Wo bí ìgbé ayé ṣe rí ní Gaza látìgbà tí Israel ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù rẹ̀

Àkọlé fídíò, Wo bí ìgbé ayé ṣe rí ní Gaza látìgbà tí Israel ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù rẹ̀
Aworan agbegbe kan ni Gaza

Lati igba ti akọtun wahala ti bẹrẹ laarin Israel ati ikọ Hamas ni Gaza ọpọ ẹmi lo ti ku ti ẹgẹlẹgbẹsi ti di alarinkiri ati alainilelori.

Akọroyin kan lati agbegbe Gaza, Plestia Alaqad ti n ṣe oniruuru awọn fidio kekeke lati fi ṣe apejuwe ohun ti oju rẹ n ri lọwọ pẹlu bi wahala naa ṣe n tẹsiwaju.

O ni ọpọlọpọ igba ni oun ti ni lati ṣi kuro ni agbegbe kan bọ si omiran nitori pe ko si ibi ti ewu ko si bayii bi ikọlu naa ṣe n waye.

Ninu fidio yii, o ṣe alaye bi o ṣe jẹ wi pe inira ni oun fi n mi ati gbogbo eruku iyanrin ti awọn ado oloru to rọ lu awọn ile n ko ranṣẹ kaakiri ayika rẹ.