‘A ò ní àbẹ́là’ - òkùnkùn birimù bo Gaza lálẹ́ lẹ́yìn tí Israel wọ́n já iná wọn

Aworan Gaza

Oríṣun àwòrán, BBC / Adnan Al Bursch

Lẹyin ti wọn ja ina mọnamọna ni ẹkun Gaza, Fatma Aly, ọmọ ilẹ Palestine to jẹ ẹni ọdunmẹrindinlogoji to n gbe ni ariwa Jabalia ti sọ pe alẹ akọkọ laisi ina mọnamọna buru jai.

Aly fẹrẹ le wọle bi o ti n gbọ iro awọn ado oloro ti Israel n ju si ara awọn ogiri ile.

‘’Ninu okunkun birimu ni Gaza wa bayii,’’Aly lo sọ bẹẹ pẹlu ẹru.

‘’A o ni abẹla ti a le fi tan ina, gbogbo ṣọọbu lo wa ni titi pa.

Tọọṣi kekere kan nikan ni a ni ti a fi n riran, amọ, wakati marun un pere lo le fi ṣiṣẹ,’’ Fatma ṣalaye pẹlu ohun rẹ to n gbọn.

Fatma ni o n gbiyanju lati tan ina sinu ile

Oríṣun àwòrán, Fatma Aly

O ṣalaye pe aisi ina mọnamọna ṣakoba nla fawọn eeyan Gaza tori ina ti ko si ko jẹ ki wọn omi mimu ati omi ti wọn le fi wẹ.

‘’Aisi ina tumọ si pe a mo le fi ẹrọ pọmpu omi fun lilo.’’

Ni nkan bi ago meji ni awọn alaṣẹ orilẹede Israel ja ina ni gbogbo ẹkun Gaza lẹyin ọjọ meji ti Israel paṣẹ ikọlu si Gaza lọjọ kẹsan an oṣu Kẹwaa yii.

Agba kekere omi meji pere ti wọn ti tọju sile ki Israel to ja ina Gaza ni Fatma atawọn obi rẹ ti wọn ti dagba gbẹkẹ le.

Fatma ni ‘’aisi ina tumọ si pe ounjẹ ko le ṣee fi pamọ sinu ẹrọ amunkan tutu, eyi to jẹ ki ọunjẹ wọn.’’

O ni ‘’ounjẹ to wa ninu ẹrọ firiiji amunkan tutu ti bajẹ nigba ti ko si ina, a ti da ounjẹ naa nu.’’

Fatma ṣalaye pe o nira fun ẹbi oun lati ri omi lo fun adura lẹẹmarun un lojumọ gẹgẹ ilana ẹsin musulumi.

Aworan Gaza ninu okunkun ni Ọjọru

Oríṣun àwòrán, BBC / Adnan Al Bursch

‘’Ewe ati igi olifi ni a gbẹkẹle bayii’’

Fatma atawọn alabagbe rẹ n gbiyanju lati maa yọ iwọnba ounjẹ ti wọn ni ati omi to wa nile lo ki o le pẹ diẹ lẹyin ti wọ ti ja ina wọn ni Gaza.

‘’A o ni ounjẹ mọ bi ko ṣe diẹ to ku nile ki ogun to bẹ silẹ.

Ewe Za’tar ati igi olifi ni a gbẹkẹle bayii,’’ Fatma ṣalaye.

Aworan bi ina ado oloro ṣe n tan imọlẹ si Gaza

Oríṣun àwòrán, Reuters

Fatma ni awọn ọmọde ni ogun naa ṣe akoba fun julọ.

Fatma ṣalaye pe ‘’awọn ọmọ ẹgbọn mi lọkunrin ati lobinrin ti wọn gbe pẹlu awọn ẹgbọn mi lo fara kaasa julọ.’’

Fatma bu sẹkun bi o ti n ṣalaye pe ko si ibi ko lewu fawọn ọmọde lati ṣere mọ.

Aworan bi Gaza ṣe wa ninu okunkun

Oríṣun àwòrán, BBC / Adnan Al Bursch

‘’Ogun iparun ni eleyii’’

‘’Ọpọ eeyan ni mo ri ni ipagọ ogunlende Jabalia ni ariwa ila oorun Gaza nibi ti ọpọlọpọ ti sa kuro nile wọn to ti di wiwo lulẹ.

Awọn ti wọn ri aṣọ bẹẹdi ati aṣọ wiwọ mu de ipagọ ogunlende ko pọ.

Igbe aye ni ipagọ ogunlende ko rọrun rara, pẹlu bi orilẹede Israel ti ju bọmbu lẹmọlemọ.’’

Aworan awọn ile ti ado oloro ti wo lulẹ

Ọkunrin kan ni ipagọ ogunlende to n mi tupe tupe ni ‘’a o ni omi ati ounjẹ, koda ko si afẹfẹ gan.

Iru aye wo ni eyi gan an.’’

Bẹẹ ni ọkunrin mii pariwo pe ‘’eyi kii ṣe ogun o, ogun ipanirun ni.’’

Ọpọ awọn eeyan Palestine to wa ni agọ ogunlende lo sọ pe ko rọrun rara nibẹ.

Abu Saqr Abu Rokba, ara Palestine to ti le ni aadọrin ọdun ti padanu ọmọ rẹ mẹtẹẹta.

Nisẹ lo n sọkun bi o ti n ṣalaye. ‘’Mo ti padanu gbogbo ẹbi mi.

Bi mo ti n lọ sin awọn ọmọ mi ni mo rii pe mi o nile lori mọ.

Mi o tiẹ mọ ibi ti mo le lọ bayii.’’

Aworan awọn ile ti ado oloro ti da wo

Ni bii ọjọ meloo sẹyin ni awọn to wa ni ipagọ ogunlende de ibẹ lẹyin ti wọn sa fun yinyin ado oloro lagbegbe wọn.

Layla, kii ṣe orukọ rẹ gan gan an ni a lo, sọ pe ati Beit Hanoun ni ariwa ila oorun Gaza ni oun ti wa, amọ iriri oun ni Jabalia tun buru ju ibi ti oun ti n bọ lọ.

Obinrin to n sọkun

‘’Mo ti padanu ọkọ ati ọmọkunrin mi.

Gbogbo awọn ọmọ mi to ku lo farapa yanayana.

Lojoojumọ ni a maa n gbọ iro ado oloro,’’ obinrin naa ṣalaye pẹlu omije loju rẹ.

Ounjẹ n tan lọ ni Gaza

Aworan awọn eeyan Gaza

Awọn to wa ni ipagọ ogunlende sọ pe ounjẹ diẹ ti awọn fi pamọ lo ku fawọn ni jijẹ pẹlu bii ko sẹ si omi ati ounjẹ mọ.

Wọn sọ pe ounjẹ to ku naa maa to tan titi ibẹrẹ ọsẹ to n bọ.

Koda, kanga loku tawọn eeyan maa bẹrẹ si ni lọ maa pọn bayii lati ri omi.

Awọn miiran ni lati maa tan abẹla lati le riran lalẹ lẹyin ti wọn ti ja ina ni Gaza.

Ọwọngogo epo

O ti nira bayii lati ri epo tan ẹrọ amunawa.

Ko si aye fawọn eeyan to ti ri agọ ogunlende Jabalia bi ile wọn fun ọpọ ọdun.

Niṣe ni wọn n ri eefin ado oloro loju ọrun loke.

Ọpọ ninu wọn lo sọ pe oorun ẹtu ibọn ni o maa n ji awọn laarọ kutu, eleyii to maa n di awọn ni imu tawọn yoo si maa wu ikọ.

Ibi iko idọtisi ko le ṣiṣẹ lai si ina mọnamọna.

Bi mo ti n rin kaakiri agọ ogunlende ọhun ni mo ṣe akiyesi pe idọti tawọn eeyan n da silẹ ti pọ nlẹ kaakiri.

Aworan akọroyin

Ohun ti mo n ro ni pe afaimọ ki ajakalẹ arun ma bẹ silẹ pẹlu bi idọti ṣe pọ nilẹ.

Ni agọ ti ajọ iṣọkan agbaye UN maa n lo tẹlẹ fawọn ogunlende ara Palestine ni ogunlọgọ eeyan ti ko ara wọn sinu awọn yara igbẹkọọ.

Aworan ile ajọ iṣọkan agbaye UN

Ile ẹkọ naa ni ko gba ọpọ eeyan ti wọn o ri ile gbe mọ bayii.

Ọkunrin kan to le ọgbọn ọdun ṣẹṣẹ pari iṣẹ lori agọ to ṣe fun ẹbi rẹ ni.

‘’Niṣe ni ko ọra, ike ati igi jọ lati ṣe agọ ni ile ẹkọ naa.

Ko si ibi tawọn eeyan fẹẹ lọ,’’ o n ba mi sọrọ bi o ti n nawọ si agọ to kọ.

Aworan awọn oṣiṣẹ ẹgbẹ alaanu Red Cross

Awọn ọmọde o le mi daadaa

Loju mi niwaju ile ẹkọ naa ni mo ti ọkunrin kan to n gbe ọmọ kekere kan digba digba sinu ọkọ anbulansi.

Oniṣẹ iṣegun kan gba ọmọ naa lọwọ ọkunrin ọhun.

O sọ fun mi pe ọpọ awọn ọmọde ati awọn obinrin lawọn oṣisẹ eleto ilera ti n tọju lẹyin ti wọn o le mi daadaa mọ tori eefin ati eruku ado oloro ti wọn n fa si imu.

Aworan oṣiṣẹ ẹgbẹ alaanu Red Cros

Ewu wa fawọn ọmọ inu igo

Ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ilera ni Gaza sọ pe bi wọn ṣe ja ina ni Gaza ti ṣakoba fawọn ile iwosan lati tọju awọn alaisan.

Ileeṣẹ naa ni ẹgbẹrun un kan le ọgọrun alaisan kindinrin ti ọmọde mejidinlogoji wa ninu wọn lo wa ninu ewu bayii lẹyin ti wọn ti ja ina mọnamọna ni Gaza.

Aisi ina mọnamọna ti ṣakoba fun ọgọrun ọmọ ikoko to wa ninu igo bayii nitori ko si ina to le ba ṣiṣẹ mọ.

Aworan ọpọ ile ti ado oloro ti wo lulẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters