Hamas/Israel: Àwọn wo ló gba ìtúsílẹ̀ nígbèkùn?

Oríṣun àwòrán, Israel Defence Forces
Eeyan mejidinlọgọta (58) ti wọn wa nigbekun ogun ni Gaza tẹlẹ ti gba ominira bayii. Asiko ti wọn kọlu awọn eeyan Isrẹli lọjọ keje oṣu kẹwaa ni wọn bọ sọwọ awọn to gbe wọn pamọ.
Ogoji eeyan ninu awọn to wa nigbekun ogun yii, ti wọn jẹ obinrin atawọn ọmọde ni wọn gba itusilẹ gẹgẹ bi adehun laarin Israel ati Hamas.
Bakan naa ni eeyan mẹtadinlogun ti wọn jẹ ọmọ orilẹ-ede Thailand, ati ẹnikan to wa lati Filipino naa gba iyọnda, eyi naa waye nipasẹ adehun mi-in to wa laarin Hamas ati ijọba ilẹ Egypt.
Labẹ adehun alasiko perete ti Israel ati Hamas ṣe, aadọta eeyan to wa nigbekun yoo gba itusilẹ lasiko ti wọn fẹẹ fi da ogun duro fọjọ mẹrin.
Igbesẹ ati jẹ kogun-o-mi fọjọ mẹrin yii bẹrẹ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kọkanla ọdun 2023 yii, laago meje aarọ.

Oríṣun àwòrán, Israel Defence Forces
Hamas sọ pe aadọjọ obinrin Palestine (150) atawọn ọdọ lawọn yoo tu silẹ lọgba ẹwọn Israel, bẹẹ ni awọn tirela to le lọgọrun-un, ti wọn ko nnkan iranwọ lawọn yoo gba laye lati wọ Gaza.
Awọn wo gan-an lọmọ Isrẹli to gba ominira nigbekun?

Oríṣun àwòrán, Israel Defence Forces
Margalit Mozes, ẹni ọdun mejidinlọgọrin (78) ti wọn mu sigbekun lati ile rẹ to wa ni Kibbutz Nir Oz. Iya yii ti ni aisan jẹjẹrẹ ri ko too ṣẹgun rẹ. Awọn ẹbi rẹ sọ pe awọn aillera mi-in tun wa to n ba a finra, to si yẹ ko maa gba itọju ni gbogbo igba.
Adina Moshe, ẹni ọdun mejilelaadọrin (72).
Iya yii naa wa lara awọn ti ogun ko lati Nir Oz lọjọ keje, oṣu kẹwaa.
Ninu ikọlu naa ni wọn ti pa ọkọ rẹ, gẹgẹ bi ẹgbẹ kan to n ṣalaye nipa awọn ẹbi ti wọn wa nigbekun ṣe sọ.
Daniele Aloni, ẹni ọdun mẹrinlelogoji ati ọmọ rẹ obinrin, Emilia, ọmọ ọdun mẹfa, bọ sinu igbekun ni Nir Oz. Bẹẹ naa ni wọn ji Sharon Aloni ẹni ọdun mẹtelelọgbọn (34) to jẹ aburo Daniele gbe pẹlu ọkọ rẹ, David Cunio, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (33).
Awọn ibeji awọn tọkọ-taya yii, Ema ati Yuly ti wọn ko ju ọmọ ọdun mẹta lọ naa si bọ sọwọ awọn to gbe awọn obi wọn pamọ pẹlu.
Doron Katz Asher, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (34) atawọn ọmọ rẹ obinrin meji, Raz, ọmọ ọdun mẹrin ati Aviz, ọmọ ọdun meji, bọ sigbekun ogun ajinigbe lasiko ti wọn n gbe lọdọ ẹbi wọn kan nitosi ẹnuubode Gaza.
Ọkọ Doron ri fidio ibi ti wọn ti n ko iyawo atawọn ọmọ ẹ sinu tirela to ko awọn eeyan to wa lahaamọ. O si tun tọpinpin ẹrọ ibara-ẹni-sọrọ rẹ de Gaza..
Ọkan ninu awọn eeyan to gba itusilẹ naa,Ọgbẹni Asher, sọ fun BBC pe,
" Mo ṣetan lati ji idile mi dide pada kuro ninu ironu ati iya ta a jẹ nigbekun ogun. Emi ko jo, mi o si ni i dunnu, afi ti gbogbo ẹni to wa nigbekun ba jade pata.
" Ki i ṣe aworan lasan tabi akọle lohun tẹ ẹ n ri nipa awọn ẹbi ti wọn mu sigbekun, otitọ ni. Eeyan ni wọn. Awọn ti wọn mu sigbekun ti di ẹbi mi latoni lọ, mo si maa ri i daju pe mo ṣe gbogbo ohun ti mo ba le ṣe lati ri i pe ko ṣẹku ẹnikan sigbekun mọ’’
Itay Ravi, sọ fun BBC Newsnight pe bi wọn ṣe fi awọn kan silẹ ninu ẹbi oun mu idunnu wa, ṣugbọn iriri buruku ti ko ti i kuro lara awọn ni.
Hanna Katzir, ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin (77) farahan ninu fidio awọn eeyan to bọ nigbekun ogun. Awọn Islamic Jihad lo fi fidio naa sita.
Aga awọn eeyan ti ko le rin ni mama naa jokoo si ninu fidio yii, to n ba awọn akọroyin sọrọ.
Oun atọmọ ré, Elad Katzir, ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta (47) ni wọn ji gbe Nir Oz.
Awọn yooku ni

Oríṣun àwòrán, @Family Handout
Channah Peri, ẹni ọdun mọkandinlọgọrin (79), ọmọ rẹ Nadav Popplewell, ẹni ọdun mọkanlelaadọta (51) .
Dr Shoshan Haran, ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin (67)
Adi Shoham, ẹni ọdun mejidinlogoji (38) , Nave, ọmọ ọdun mẹjọ, Yahel, ọmọ ọdun mẹta . Ọkọ Adi ṣi wa nigbekun ni tiẹ .
Noam, ọmọ ọdun mejila,
Yafa Adar, ẹni ọdun marundinlaadọrun-un (85)
Shiri Weiss, ẹni ọdun mẹtalelọgọta (53) ati ọmọ rẹ obinrin, Noga, ẹni ọdun mejidinlogun (18).
Noam, Alma,Roni Krivoi
Hen Almog-Goldstein, ẹni ọdun mejidinlogoji (48) atawọn ọmọ rẹ Tal, ọmọ ọdun mẹjọ , Gal, ọmọ ọdun mọkanla 11) ati Agam, ọmọ ọdun mẹtadinlogun(17).
Dafna,ọmọ ọdun mẹẹẹdogun (15),Ela Elyakim, ọmọ ọdun mẹjọ.
Adrienne Aviva Seigel, ẹni ọdun mejilelọgọta (62), ọkọ rẹ,Keith, ẹni ọdun mẹrinlelọgọta (64) la gbọ pe o ṣi wa nigbekun.
Elma Avraham, ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin (84) Ati bẹẹ bẹẹ lọ bi wọn ṣe n gba ominira si i.















