta làwọn òṣèrébìnrin yìí gbè lẹ́yìn lórí ọ̀rọ̀ ìfipábánilòpọ̀?

"Wọn maa n ro pe awọn lẹtọ si obinrin, bii pe ohun to yẹ ko jẹ tiwọn ni".
O ti le ni ẹẹdẹgbẹrin-le ẹgbẹrun meji obinrin ti wọn ti fipa balopọ lorilẹede South Africa lọdun to kọja nikan.
Nibayii, Zahara ti di gbajugbaja olorin to n kọrin pọ mọ tita jita funrarẹ.
Ko sẹni to kọ |ahara bi wọn ṣe n ta jita lohun to jẹ pe owo gọbọ́i lawọn eeyan n na lati kọ ọ.

