Ẹ máà pín owó rìbá yín kàn mí, ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá kìlọ̀ f’áwọn ọlọ́pàá

Ọga ọlọpaa ni NAijiria

Oríṣun àwòrán, Nigeria police

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria, Kayode Egbetokun ti fi ọrọ lede wi pe oun ko reti ki ọlọpaa kankan pin owo kan oun pẹlu alaye wi pe ojuṣe ti ofin la kalẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa nikan lo yẹ ko jẹ wọn logun.

Igbakeji ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa lati ẹkun ikọkanla to jẹ iṣẹ naa lasiko abẹwo si olu ileeṣẹ ọlọpaa to n bẹ niluu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Ọyọ l'Ọjọru, Paul Ojeka Odama parọwa si gbogbo oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa lati dẹkun gbogbo iwa ti o le ta ẹrẹ ba aṣọ ala ileeṣẹ naa.

O ni, "Iṣẹ ti o lọla ninu ni iṣẹ ọlọpaa, ti o si duro fun idajọ ododo ati alaafia. Agbofinro tuntun ti wọ ilu, oun si ni ọga agba tuntun fun ileeṣẹ ọlọpaa. Gbogbo igba si lo maa n fi ikorira han si iwa ajẹbanu.

Apẹrẹ rere lo maa n jẹ ni gbogbo ibi ti o ba ti ṣiṣẹ. Akọsilẹ awọn iwa naa n bẹ n'ipinlẹ Kwara nibi to ti ṣiṣẹ gẹgẹ bii Kọmisana ajọ ọlọpaa ati awọn ibomii ti o ti ṣiṣẹ."

Ọlọpaa to ba mọ nnkan to n ṣe ko ni bawn gba riba - Ọga agba ọlọpaa Naijiria

O ṣe alaye wi pe iṣẹ ni wọn ran gbogbo ọlọpaa lati ṣe n'igboro, bẹẹ sini kii ṣe lati pa owo wọle fun ẹnikẹni gẹgẹ bi ofin orilẹede Naijira ti ọdun 1999 ṣe laa kalẹ.

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ni oṣiṣẹ ajọ naa ti o ba mọ ohun ti o n ṣe ko ni ba wọn gba owo ibọbẹ lọwọ ọlọkada tabi awakọ kankan.

O ni iwa ibajẹ ti o gbudọ dopin ni bi awakọ ṣe n gba owo lọwọ ero ọkọ lati fun ọlọpaa to dena ọkọ nitori owo ẹyin.

Egbetokun ni gbogbo oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa lo gbudọ ṣe iṣẹ wọn pẹlu ibẹru Ọlọrun ki wọn si tẹle ofin ijọba lẹnu iṣẹ wọn.

Bakan naa lo ke si awọn ọlọpaa lati ṣọra fun irufẹ iroyin ti wọn n pin kiri lori ayelujara. O ni wọn gbudọ ṣe ayẹwo finifini ki wọn to pin ohunkohun kiri lori itakun agbaye.

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa tun mẹnuba pataki imura awọn ọlọpaa ati bi wọn ṣe n wọ aṣọ wọn lẹnu iṣẹ ati nigba ti wọn ba ṣiwọ iṣẹ, nitori irinisi ni iṣenilọjọ.

Tẹlẹri ni iroyin maa n lọ kaakiri wi pe awọn oṣiṣẹ ọlọpaa kan ti wọn n huwa ibajẹ n'igboro ti wọn si n gba owo lọna aitọ ni awọn ọga ti wọn n fi owo naa jiṣẹ fun.

Ọrọ ti ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa fi lede fi han gbangba wi pe iru iwa bẹẹ ko ni waye ninu iṣakoso tuntun yii.