Àjọ AIU fòfin de Divine Oduduru pé kò gbọdọ̀ kópa nínú ìdíje eré sísá fún ọdún mẹ́fà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbimọ adamọ lẹkun ariṣekandu iwa kotọ lagbo ere idaraya lagbaye, AIU ti paṣẹ pe ki Divine Oduduru, ọmọ Naijiria to n sa ere ije lọ rọọkun nile fun ọdun mẹfa fun titapa si ofin to de lilo ogun oloro.
Ninu atẹjade ti Ajọ AIU fi lede l'Ọjọbọ, wọn ni Oduduru yoo rọọkun nile fun bi wọn ṣe ba awọn ohun elo ti wọn ti fi ofin de ati gbigbimọran ati lo ogun ti ko tọna.
Wọn fun un ni ọdun meji miran fun awọn iwa kotọ miran.
Bakan naa ni wọn tun ni ko san owo toto ẹgbẹrun mẹta dọla fun ajọ ere idaraya agbaye fun iye owo ti wọn na lori ẹsun naa.
Lati inu oṣu keji ni wọn ti fofin de Oduduru lẹyin ti iwadi fihan pe o jẹ ọkan lara awọn olubara Eric Lira, ẹni to pe ara ni dokita, to si jẹwọ pe oun jẹbi ẹsun egbogi oloro ti wọn fi kan fun ere idaraya Olympic ti ilu US.
Oduduru ni o ri iya he pẹlu Blessing Okagbate, ti oun naa jẹ onibara Lira.
Iwadi AIU fihan pe ibaraẹnisọrọ to waye laarin Lira ati Okagbare lori ayelujara Whatsapp soju abẹ niko pe wọn ra egbogi oloro fun Oduduru.
“Apoti egbogi oloro meji, Somatropin, Xerendip ati Humatrope ni a ba ni ile Oduduru pẹlu awọn ogun mii to mu ki eeyan dagba si.
“Bakan naa ni a tun ri atẹjisẹ kan ti wọn fi ransẹ si Okagbare pẹlu ami danimọ Lira gẹgẹ ẹni to fi ransẹ.”
Gẹgẹ bi AIU ṣe sọ, Oduduru ni oun ko jẹ ẹsun ki wọn fi kan oun rara.
Fifofin de lo ti bẹrẹ lati ọjọ kẹsan an, oṣu keji ọdun 2023, ti yoo si pari ni ọjọ kẹjọ, oṣu kẹji ọdun 2029.















