Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Sierra Leone ti ṣàwárí 'Killaboy' tó ṣekúpa olólùfẹ́ rẹ, tó sì fẹsẹ̀ fẹ́ẹ

Oríṣun àwòrán, @AUSTA_XXO/INSTAGRAM, @ENIBOY/X
Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Sierra Leone ti kede pe awọn ti mu ọmọ orilẹede Naijiria, Benjamin Best Nnayereugo ti ọpọ mọ si Killaboi, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o ṣekupa ọrẹbinrin rẹ, Augusta Osedion, to si salọ.
Agbẹnuṣọ ileeṣẹ ọlọpa ipinle Eko, Benjamin Hundeyin fidi rẹ mulẹ fun ileeṣẹ BBC News pe ọwọ Ileeṣẹ ọlọpaa ti orilẹede Sierra Leonan lo tẹ afurasi naa ti wọn si ti n ṣe igbinyanju lati gbe pada wa si orilẹede Naijiria.
“A n fidi rẹ mulẹ pe Ọlọpaa Sierra Leone lo mu afurasi yii ati pe a ti n sisẹ pọ pẹlu wọn lati gbe afurasi naa pada si orilẹede Naijiria.”
Lọjọ kẹwaa oṣu kẹwaa ni Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko kede pe awọn n wa afurasi naa, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn lẹyin to ṣekupa ọrẹbinrin rẹ, ẹni ọdun mọkanlelogun, to jẹ akẹkọọ Fasiti Lead City.
Ninu oṣu keje ni Killaboi jẹwọ lori opo ayelujara rẹ pe oun ati ọrẹbinrin rẹ ni gbolohun a sọ, ti oun ṣe si gun lọbẹ pa.
Killaboi ni pe oun yoo jọwọ ara oun silẹ lati koju ofin fun awa ti oun wu naa.
Ninu awọn ọrọ rẹ to gbe sori ayelujara, o safihan awọn atẹjisẹ to fi ransẹ si Iya ọmọ ọrẹbinrin rẹ nibi to ti ni oun ko mọmọ ṣekupa ọrẹbinrin oun.
Ọpọ iroyin lo ti gba ori ayelujara pe Killaboi lo ẹgbẹrun lọna marundinlọgbọn dọla fi ṣe ayipada ara rẹ ni Sierra Leone, eyi to tun mo ra paali idanimọ ti orilẹede naa ati awọn nnkan mii.
Bakan naa ni ayelujara tun fidi rẹ mulẹ pe Killaboi ṣe ayipada orukọ rẹ si Kanu Princeton Samuel, to si jẹ pe ile igbafẹ alẹ ni ọwọ ti tẹ.

Oríṣun àwòrán, LAGOS STATE POLICE COMMAND
Ta ni Killaboi?

Oríṣun àwòrán, @KILLABOIGRAM/INSTAGRAM
Killaboi, lori opo ayelujara rẹ ni oun jẹ eni to n ta ati ra owo Crypto lori ẹrọ ayelujara.Ọdọmọkunrin naa ko ni akọle to pọ lori opo ayelujara rẹ sugbọn eyi ti a ri fihan pe ọmọ jayejaye nii.
Ọkan lara ohun ti a ri loju opo ni ibi to ti duro ni ẹgbẹ ọkọ ofurufu aladani kan.
Bakan naa lo tun gbe sori ayelujara pe o ri owo toto milọnu lọna ọọdurun naira nmi ọdun 2022 ati 2023 nipa tẹtẹ tita.
Killaboi, to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ti wọn fi ẹsun pe o sekupa ọrẹbinrin rẹ kan, ni oun ko ni okun lati koju awọn mọlẹbi oun sọpe ohun ko le koju awọn mọlẹbi nitori nnkan to ṣe.
Ta ni Augusta?

Oríṣun àwòrán, @AUSTA_XXO/INSTAGRAM
Onuwabuagbe Augusta Osedion, ti ọpọ mọ sii Augusta jẹ eni ọdun mọnkanlelogun, akẹkọọ fasiti Lead City to wa nilu Ibadan.
Lori opo ayelujara rẹ, Augusta sapejuwe ara rẹ gẹgẹ bi eniyan pataki lawujọ
Awọn eeyan to le ni ọgọrun ni wọn n tẹle lori ayelujara Instagram rẹ.












