Lẹ́yìn ọdún kan nípò, kí ni aráàlú ńsọ nipa ìṣèjọba Gómìnà Ademola Adeleke l'Osun?

Aworan Gomina Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Osun Government

Awọn olugbe ipinl̀ Osun dibo gbe Gomina Ademola Adeleke wọle sì ipò Gómìnà ni Ọjọ́ Kẹrindínlógún Oṣù Keje Ọdún 2022.

Wọn se ìbúra fún Gómìnà Ademola Adeleke ni Ọjọ́ Kẹtadinlogbon oṣù Kọkànlá ọdún 2022.

Gomina Adeleke bẹ̀rẹ̀ isẹ lọjọ tí wọn búra fún, tí ó sì yìí orúkọ ti Aregbesola ń tọ pe Ìpínlẹ̀ Osun.

Lati State of Osun si Osun State. Èyí ni isẹ àkọ́kọ́ tí Gomina Adeleke se.

Láàárín Ọdún kan Gomina Ademola Adeleke yàn àwọn olubasise pọ ati ọpọlọpọ olu ba dámọ̀ràn.

Ki ni ẹgbẹ APC sọ nipa iṣejọba Adeleke?

Sunday Akere, eekan ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọṣun

Oríṣun àwòrán, others

BBC YORUBA tesiwaju láti ba ọkan lara ọmọ ẹgbẹ òṣèlú APC ti Ìpínlẹ̀ Osun sọ̀rọ̀ Sunday Akere.

Sunday Akere lo ti sọ pe kí se nítorí ẹgbẹ́ alátakò, ṣùgbọ́n ko sì àṣeyọrí kan tí a le tọ kasi pe Gomina Ademola Adeleke se ni pàtó láàárín ọdún kan

Adeleke lo tí sọ nígbà tí ó ń se ìpolongo idibo pe oun yoo san owo tí ìjọba Aregbesola jẹ àwọn òṣìṣẹ́ láàárín osu Mẹ́fà tí oun ba de ọ́fíìsì. Ṣùgbọ́n ko ri san ju osu Mẹta lọ láàárín ọdún kan.

Bẹ́ẹ̀ ní Gómìnà Adeleke sọ pe oun tí gbẹ omi ẹ̀rọ ìgbàlódé to to 332 káàkiri Ìpínlẹ̀ Osun, Sùgbọ́n kò si èyí tí a ri nibẹ.

Sunday Akere tún tesiwaju pe. Àwọn oju ọna tí ìjọba Adeleke sọ pe oun se, pàápàá ọna IKirun, ní ọ̀nà tí Ìjọba Oyetola ń se lásìkò ìjọba rẹ ki se ọna tuntun rárá.

Ṣùgbọ́n oun oju un wa loju ri ni fún àwọn ara Ìpínlẹ̀ Osun tí wọ́n dibò yan Adeleke.

Ki ni ijọba ipinlẹ Osun sọ?

Rasheed Olawale, Agbenuso fún Gómìnà Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

BBC YORUBA kan si Rasheed Olawale ẹni to jẹ agbenuso fún Gómìnà Ademola Adeleke,

Rasheed Olawale sọ pe Gomina Ademola Adeleke tí se ribiribi tí àwọn ìjọba to kọjá lọ tí ko rí se láàárín ọdún Mẹrin, ní Gómìnà Adeleke se láàárín ọdún kan.

O tún tesiwaju nínú ọ̀rọ̀ rẹ pé, Gómìnà Adeleke se ọ̀nà, eto ìwòsàn ọ̀fẹ́, tí tún ile iwe to tí bá jẹ́ se ati ti tún ile ìwòsàn se.

Gómìnà Adeleke ko tún da ọwọ dúró. Ó tún se eto ayélujára bi ITC àti bẹẹbẹẹ lọ.

Omi ìgbàlódé ko tún gbẹyin ati lati tún omi ero to ti bá jẹ́ ní Ede ati ibo miran se.

Gómìnà Adeleke tún ti gbe isẹ àkànṣe kan kalẹ tí wọ́n ń pe ni Multi Billion naira project. Èyí ni lati le se ọ̀nà afárá ni Osogbo, Ede, IKirun ati Ile-Ife pẹ̀lú àwọn ọ̀nà oko káàkiri.

Gomina Adeleke tún mu owo osu àwọn òṣìṣẹ́ ati òṣìṣẹ́ feyinti ni ọkunkundun lati maa san owo osu wón deede.

Ọ̀rọ̀ yi lo wáyé lásìkò tí Komisanna fún Eto Iroyin ni Ìpínlẹ̀ Osun Kolapo Alimi ati Rasheed Olawale Agbenuso fún Gómìnà Adeleke se ìpàdé parí tán pẹlu àwọn Akoroyin lori àṣeyọrí ọdún kan tí Gomina Adeleke tí se.

Awọn isẹ akanṣe ti ijba Gomina Adeleke ni awn ti gbe ṣe

Aworan

Oríṣun àwòrán, Osun Govt

Gomina Adeleke bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àkànṣe nilu Ede to jẹ ìlú abínibí rẹ. To si se awọn ọna to wọ agbegbe kọ̀ọ̀kan nilu Ede.

Gomina Adeleke tesiwaju nínú isẹ àkànṣe láti gbẹ omi ẹ̀rọ ìgbàlódé to jẹ 332 káàkiri Ìpínlẹ̀ Osun.

Ninu atejade tí Alaga ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tí Ìpínlẹ̀ Osun Sunday Bisi fi sita lo ti sọ àwọn àṣeyọrí tí Gomina Adeleke tí se.

Nínu rẹ lo tí sọ pe Gomina Adeleke tún àwọn ile ẹ̀kọ́ ṣe ó sì tún tun ètò ẹ̀kọ́ se n Ìpínlẹ̀ Osun.

O sì tún se awọn isẹ àkànṣe káàkiri Ìpínlẹ̀ Osun. Bii àwọn ojú pópó to ti bajẹ káàkiri Ìpínlẹ̀ Osun.

Ikọ BBC YORUBA kan sì Waheed Lawal ẹni tó jẹ́ ajá fún ẹtọ ọmọ niyan.

Waheed Lawal nínú ọ̀rọ̀ rẹ lo tí sọ wí pe, ki se pe ase omi tabi oju ọ̀nà àbí ikan miran ní àṣeyọrí to se tọ́ka si, ti ko ba si eto àbò fún ẹ̀mí ati dúkìá.

O tún tesiwaju pe, òun gba Gómìnà Ademola Adeleke ni ìmọ̀ràn pe ko tún eto àbò se nitori kí se ẹni to bá bẹ̀rẹ̀ la ma ki, bí ko ṣe pé ẹni tó ba forí tí dópin là ma ki.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Osun Govt