Dókítà Olaleye, tó fipá bá ọmọdé lòpọ̀, rí ẹ̀wọ̀n gbére he

Aworan Dokita Olaleye

Oríṣun àwòrán, Others

Ileẹjọ to gbọ ẹjọ nipa ibanilopọ to n joko niluu Ikeja ti ran Dokita Ileeṣẹ Optima Cancer Care Foundation si, Olufemi Olaleye lọ si ẹwọn gbere fun ẹsun pe o fipa ba aburo Iyawo rẹ lopọ. to si tun fi tipatipa fi nnkan ọmọkunrin rẹ si lẹnu.

Adajọ Rahman Osodi lo gbe idajọ naa kalẹ lẹyin to jẹ ko di mimọ pe o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan pe o ba ọdọmọbinrin, ọmọ ọdun mẹdogun lopọ, to si tun ja ibale rẹ.

Adajọ ni Dokita kuna lati fi ẹri han pe ko jẹ bi ati pe gbogbo ẹri to wa ni ile ẹjọ fihan pe o jẹ ẹsun naa.

Olaleye ni Ijọba ipinlẹ Eko fẹsun meji kan to si da lori pe o fipa ba aburo iyawo rẹ lopọ.

Saaju ni Olaleye ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun lọjọ Kẹdọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2022.

Agbẹjọrọ fun ijọba, Babajide Martins ni laarin oṣu keji ọdun 2020 si oṣu kọkanla ọdun 2021 ni Dokita fi ṣẹ ẹsẹ naa.

O ni isẹlẹ naa waye ni ojule kẹtadinlogun, ni agbegbe Layi Ogunbambi, Maryland nipinlẹ Eko.

Wọn fi ẹsun kan Olaleye pe o fipa ọmọ ọdun mẹẹdogun lopọ, ẹni tii se aburo iyawo rẹ, to si ja ibale ọdọbinrin naa, ni ilana ti ko ba ofin mu.

Bakan naa ni wọn fẹsun kan Olaleye pe o fi tipa fi nnkan ọmọkunrin rẹ si ọmọ naa lẹnu.

Ọkọ mi ni arun to maa n jẹ ko fẹ ni ibalopọ ni gbogbo igba - Aya Dokita Olaleye

Dokita Femi Olaleye sọ saaju pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun rara ati pe irọ ni gbogbo ohun ti wọn sọ pe oun ṣe.

O jẹ ko di mimọ pe ọrọ kekere ni oun pe ọrọ naa ati pe oun wo boya nnkan ti oun le yanju pẹlu iyawo oun ni sugbọn o dabi pe awọn eeyan fẹ lo iyawo oun lati da ile oun ru ni.

Iyawo Dokita, Remi Olaleye sọ fun ileẹjọ ni ọjọ Kọkandilogun oṣu Kejila ọdun 2022 pe ọkọ oun ni aarun to maa n jẹ ko fẹ ni ibalopọ ni gbogbo igba.

Lọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdunb 2022 ni Dokita Olaleye kọ lati farahan niwaju Onidajọ Rahmon Oshodi, ti ile ẹjọ to n gbọ ẹsun ifipabanilopọ.

Agbẹjọro agba meji, Babatunde Ogala (SAN) ati Olusegun Fabunmi (SAN) si lo ṣoju rẹ nile ẹjọ.