Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fòfin gbé ẹ̀gbọ́n tó sin àbúrò rẹ̀ ọmọ ọdún méje mọ́lẹ̀ láàyè

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/Facebook
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Kogi ti nawọ́ gán ọmọ ọkùnrin kan fẹ́sùn wí pé ó ri àbúrò rẹ̀ mọ́lẹ̀ láàyè.
Ọmọkùnrin náà, Goodness Oshodi ní òun rí àbúrò òun, Friday Oshodi mọ́lẹ̀ nípa mímú àṣẹ ìyá òun tó ní kí òun fi ìyà jẹ Friday nítorí pé ó jí owó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà tó jẹ́ ti ìyá òun.
Ní agbègbè Apamisede, ní ẹ̀bá Lokoja, olú ìlú ìpínlẹ̀ Kogi ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Agbenusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kogi, William Aya nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn ní àwọn ti ń fi ọ̀rọ̀ wá Goodness lẹ́nu wò ní àgọ́ ọlọ́pàá tó wà.
Aya ṣàlàyé pé Goodness sọ fún àwọn ọlọ́pàá pé ìyá òun ló ní kí òun fi ìyà jẹ Friday látàrí ìwà olè tó hù ni òun ṣe gbẹ́ kòtò tí òun sì bò ó mọ́lẹ̀ láàyè.
Ó ní Friday ti máa ń jí owó tẹ́lẹ̀ àti pé nígbà tó jí owó yìí ló kọ́kọ́ sá kúrò nílé.
Ó ní Friday padà wálé lẹ́yìn náà tó sì tún jí owó mìíràn èyí ló sì mú kí ìyá Goodness sọ fún Goodness láti fìyà jẹ àbúrò rẹ̀ kí ìyá wọn tó máa lọ sí ilé ìjọsìn.
Agbenusọ ọlọ́pàá náà fi kun pé Goodness ní òun kàn fẹ́ dá sèríà fún Friday lásán ni kí àwọn ènìyàn tó bá àwọn níbẹ̀.
Ó ní àwọn ará àdúgbò tó ń kọjá lọ ló gba Friday kalẹ̀, tí wọ́n sì hú kúrò nínú kòtò tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ bò ó mọ́.
Aya ni ìwádìí ti ń lọ lọ́wọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé Goodness ṣì wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.
Bákan náà ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ ọdún méje ń ọmọ tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ náà jẹ́.
Ohun ti ajọ UNICEF sọ lori ẹtọ ọmọde
Ajọ UNICEF to n ri si ọrọ ẹtọ awọn ọmọde ni ifiyajẹ awọn ọmọde jẹ ohun to n ṣẹlẹ lojoojumọ lorilẹede Naijiria.
Ati pe diẹ lara awọn irufẹ ọmọ bẹẹ lo maa n ri iranwọ.
UNICEF ni mẹfa ninu mẹwaa awọn ọmọde lo n doju kọ iwa ipa.
Ajọ naa tun fikun ọrọ rẹ pe ẹyọkan ninu ọmọdebinrin mẹrin ati ida mẹwaa ninu ida ọgọrun awọn ọmọdekunrin lo ti doju kọ iwa ifipabanilopọ.
Ki ni ofin lori ẹtọ ọmọde ni Naijiria sọ?
Ofin kan ṣoṣo to sọ nipa idaabo bo ọmọde ni Naijiria ni ijọba ṣe agbekalẹ rẹ lọdun 2003.
Ile aṣofin Naijiria lo ṣe agbekalẹ ofin naa lati maa daabo bo awọn ọmọde ni Naijiria.
Ofin naa sọ pe ọrọ awọn ọmọde gbọdọ jẹ ẹnikẹni logun ni gbogbo igba.
Mẹrinlelọgbọn ninu ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria lo ti ṣe ẹda ofin naa gẹgẹ bi ofin ipinlẹ.
Awọn ipinlẹ meji toku ko tii bẹrẹ si ni tẹle ofin naa gẹgẹ bi ofin ipinlẹ wọn.
Labẹ ilana ofin Naijiria, ẹnikẹni ti ofin ba mu pe o fiya jẹ ọmọde tabi huwa ipa si ọmọde le dero ẹwọn tabi ko san owo itanran.
Iru ẹni bẹẹ tun le dero ẹwọn ti yoo si tun sanwo itanran bakan naa.












