Àwọn obìnrin lẹ́gbẹ́ òṣèlú NNPP fẹ̀hónú hàn nítorí gómìnà Kano tí kóòtù yọ nípò

Oríṣun àwòrán, @Channels
Idajọ ileẹjọ Kotẹmilọrun to ni Gomina ipinlẹ Kano, Abba Yusuf, ti ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People’s Party (NNPP) kọ lo wọle ibo to waye loṣu kẹta ọdun yii, to fi wa paṣẹ pe Nasiru Gazwuna, ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lo bori ti mu kawọn obinrin NNPP kan o fi ẹhonu han nilu Kano.
Awọn obinrin ẹgbẹ naa yari pe Abba Yusuf ni Gomina awọn, ki kootu yi aṣẹ rẹ pada.
Ọjọ Aiku ni awọn obinrin naa wọde pẹlu aṣọ pupa lọrun wọn, pẹlu onirurur patako alakọle ti wọn kọ oriṣiiriṣii ti wọn fi n kede pe Abba Yusuf lawọn eeyan Kano dibo yan.
Kootu Kotẹmilọrun lo gbe idajọ kalẹ ni bii ọsẹ kan sẹyin, pe Abba Yusuf ti ti ẹgbẹ NNPP fa kalẹ tako ilana eto idibo, ko si kun oju oṣuwọn lati du ipo naa.
Eyi ni ileẹjọ ọhun ṣe fagile iyansipo rẹ, to si paṣẹ pe Nasiru Gaawuna, ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ipinlẹ Kano ti kilọ pe ko gbọdọ si ifẹhonuhan nitori idajọ yii, eyi tawọn obinrin NNPP ṣe yii ni ẹlẹẹkẹta ifẹhonuhan lori idajọ naa.
Lati ibugbe oludije ipo aarẹ ninu ẹgbẹ NNPP, Rabiu Kwakawanso lawọn iya ti wọn to ọgọrun un naa ti gbera, ti wọn wọde de Olu ileeṣẹ ọlọpaa Kano.
Wọn n pariwo pe idajọ ai-ṣododo ni kootu Ko-tẹ-mi-lọrun gbe kalẹ, ki wọn yi i pada. Abba Yusuf ni gomina awọn.
NNPP ati Gomina Yusuf ti lọ sile-ẹjọ to ga julọ
Apapọ ẹgbẹ oṣelu NNPP ati Gomina Abba Yusuf funra rẹ ti lawọn ko gba idajọ kootu Apiili wọle.
Wọn ti lọ sile-ẹjọ to ga ju lọ ( Supreme Court) lati tako idajọ kootu yii.
Gomina Yusuf to fidii gomina ana nipinlẹ Kano nalẹ ninu ibo oṣu kẹta ọdun 2023 yii, sọ pe idajọ ti ko r’oju ọjọ ni kootu Ko-tẹ-mi-lọrun gbe kalẹ, pẹlu bi gbogbo ẹri ṣe fi ijawe olubori oun han to ninu ibo naa.
Ifẹhonuhan tun waye n’Ibadan, awọn olutẹle Gomina Kano lawọn ko faramọ idajọ kootu
Bakan naa ni lawọn ololufẹ Gomina Abba Yusuf tun ko ara jọ lọjọ Aiku kan naa niluu Ibadan, ti wọn lawọn ko faramọ idajọ kootu Kotẹmilọrun to yọ Abba Yusuf.
Gẹgẹ bi iwe iroyin àwn ileeṣẹ iroyin abẹle kan ṣe royin, Papa iṣere Lekan Salami to wa niluu Ibadan lawọn eeyan naa kora jọ si.
Wọn gbadura wọn si ṣe iwọde alaafia lati sọ pe Abba Yusuf ni Gomina Kano, ki kootu ma gbe Gawuna wa.
Awọn akọle bii ‘’Idajọ ododo fun Kano, Abba ni aayo wa, Abba ni Kano dibo fun’’ ati bẹẹ bẹẹ lọ lawọn eeyan naa gbe dani, ti wọn fi kede ẹdun ọkan wọn.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ n’Ibadan,Oludamọran pataki fun Gomina Kano lori itọju ọrọ igbo ọba, Ahmad Sawaba, rọ ile-ẹjọ to ga julọ lati farabalẹ wo idajọ kootu Apiili, ki wọn si dajọ to yẹ.
O ni ki ẹka idajọ maa ṣe ohun to le da rogbodiyan silẹ ni Kano ati lawọn ibo mi-in lorilẹ-ede yii.
’’ Yusuf lawọn eeyan Kano dibo fun, ki i ṣe ẹlomi-in. Ki kootu ṣedajọ ododo lori ẹjọ yii, a ko fẹ rogbodiyan ni Kano’’
Bayii ni Sawaba wi.














