Koko lara mi le lẹ́yìn tí mo parí Wash-a-thon, ohun tó gbé mi lọ sílé ìwòsàn rèé – Subair Enitan

Oríṣun àwòrán, @__communicator_
Akẹkọọ ipele keji ile ẹkọ Obafemi Awolowo to wa niluu Ile Ife, OAU, Subair Enitan ti dero ile iwosan lẹyin to fọ aṣọ fun wakati mejidinlọgọta lona ati gba ami ẹyẹ Guiness World Record, GWR.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii ni Enitan bẹrẹ si n fọ aṣlọ ọhun ko to pari rẹ lọjọ Aje lẹyin to di ero ile iwosan.
Bo tilẹ jẹ pe awọn kan to sunmọ akẹkọọ naa sọ pe ni kete to pari igbiyanju lati gba ami ẹyẹ naa ni awọn gbe digbadigba lọ sile iwosan, akẹkọọ ọhun ti sọ fun BBC pe alaafia ni oun wa.

Oríṣun àwòrán, @callme_chicken
O ni iyalẹnu lo jẹ lẹyin ti oun bẹrẹ si n ri awọn iroyin to sọ pe ṣe ni wọn gbe oun digbadigba lọ sile iwosan.
Enitan sọ fun BBC pe “Ko si ohun to ṣe mi o, niṣe ni mi lọ sinmi fun wakati kan, ti emi atawọn akẹgbẹmi si ṣe fidio bi ọwọ mi ṣe ri, ti a si n ṣere lẹyin naa…. Nnkankan ko ṣẹlẹ si mi.
“Lẹyin wakati aadọta, mo tun ṣe wakati mẹjọ mii si ki n to lọ sile iwosan.”
Lẹyin ti Enitan ti fọ aṣọ fun wakati mejidinlọgọta, o ni “inu mu dun gidi lati pari igbiyanju mi niwaju iya mi, awọn ọrẹ atawọn akẹgbẹ mi to wa sinu gbọgan yii lati ṣatilẹyin fun mi.”
“Mo ṣe igbiyanju ‘Wash-a-thon’ nitori pe iṣẹ mi ni.”
Akẹkọọ naa ṣalaye siwaju si pe oun yan ‘Wash-a-thon’ laayo nitori ohun ti oun maa n ṣe ni gbogbo igba ni, oun si n ṣe iṣẹ lati wa owo fun ẹkọ oun.
“Mo ṣe ‘Wash-a-thon’ nitori mo ni ileeṣẹ ti wọn ti n fọ aṣọ, gbogbo igba ni mo si maa n fọ aṣọ, iṣẹ mi ni.”
“Koko lara mi le lẹyin ti mo pari ‘Wash-a-thon’ naa tan, mo kan ṣe fidio lati ṣalaye awọn nnkankan fun awọn eeyan ni.”
Akẹ́kọ̀ọ́ OAU tó fọ aṣọ fún àmì ẹ̀yẹ Guiness World Records dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tó parí

Oríṣun àwòrán, X/Dr_Bush
Akẹkọọ Fasiti Obafemi Awolowo to n se idije fifọ asọ fun ọpọlọpọ wakati fun Guinness World Record, Subair Enitan lo ti dero ile iwosan lẹyin to pari idije naa.
Enitan pari fifọ aṣọ fun ọpọlọpọ wakati ni owurọ ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kọkanla, ọdun 2023.
Fọnran ti o tẹ wa lọwọ safihan Enitan lori ibusun ile iwosan nibi ti o ti n gba itọju, ti ọwọ rẹ si funfun eyi to waye lẹyin to pari aṣọ fifọ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Gẹgẹ bii ọkan lara awọn ọrẹ Enitan ṣe fi to BBC leti, o ni o ṣe koko pe ki Enitan lọ si ile iwosan lati gba itọju lẹyin to gunle idije oni ọpọlọpọ wakati.
Enitan, ẹni to bẹrẹ aṣọ fifọ lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinlelogun ninu ọgba Fasiti OAU, ti ọpọlọpọ awọn akẹkọọ ati osisẹ Fasiti si wa lati wa yẹ si.
O pari aṣọ fifọ naa lẹyin wakati mejidinlogoji, ti wọn gbe digbadigba lọ si ile iwosan bi o ṣe pari aṣọ fifọ.
O ni inu oun dun pupọ lati pari aṣọ fifọ naa niwaju iya oun ati awọn akẹgbẹ rẹ.
“Inu mi dun pupọ lati pari aṣọ fifọ yii niwaju iya mi, awọn akẹgbẹ mi ati awọn ọrẹ mi ti wọn duro ti mi, ti wọn si fi ife han si lasiko ti mo n fọ aṣọ.”
Ajọ GWR ko ti fesi si idije ti Enitan gunle.















