Èèyàn méjì kú nígbà tí ilé ìjọsìn kan ya lulẹ̀ l'Osun

Ní ọjọ kọkànlá oṣù Kẹ̀wá Ọdún 2023 ni ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ ni agbegbe Eweta nilu Ikirun nipinle Osun níbi ti ile Ìjọsìn C. A. C. LAND OF HOPE tí yà lu lẹ.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yii lo mu ẹ̀mí oludasilẹ ṣọọṣi naa lọ tí ọmọdébinrin kan náà si pàdánù ẹ̀mí rẹ.
Ọmọdébirin mii naa tun fara pa ṣùgbọ́n o ti gba ìtọ́jú tán bayii.
Bẹẹ naa ni èèyàn meji fara pá, tí ọkàn lara wọn si jẹ akọ́bí si arábìnrin tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà gbà èmi rẹ pẹlu arakunrin kan tí ó jẹ agbasẹse ni ṣọọsi naa.
Gbogbo akitiyan BBC Yoruba láti le gba ọrọ lẹ́nu ọkọ arábìnrin tabi ara ile ijọsìn náà lo ja si pàbó látàrí bí ọkọ arábìnrin náà kò ṣe fi àyè silẹ rárá.



Ninu iwadii wá láti gbọ pe ọkọ arábìnrin tó jẹ́ oludasilẹ ṣọọsi naa jẹ ọkan lara àwọn agbofinro.
Ẹnikan lara awọn aladugbo lo fi idi iṣẹlẹ̀ náà múlẹ̀ fún Ikọ BBC Yoruba ti o si kọ lati da orúkọ rẹ fun wa.











