Mama Kuto rèé, ìyá àgbà awakọ̀èrò tí àìsàn ìyá rẹ̀ sọ̀ di ọmọ gáréèjì

Àkọlé fídíò, Mama Kuto rèé, ìyá àgbà awakọ̀èrò tí àìsàn ìyá rẹ̀ sọ̀ di ọmọ gáréèjì
Mama Kuto rèé, ìyá àgbà awakọ̀èrò tí àìsàn ìyá rẹ̀ sọ̀ di ọmọ gáréèjì
Mama Kuto

Ilumọọka ni Arabinrin Kẹhinde Godsgift Igwe ti ọpọ mọ si Mama Kutọ ni ilu Abẹokuta paapaajulọ lagbo awọn awakọ ero ni ibudokọ ero Terminal 1, Oshodi nilu Eko.

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, Mama Kutọ ṣalaye pe iṣẹ ọkọ ero wiwa pe pupọ ti o si ti ni ipa manigbagbe ni aye oun.

O ni kẹkẹ Marwa wiwa loun fi bẹrẹ iṣẹakero ki oun to kọja si ipa ti ọkọ wiwa.

O ni ko si iṣẹ kan to jẹ iṣẹ ọkunrin, gbogbo iṣẹ ni iṣẹ aṣejẹ.

Amọṣa o fi kun un pe iṣẹ awakọ ero kii ṣe iṣẹ ọlẹ, iṣẹ to n gba ifọkansin pupọ ni.

“Mo maa n wa mọto lati Eko lọ si Abẹokuta ni igba marun un laarin ọsẹ kan.”

‘Iku iya mi lo sun mi di ọmọ inu gareeji’

Ọkọ ti Mama Kutọ n wa

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, o ṣalaye pe iku iya oun lọsọ oun di ọmọ inu gareeji.

O ni eyi lo mu ki ajọṣepọ oun atawọn agbero rọrun pupọ nitori pe oun ti gbọ ede awọn ọmọ ita.

Nigba ti a beere nipa ede awọn ọmọ ita gẹgẹbi o ṣe sọ, Mama Kutọ ṣalaye pe ọwọ ni awọn ọmọ ita nfẹ.

“Bi o ba fun wọn lọwọ wọn, awọn naa naa bu ọwọ fun ẹ pada”

O ni afọkansin oun lati ọjọ akọkọ ti oun ti wọ gareeji ni pe oun yoo ṣe oriire nibẹ.

Mama Kutọ lẹnu irinajo kan

‘Banki ko le san owo ti awakọ ero n ri nidi iṣẹ wọn’

Mama Kutọ

O ṣalaye siwaju sii pe owo ti awakọ ero n pa lojumọ ju owo ti banki n san fun awọn oṣiṣẹ rẹ miran lọ.

O ni ileeṣẹ epo rọbi nikan lo le san iye owo ti awakọ ero npa wọle.

O ni iṣẹ to ṣe e fi le ọmọ lọwọ ni iṣẹ ọkọ ero wiwa, niwọn igba ‘ti eeyan ko ba ti mu ọti, ti eeyan ko ba mu igbo.’

O rọ awọn awakọ ẹgbẹ rẹ lati kiyesara, paapaajulọ lori ohun ti wọn n jẹ tabi mu.

Gẹgẹ bi ohun to wi, o ni “nigba ti eeyan kan ba pa irọ fun ara rẹ pe nitori ati le e riran loun fi n mu ọti lo mu ki ijamba ọkọ pọ loju popo.”

O wa gba awọn obinrin nimọran lati wa iṣẹ ṣe dipo fifi idi mọle lati joye ‘bi ọkọ o mu wa a ko ni jẹ’.