Ìjọba ológun yóò fi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀mọ́ ìjọba kan Ààrẹ Bazoum tí wọ́n rọ̀ lóyè

Oríṣun àwòrán, PA media
Ijọba ologun to ditẹgbajọba ni oriẹede Niger ti kede erongba rẹ lati foju Aarẹ Mohamed Bazoum ti wọn rọ loye wina ofin fun ẹsun iditẹmọ ijọba.
Wọn tun fi ẹsun kan pe o n fi eto aabo orilẹede naa sinu ewu.
Ikede yii ni ẹri tuntun pe ijọba ologun naa ṣetan lati kọ ọrọ si ajọ agbaye to ni ko da ijọba pada fun Bazoum.
Lati ọṣẹ mẹta ti awọn ologun ti gba ijọba ni Ọgbẹni Bazoum ti wa ni ahamọ ologun ni isalẹ ile rẹ.
Amọ dokita rẹ sọ pe Bazoum ko ba ọkan jẹ rara, botilẹ jẹ pe ipo to wa ko dara.
Awọn ologun fọwọ si ki dokita bẹẹ wo lọjọ Abamẹta lẹyin ọpọlọpọ ariwo lati ilẹ okeere fun itusilẹ rẹ.
Ṣaaju ni ijọba ologun naa kede pe oun ṣetan lati jiroro pẹlu ajọ Ecowas.
Ṣugbọn ọrọ tun gba ibomiran yọ nigba to kede pe oun ti ko ẹri jọ lati gbe aarẹ ti wọn yọ nipo, ati awọn alajọṣiṣẹ pọ rẹ ni abẹle ati ilẹ okeere lọ sile ẹjọ, fun ẹsun pe o gbabọde fun orile-ede Niger, to si tun fi eto aabo rẹ sinu ewu.
Amọ wọn o sọ ọna to gba ṣẹ ẹsẹ naa.
Ọgbẹni Bazoum, ọmọ, ati iyawo rẹ ni wọn fi si ahamọ - ti ọpọ si n jaya nipa ilera wọn.
Lọjọ Abamẹta to kọja, ikọ awọn olori ẹsin Islam lati Naijiria ṣe ipade pẹlu awọn olori ijọba ologun ni Niamey, pẹlu erongba lati yanju wahala naa.
Olootu ijọba ti awọn ologun yan, Ali Mahamane Lamine Zeine sọ pe oun ni ireti pe ijiroro yoo waye pẹlu Ecowas laipẹ, lati sọrọ lori bi wọn o ṣe fopin si "ijiya ti wọn n fun wa".
Lara ijiya ti Ecowas fun Niger ni pe wọn ge ina ẹlẹtiriki to wọ orile-ede naa, eyi to fa okunkun ni ilu Niamey, ati awọn ilu nla mii.
Iroyin sọ pe Ọgbẹni Bazoum ti ru pupọ, ti ọmọ rẹ ọkunrin, ẹni ogun ọdun, to ni aisan gbẹmi-gbẹmi, ko si ri anfaani si itọju.
Alamojuto ẹtọ ọmọniyan ninu ajọ United Nations, Volker Turk, ṣapejuwe fifi awọn eeyan naa si ahamọ gẹgẹ bi nnkan to tako ofin ẹtọ ọmọniyan l'agbaye.
Ọmọbinrin Bazoum, Zazia, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, to lọ fun irinajo afẹ ni France lasiko ditẹgbajọba naa, sọ fun iwe iroyin UK Guardian pe, awọn obi oun ati aburo rẹ ko ri omi to mọ lo, tabi ri ina ẹlẹtiriki lo.
O ni irẹsi nikan ni wọn n fun wọn jẹ.
Ẹẹkan pere ni Ọgbẹni Bazoum ti yọju si gbangba lati igba ti wọn gba ijọba lọwọ rẹ, ninu aworan kan ti wọn fi sita lẹyin ipade rẹ pẹlu aarẹ Chad, Mahamat Idriss Déby Itno.
Ní Niger, àwọn mọogun adìtẹ̀gbàjọba gbà láti jíròrò pẹ̀lú Ecowas

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ologun lorilẹede Niger ti gba lati bẹrẹ ijiroro pẹlu ajọ orilẹede iwọ oorun Afirka, Ecowas lori ọna abayọ lati yanju rogbodiyan ọrọ oṣelu to n lọ lorilẹede naa.
Igbimọ awn olori ẹlẹsin Musulumi ti orilẹede Naijria gbe kalẹ lati yanju ọrọ naa kede ninu atẹjade ti wọn fi ransẹ si awọn akọroyin lọjọ Aiku pe igbimọ naa morile Niger pẹlu asẹ Aarẹ Bola Tinubu, ẹni to ke si wọn lati da si ọrọ naa .
Igbimọ naa ti Sheikh Bala Lau lewaju rẹ se ipade pẹlu olori ijọba ologun ti awn aditẹgbajọba gbe kalẹ nibẹ, Ọgagun Abdourahmane Tchiani ti wọn si jiroro lori bi wọn yo se da Aarẹ tẹlẹ, Mohamed Bazoum pada sipo.
Lau ni oun sọ fun Ọgagun Tchiani pe wiwa awọn da lori wiwa ọna bi awọn olori ikọ ọmọogun aditẹgbajọba naa yoo ṣe.
O ni oun jẹ ko mọ pe ọpọ nnkan ni yoo bajẹ bi wọn ba n gbero ati fi ogun yanju rẹ.
Ninu esi rẹ, Ọgagun Tchiani, kan sara si igbiyanju awọn olori ẹsin naa.
O ni "Ilẹkun ṣi silẹ fun ijiroro alaafia" lati yanju irukerudo naa.
"O dun wa pupọ pe awọn olori ECOWAS ko gba wa laye lati wi tẹnu wa ki wọn to gbe igbesẹ pe ki a kuro ni ijọba."
O tẹsiwaju pe eredi iditẹgbajọba naa wa lati yọ orilẹede Niger ati orilẹede Naijiria kuro ninu wahala to sese ko waye lọjọ iwaju.
Ọgagun Tchiani wa tọrọ aforijin bi ko se fi aye gba awọn igbimọ lakọkọ ti A arẹ Bola Tinubu kọkọ ran wa, o ni inu lo bi awọn si igbesẹ ajọ ECOWAS.
Àláfíà ni Ààrẹ Bazoum wà ní àhámọ́ tó wà ṣùgbọ́n..

Oríṣun àwòrán, AFP
Aarẹ Niger ni wọn ti kede pe lakọ lo wa ni ahamọ ikọ ologun to ditẹgbajọba lẹyin ti dokita se abẹwo si.
Mohamad Bazoum, ọmọ rẹ ọkunrin ati Iyawo rẹ ni awọn wa ni abẹ agbala wọn ni Niamey lati ọjọ kẹrindinlogoji oṣu keje.
"Ibi ti wọn fi wọn pamọ si ko dara rara, wọn ti yọ ina." Eyi ni ọrọ Dokita lasiko to n ba ileeṣẹ oniroyin lati orilẹede France sọrọ.
Abẹwo ọhun ni ijọba tuntun buwọlu lẹyin ti ọpọ awọn olori orilẹede bẹrẹ si ni pe fun itusilẹ Aarẹ ati mọlẹbi rẹ.
Ileeṣẹ iroyin RFI ni abẹwo yii lo jẹ igba akọkọ ti Aarẹ Bazoum yoo gba alejo lẹyin ti wọn gba ijọba lọwọ rẹ.
Bazoum, ẹni ọdun mẹtalelọgọta ni iroyin ni o ru gan, ti ọmọ rẹ, ẹni ogun ọdun si wa ni idubulẹ aisan sugbọn ti wọn ko ni anfani si itọju.
Dokita ni anfani lati ba Aarẹ sọrọ, pẹlu Iyawo ati ọmọ rẹ."
Bakan naa ni dokita gbe ounjẹ ati oogun lọ fun wọn ni ahamọ.
Lẹyin abẹwo naa, Aarẹ Bazoum jẹ ko di mimọ pe ọkan oun balẹ.
Igbesẹ ijọba tuntun ti Ọgagun Abdourahamane Tchiani n dari lati fi aye silẹ fun dokita lati se abẹwo Aarẹ ati mọlẹbi rẹ ko sẹyin ipe ti ghogbo agbeye n pe fun pe ki wọn tu Aarẹ naa silẹ.
Ọmọ obinrin Aarẹ Bazoum, Zazia, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ti ko si ni ile lasiko iditẹgbajọba naa ni awọn mọlẹbi oun ko ni anfani lati mu omi to mọ, tabi ri ina mọnmọna, ti wọn ko si ri ounjẹ gidi jẹ.
O ni gbogbo ounjẹ gidi ti awọn ko sinu ẹrọ amu nnkan tuntun lo ti bajẹ nitori ko si ina mọnamọna.
"Ipo ti awọn mọlẹbi wa nira pupọ sugbọn wọn ni awọn ko dẹkun ija fun nnkan to tọ sugbọn o nira fun lati ri mọlẹbi ninu isoro.















